Àwọn ajínigbé ṣọṣẹ́ ní Kwara, jí gbogbo èèrò inú ọkọ̀ gbé

Àwọn agbébọn

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ni ọjọ Abamẹta, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin ni ariwo tun sọ ni opopona Obbo-Aiyegunle si Osi, ijọba ibilẹ Ekiti ni ipinlẹ Kwara bawọn ajinigbe tun ṣe ṣọṣẹ ni opopona naa.

Ọkọ Sienna kan to ko ero lati ilu Abuja to n lọ si Offa ni awọn ajinigbe naa ṣe ikọlu si gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ.

Ọkan lara awọn olugbe ilu Obbo Aiyegunle to ba BBC News Yoruba sọrọ, Ọgbẹni Layọde salaye pe awọn ajinigbe naa ko awọn agbalagba to wa ninu ọkọ naa lọ amọ ti wọn fi awọn ọmọde silẹ.

O ni awọn ọmọde to wa ninu ọkọ ọhun, amọ ti wọn ji awọn obi wọn gbe, lọ ọ sun lọdọ alaga ijọba ibilẹ Ekiti mọju ọjọ Aiku.

O fi kun ọrọ rẹ pe, awọn odẹ ibilẹ ati awọn fijilante to fi mọ awọn ọlọpaa ti wọ inu igbo lọ lati ṣawari ati lati doola awọn eeyan naa kuro ni akata awọn ajinigbe ti wọn wa.

Ninu ọrọ rẹ, Alaga ijọba ibilẹ Ekiti, Awelewa Olawale Gabriel sọ pe inu ile oun lawọn ọmọ kekere mẹta ti awọn ajinigbe naa ko fi ọwọ kan sun mọjumọ ọjọ Aiku.

Awelewa ṣalaye pe bi o tilẹ jẹ pe ọjọ ori awọn ọmọ naa kere, o ni ọkan lara wọn le ṣapejuwe ile wọn ni ilu Offa.

O sọ pe awọn gbiyanju lati pe nọmba baba rẹ amọ ko lọ, eyi lo mu oun pe alaga ijọba ibilẹ Offa to jẹ akẹgbẹ oun lati ba oun lọ si ile ti ọmọ naa juwe.

O ni bẹẹ ni awọn ṣe ri awọn ara ile wọn ba sọrọ lati ṣalaye ohun to ṣelẹ fun wọn ati lati wa ko awọn ọmọ to wa ni akata oun.

Alaga naa sọ pe alaga ijọba ibilẹ naa ti ko awọn ọmọ ọhun lọ sọdọ awọn eeyan wọn nigba tawọn agbofinro n tẹsiwaju lati ṣawari awọn obi wọn.

O salaye pe ọkunrin marun-un, obinrin meji lo wa ninu ọkọ ile iṣẹ akero Olumo Express tawọn ajinigbe naa ṣe ikọlu si.

O tẹsiwaju pe igba akọkọ kọ niyii ti iṣẹlẹ ijinigbe n waye ni agbegbe naa, ti oun si ti ṣepade pẹlu Alaga ijọba ibilẹ Oke Ero ti awọn jọ paala lagbegbe ibi ti iṣẹlẹ ijinigbe naa ti saba maa n waye

O fi kun pe awọn tun ti ranṣẹ si ileeṣẹ Ologun to wa lagbegbe naa lati ran awọn lọwọ lati fopin si iṣẹlẹ ijinigbe nibẹ.

Ki ni ileeṣẹ ọlọpaa Kwara sọ?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Adetoun Ejirẹ-Adeyemi fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ninu atẹjade kan to fi lede.

Ejire-Adeyemi sọ pe eeyan meje to fi mọ awakọ lo wa ninu ọkọ to n lọ si ilu Offa lati Abuja naa kawọn ajinigbe, ti wọn to mẹjọ to dawọn lọna ni agbegbe Obbo-Aiyegunle si Osi.

O ni nnkan bii aago mẹfa abọ irọlẹ ọjọ Abamẹta ni iṣẹlẹ naa waye.

O sọ pe bi iṣẹlẹ naa ṣe to ileeṣẹ ọlọpaa leti ni wọn bẹrẹ iṣẹ pẹlu awọn fijilante to wa ni gbegbe naa lati lọ doola awọn eeyan naa.

Agbẹnusọ ọlọpaa naa ni nibi tawọn ẹṣọ aabo ti n wa awọn eeyan naa ni wọn ti ṣawari awọn ọmọde mẹta kan ti ọjọ ori wọn wa laaarin ọdun meji si mejila ti ọkan lara si juwe ile wọn fawọn ọlọpaa.

O ni awọn ọmọ naa ti wa pẹlu awọn ẹbi wọn bayii.

Bakan naa lo fi kun pe awọn ti n pọnkun igbesẹ ati iṣẹ iwadii awọn lati ri daju pe awọn eeyan ti wọn ji gbe naa di riri.

O sọ pe Kọmiṣanna ọlọpaa Kwara, Adekimi Ojo rọ ẹnikẹni to ba nimọ nipa bi wọn ṣe le ṣawari awọn ajinigbe ẹhun ati bi wọn ṣe le gba awọn eeyan naa silẹ, ki wọn fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti lẹyẹ o sọka.