'A kàn ṣàdédé rí àwọn agbébọn tí wọ́n ṣíná ìbọn bolẹ̀, pa èèyàn mẹ́jọ, inú ìbẹ̀rù là ń gbé báyìí'

Àwọn agbébọn

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kejìlélógún, oṣù Kẹrin ni ìròyìn kan jáde pé àwọn agbébọn kan ṣèkọlù sí àwọn ìjọba ìbílẹ̀ méjì ní ìpínlẹ̀ Kwara tí wọ́n sì ṣekúpa èèyàn èèyàn mẹ́jọ.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nínú àtẹ̀jáde tí wọ́n fi léde lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun látọwọ́ agbẹnusọ iléeṣẹ́ náà Adetoun Ejire-Adeyemi fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn agbébọn náà lọ ṣíná ìbọn bolẹ̀ fáwọn èèyàn tí wọ́n wà ní ilé ìgbafẹ́ kan ní ibùdókọ̀ Ilesha-Baruba, ìjọba ìbílẹ̀ Baruten.

Èèyàn mẹ́fà ló pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìkọlù náà nígbà tí àwọn méjì míì tún farapa yánnayànna tí wọ́n sì ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe sọ.

Àwọn agbébọn náà tún ṣe ìkọlù sáwọn fijilanté ní ìlú Kemanji, ìjọba ìbílẹ̀ Kaiama, tí wọ́n sì pa ẹnìkan nínú wọn nígbà tí wọ́n kojú oro síra wọn.

Èyí ló mú BBC News Yorùbá kàn sí láti gbọ́ lẹ́nu àwọn aráàlú láti mọ bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé.

Ọ̀kan lára àwọn aráàlú Ilesha-Baruba tí kò fẹ́ kí a dárúkọ òun sọ pé ṣàdédé ni àwọn agbébọn náà yawọ ibùdókọ̀ náà tí wọ́n sì ṣíná ìbọn bolẹ̀.

Ó ní èèyàn mẹ́jọ ni àwọn agbébọn náà ṣekúpa àmọ́ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ pé èèyàn mẹ́fà ni àti pé àwọn méjì kan farapa lásán ni.

"Wọ́n kàn wọlé wá, wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe ìkọlù sáwọn èèyàn, a ò mọ ibi tí wọ́n ti wà, wọ́n sì pa èèyàn mẹ́jọ."

Ó ní ìgbàgbọ́ wà pé èèyàn kan ni wọ́n tọpasẹ̀ rẹ̀ wá sí ìlú náà nítorí irúfẹ́ ìkọlù bẹ́ẹ̀ kò wáyé rí ní agbègbè àwọn.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ti máa ń gbọ́ nípa pé àwọn agbébọn ti wà ní àwọn ìjọba ìbílẹ̀ Baruten àti Kaiama àmọ́ wọn ò ṣe ìkọlù sí ìlú Ilesha Baruba rí.

Ó fi kun pé àwọn kò ti ẹ̀ kẹ́fín rẹ̀ àwọn àjòjì kankan tàbí fura sí ẹnikẹ́ni nínú ìlú kó tó di pé ìkọlù náà wáyé.

"A ti máa ń gbọ́ pé àwọn agbébọn ń ṣe ìkọlù ní Kaiama àti Yashikira àmọ́ wọn ò dé Ilesha Baruba rí."

Ó wá kọminú lórí ààbò àwọn èèyàn agbègbè náà bí ó ṣe ni inú ìbẹ̀rù ni àwọn fi ń gbé báyìí nítorí àwọn kò mọ nǹkan tó lè ṣẹlẹ̀ sí àwọn.

Láti ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni ìròyìn ti ń jà rainrain pé àwọn ẹgbẹ́ àwọn agbébọn kan ti ń ṣọṣẹ́ ní ìjọba ìbílẹ̀ méjì ní ìpínlẹ̀ Kwara àmọ́ tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, nígbà náà, sọ pé irọ́ ni ìròyìn náà.

