Àwọn òrìṣà méje ìṣẹ̀mbáyé tó di ilẹ̀ gbogbo àgbáyé mú

Orisa Osun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Awọn oriṣa ni ilẹ Yoruba jẹ igbagbọ awọn ẹlẹsin ibilẹ paapaa ni orilẹede Naijiria, Benin ati Togo.

Ọpọlọpọ awọn onigbagbọ ninu oriṣa iṣẹmbaye ni wọn ri awọn orisa yii gẹgẹ bi ọlọrun wọn.

Wọn gbagbọ wi pe awọn orisa yii ṣiṣ̣ẹ pọ fun ara wọn ni, amọ wọn ki n ṣe nkankan naa lati ọdọ Olodumare to ran wọn wa si ile aye.

Paapaa wọn ni igbagbọ wi pe awọn orisa yii dabi angẹli tabi iranṣẹ olodumare ti awọn eniyan ma n pe ni igba iṣoro.

Lara awọn orisa naa ni Esu, Ogun, Ọbatala, Yemọja, Osun, Sango ati Ọya, ti wọn pe ni Ọrumila.

Ni ilẹ Yoruba, awọn ̣elẹsin ibilẹ gbagbọ wi pe esu jẹ oriṣa to lagbara pupọ, to si jẹ iranṣẹ laarin aye ati ọrun, to fi mọ agbede meji.

Oun si ni ọkan lara awọn orisa ti o ma n tọ awọn oku sọna lẹyin ti wọn papoda.

Wọn gbagbọ wipe esu ni a n ke pe ti ohun ba daru, ti eniyan si n wa ọna abayọ tabi ojutu si nkan to wọ.

Bakan naa ni wọn ri ẹmi esu gẹgẹ bi orisa alarekereke, to ṣeeṣe ko tan eniyan jẹ.

Awọn aṣọ pupa ati dudu ni o jọ mọ orisa yii, ti wọn si n lo ata wẹwẹ, taba mimu ati ounjẹ gbigbona lati fi bọ oriṣa yii.

Ogun

Ogun jẹ orisa akunlẹbọ ti wọn gbagbọ wi pe oun ni ẹni keji to lagbara julọ ninu awọn orisa meje to ku.

Ogun ti gbogbo eniyan mọ pẹlu irin, ni o ma n ṣiṣẹ iwosan to si jọba lori gbogbo ohun ti a fi irin da.

Awọn ẹlẹsin ibilẹ gbagbọ wipe abiyamọ tootọ ni Ogun, ti o ma n ṣe atilẹyin fun ọmọde ati idile. Oun si ni wọn n pe lati bura tabi rin irinajo.

Wọn gbagbọ wi pe oriṣa kan ti kii sinmi ni Ogun jẹ, to si ma n fi ẹjẹ wẹ bi omi.

Amọ, ẹnikẹnị ti ẹjẹ ba n yọ ni ara rẹ ko gbọdọ sunmo idi oriṣa Ogun.

Lati bọ Ogun, wọn ma n lo ewe ni ẹba titi, irin, ẹjẹ, awọn ohun ija, ẹran, ogogoro ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ọbatala

Ọbatala jẹ ọkan lara awọn orisa meje ti o tutu pẹlu ẹbun itusilẹ ati alaafia.

Amọ, oun ni awọn oloriṣa gbagbọ wi pe o ma n da awọn eniyan ti ko pe, paapaa awọn akanda eniyan.

Ọbatala ni o ni suuru julọ laarin awọn ẹmi meje yii, to si ma n ṣe idajọ ododo.

Oriṣa yii fẹran awọn eniyan ti kii ṣe alara gbigbona, ti wọn si le e ko ara wọn ni ijanu.

Aṣọ funfun ni a mọ pẹlu Ọbatala, ti o si ma n ṣiṣẹ iwosan fun awọn to ba ni ailera, paapaa awọn akanda ẹda.

Bẹẹ si ni Ọbatala kii gba oṭi kikan rara, yatọ si omi, miliki, ṣuga, ọgẹdẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Yemọja

Yemọja jẹ obinrin lara awọn orisa meje to di ile aye mu, to n gbe ninu omi, to si n jọba lori gbogbo omi nla nla.

Yemọja to jẹ ẹja nla ninu odo ni ibatan Osun to jọba lori awọn omi kekeke.

Awọn ẹlẹsin ibilẹ gbagbọ wi pe olupese ni Yemọja, to n pese ọmọ to si n fun awọn eniyan ni ohun meremere ninu omi, amọ o si le e fa ibinu yọ bi ẹkun omi tabi iji lile.

Lailai, Ọya ati Yemọja kii ṣe ọrẹ nitori naa wọn kii gbe wọn si ibi kan naa.

Awọn arinrinajo lori omi ma n bọ lẹba odo, ki wọn to bẹrẹ irinajo wọn, ki o le lo ni irọwọ-rọsẹ.

Ọsun

Osun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oriṣa akunlẹbọ yii ni awọn ẹlẹsin ibilẹ gbagbọ wi pe o jọba lori awọn omi kekeke, to si jẹ ibatan Yemọja.

Ọsun ni wọn ma n bọ ti wọn ba n wa nkan ayọ, paapaa ọmọ tuntun jojolo.

Ọsun kii tete binu, amọ ibinu rẹ ko sunwọn rara.

Awọn eroja ti wọn fi n sin Osun ni omi, miliki, oyin ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ṣango

Ibi ti Sango n sun nigba aye rẹ
Àkọlé àwòrán, Osé Sango, ati ibi ti Ṣango n sun nigba aye rẹ

Ṣango jẹ ọkan lara awọn oriṣa to gbona jainjain, ti si n rọjo ina ti irin ba koju irin.

Ṣango ni awọn ẹlẹsin ibilẹ gbagbọ wi pe o jẹ Ọya ati Ọsun.

Ṣango ati Ogun kii ri ara wọn soju nitori wọn kii ṣe ọrẹ nitori ọta ara wọn ni wọn n ṣe.

Ṣango ni o ma n ṣe idajọ nipa lilo mọnamọna, ti kii si jẹ ki ibi ṣẹlẹ si awọn ọlọlufẹ rẹ, to si fẹran obinrin, orin ati igbadun.

Ọya

Ere Oya niluu Ile-Ira, nibi to wọlẹ si
Àkọlé àwòrán, Ere Oya niluu Ile-Ira, nibi to wọlẹ si

Ọya lo kẹyin ninu awọn oriṣa meje to lagbara julọ lagbaye, ti wọn si ma fi n rọpọ orunmila nigba miran.

Awọn ẹlẹsin ibilẹ gbagbọ wi pe obinrin to rẹwa ni ti o si wa ninu omi pẹlu agbara lati ṣiṣẹ iwosan ati ọmọ bibi.

Eewọ ni lati pe oriṣa Ọya, Yemọja ati Ọsun papọ lẹẹkan naa, nitori ọta ni wọn, wọn kii ri Ọya soju, afi ti ẹ ba n pe awọn oriṣa mejeeje papọ ni igba kan naa.