Bí àyípadà ojú ọjọ́ ṣe le mú kí èròjà arsenic tó wà nínú irẹ̀sì fa àìsàn jẹjẹrẹ àti ìtọ̀ ṣúgà

Irẹsi

Oríṣun àwòrán, Alamy

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Irẹsi jẹ ounjẹ kan gboogi ti ọpọ eeyan n jẹ kaakiri agbaye, paapaa ni Naijiria, amọ awọn onimọ ti sọ pe ayipada oju ọjọ le 'sakoba fun eroja "arsenic" to wa ninu ounjẹ ọhun.

Awọn onimọ sọ pe bi awon eefin ọkọ atawọn irinṣẹ nla nla mii ṣe n lọ soju ofurufu ti ilẹ aye si n gbona sii naa ni eroja arsenic ọhun n ga si ninu irẹsi.

Ṣaaju akoko yii ni wọn ti kọkọ sọ pe arsenic ọhun lewu fun awọn to ba n jẹ irẹsi.

Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, asiko ti irẹsi naa ba n wu ni eroja arsenic naa maa n wọ inu rẹ lati inu ilẹ.

A gbọ pe o lewu fun ẹda lati maa jẹ eroja arsenic naa yala ninu ounjẹ ni o tabi lati inu omi ti eeyan n mu nitori o le fa aisan jẹjẹrẹ atawọn aisan mii bii itọ ṣuga.

Kaakiri agbaye lawọn onimọ ti n wa ọna lati mu adinku ba iye iwọn arsenic ninu irẹsi.

Wọn ni bi eeyan ṣe n se irẹsi rẹ le ṣamọna bi yoo ṣe din aroja naa ku ninu rẹ si.

Ninu iwadii wọn, awọn onimọ naa gbin oniruru irẹsi mejidinlọgbọn sinu oko mẹrin ọtọtọ ni China, wọn si bojuto awọn eso rẹ fun ọdun mẹwaa gbako.

Esi iwadii wọn fi han pe awọn irẹsi ti wọn gbin sibi to mooru julọ ni eroja arsenic pupọ ninu.

Wọn ṣalaye pe eroja arsenic to wa ninu irẹsi wa lara nnkan to mu ki eeyan to le ni miliọnu mọkandinlogun ni arun jẹjẹrẹ lorilẹede China nikan ṣoṣo.

Bo tilẹ jẹ pe China ni iwadii naa ti waye, wọn ni awọn eeyan to n gbe ni Europe ati Amẹrika naa le wa ninu ewu kan naa ti wọn ba tẹsiwaju lati maa jẹ irẹsi to ni eroja ọhun to pọ ju ninu.

Yatọ si arun itọ ṣuga ati jẹjẹrẹ, wọn sọ pe eroja naa tun le ṣokunfa aisan ọkan.

Nibi ti ọrọ de duro yii, ṣe ki a yọ irẹsi kuro ninu ounjẹ wa ni?

Wayi o, awọn onimọ ọhun ti sọ pe tunṣe si bi wọn ṣe n gbin irẹsi le dena eroja arsenic naa.

Wọn ni kaka ni gbogbo ibi ti awọn agbẹ n gbin irẹsi si jẹ kiki omi, wọn le ṣe idaji rẹ ni omi ki idaji rẹ si jẹ ilẹdu.

Wọn tun ni ki awọn agbẹ maa fi 'sulphur' sinu omi ilẹ ti wọn n gbin irẹsi naa si.

Ju gbogbo rẹ lọ, wọn ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lori ọna abayọ.