Alàgbà ni ọkọ mi ní ṣọ́ọ̀ṣì, wòólì ni mí fún ogún ọdún kí ń tó di Yeye Olokun - Omolara Fanimokun

Aworan Yeye Olokun Omolara Fanimokun
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Akunlẹyan ni adayeba, a de ile aye tan, oju n kan wa. Bayii ni ọrọ ṣe ri gẹlẹ pẹlu Yeye Olokun ilu Eko, Arabinrin Omolara Fasola Fanimokun.

Arabinrin Omolara ṣalaye ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu BBC Yoruba wi pe, oun ṣe ẹsin Musulumi ri, bakan naa ni oun tun lo ogun ọdun ni ṣọọṣi gẹgẹ bii wooli ijọ kan ki oun to wa gba ibi iṣẹ ti ori ran oun lọ eyi ti i ṣe bibọ okun.

"Ipe mi ni Oloriṣa olokun, iṣẹ ti mo si yan laayo ni iṣẹ amofin lorilẹede Naijiria.''

"Lati kekere ni mo ti maa n ri ara mi nibi ti mo ti n wẹ, ṣere ninu omi."

Yeye Omolara Fanimokun to jẹ amofin nipa alumọni inu omi ṣalaye bo ṣe yan lati di yeye Olokun eyi ti ọpọlọpọ maa n pe ni Yemoja nilẹ Yoruba.

Iṣẹ to n ṣe bayii dabii ajogunba nitori gẹgẹ bi o ṣe sọ fun BBC Yoruba, lati ile baba ati ile iya rẹ ni wọn ti n bọ okun.

''Ọmọ Isalẹ-Eko ni mi, ilu Benin nipinlẹ Edo si ni mama mi ti wa.

A kii fi olokun ṣere l'Eko, nitori naa, oriṣa olokun wa nile baba, awọn ẹbi iya mi naa n bọ okun.

Ko si ile kan ni Isalẹ-Eko ti ẹ ko ni i ri ẹnikan to n bọ okun nibẹ tori olokun lo faye gba wa niluu Eko.

Okun ati ọsa lo gba wa laaye l'Eko, ẹ maa ri i wi pe wọn maa n saba wa lẹgbẹ ara wọn ni.'

''Pasitọ CAC lo sọ fun mi pe Eledumare fẹ ki maa n bọ okun''

Aworan Yeye Olokun Omolara Fanimokun
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Yeye Olokun Omolara ni oun lọ si ṣọọṣi CAC kan lọjọ kan nibi ti wọn ti n ṣe isọji lọwọ.

O ni baba oludasilẹ ṣọọṣi naa ba sọ fun oun wi pe, ki awọn rira lẹyin isin isọji naa.

''Baba yii sọ fun mi pe idi omi ni mo ti sẹ wa, o ni Eledumare fẹ lo mi lati maa lo omi amọ kii ṣe ni ṣọọsi.

Iyẹn lo wa mu mi ronu pe ọrọ ti pasitọ naa sọ ko yatọ si awọn nnkan ti mo ti n gbọ tẹlẹ.

Nibẹ ni mo ti pinnu wi pe asiko ti to lati bẹrẹ si ni maa bọ okun.

Ko si igba ti mo de ọdọ olokun lati ba a sọrọ ti ki i gbọ nnkan ti mo ba ba a sọ, gbogbo rẹ lo maa n gbọ.

Ẹni to n ṣowo to ba b'olokun da owo pọ, o maa jere, ẹni to n ṣiṣẹ ijọba to ba ba olokun da owo pọ, yoo maa ni igbega lẹnu iṣẹ.

Awọn ọmọlẹyin Kristi atawọn aafa n wa sokun, ko si ẹni ti kii wa si okun, nitori ara awọn nnkan iyanu nla ti Eleduwa fi jinki wa ni okun jẹ,'' Yeye Olokun ṣalaye

Arabinrin Omolara ko ṣai dupẹ lọwọ ọkọ rẹ ẹni to ṣapejuwe gẹgẹ bi alatilẹyin rẹ.

Yeye Olokun ni bo tilẹ jẹ pe alagba ni ọkọ oun ni ile ijọsin to n lọ, ko sọ pe ki oun ma bọ okun, bọ ọsa.

Arabinrin Fanimokun sọ pe ọkọ oun mọ itan oun, o si mọ ibi ti oun n lọ wi pe oun gbọdọ jiṣẹ ti Eledumare ran oun.

Yeye Olokun ni ''iya ẹni ni iṣẹṣe ẹni, baba ẹni ni iṣẹṣe ẹni, bi a ṣe n gbe ile aye, iṣẹṣe ẹni.

Iṣẹṣe ni nnkan ti a ba lọwọ awọn baba nla wa ti wọn n ṣe ti awọn naa si n ṣe.

O ni ti gbogbo eeyan ba kọ lati ṣe iṣẹṣe, iṣẹṣe yoo parun.