Àwọn agbébọn pa èèyàn méje nínú ìkọlù tó wáyé níjọba ìbílẹ̀ méjì ní Kwara

Àwòrán àwọn agbébọn

Oríṣun àwòrán, Others

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí àwọn agbébọn tó ṣe ìkọlù sí ibùdókọ̀ kan ní Ilesha Baruba, ìjọba ìbílẹ̀ Baruten, ìpínlẹ̀ Kwara tí wọ́n sì ṣekúpa èèyàn mẹ́fà.

Bákan náà ni àwọn èèyàn méjì míì tún faragba ọta ìbọn nínú ìkọlù náà tí wọ́n sì wà lẹ́sẹ̀ kan ayé, ẹsẹ̀ kan ọ̀run.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá Kwara, Adetoun Ejire-Adeyemi nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀.

Ejire-Adeyemi sọ pé ni nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án àbọ̀ alẹ́ ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù Kẹrin, ọdún 2025 láwọn agbébọn náà yawọ ibùdókọ̀ náà tí wọ́n sì ṣíná ìbọn bolẹ̀ sáwọn èèyàn tó ń gbafẹ́ ní ilé ìgbafẹ́ kan tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ibùdókọ̀ náà.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ó ní àwọn agbébọn ọ̀hún ni iye wọn tó mẹ́wàá.

Ó ṣàlàyé pé ìkọlù náà ṣokùnfà ikú èèyàn mẹ́fà táwọn méjì míì sì farapa yánnayànna.

Ó fi kun pé òkú àwọn mẹ́fẹ́ẹ̀fà ti wà ní mọ́ṣúárì fún àyẹ̀wò, táwọn tó farapa sì ti ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn.

Ó tẹ̀síwájú pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìkọlù náà àti pé ìgbésẹ̀ ààbò tó gbópọn láti fojú àwọn tó ṣiṣẹ́ ibi náà winá òfin ti bẹ̀rẹ̀ ní kíákíá.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá náà tún sọ pé ṣáájú ni àwọn afurasí agbébọn, ní nǹkan bíi aago mọ́kànlá àbọ̀ òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé kan náà, ti ṣèkọlù sáwọn fijilanté ní agbègbè Kainji National Park.

"Àwọn fijilanté àti àwọn afurasí agbébon fìjà pẹ́ẹ́ta, tí wọ́n sì kojú ìbọn síra wọn. Ìbọn ba àwọn afurasí agbébọn mẹ́ta àti fijilanté kan."

Ó ṣàlàyé pé fijilanté náà padà jáde láyé.

Ejire-Adeyemi ní ìwádìí àwọn ṣokùnfà bí ọwọ́ ṣe tẹ ẹnìkan tí wọ́n fura sí pé ó jẹ́ agbódegbà fáwọn agbébọn náà tó sì ti jẹ́wọ́ pé òun ni òun ń ṣe atọ́nà fún wọn.

Ó ní ìgbàgbọ́ wà pé afurasí náà yóò jẹ́ atọ́nà fáwọn lórí ìwádìí láti nawọ́ gán àwọn afurasí náà.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Kwara wá rọ àwọn èèyàn láti fọkàn balẹ̀, pé iṣẹ́ ń lọ láti pèsè ààbò tó péye lórí ẹ̀mí àti dúkíà àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Kwara

Wọ́n ní ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣe agbódegbà fáwọn oníṣẹ́ ibi ni yóò fojú winá ofin.

Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni ìròyìn kan gbòde pé àwọn agbébọn kan tí wọ́n pe ara wọn ní Mahmuda ti dé sí ìpínlẹ̀ Kwara, ní ìjọba ìbílẹ̀ Baruten àti Kaiama tí wọ́n sì ti ń ṣekúpa àwọn èèyàn.

Àmọ́ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nínú àtẹ̀jáde kan sọ pé ìròyìn tó jìnà sí òótọ́ ni ìròyìn náà pé kò sí agbébọn tuntun ní Kwara.

Pẹ̀lú ìkọlù tuntun yìí, àwọn èèyàn kan gbàgbọ́ pé ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé àwọn agbébọn tuntun náà ló ṣe iṣẹ́ ibi yìí.