Pàtàkì ẹyin àti ehoro nínú ìtàn àti ayẹyẹ ọdún Àjíǹde Jésù Kristì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọdun Ajinde Easter jẹ opomulero igbagbọ awọn ọmọlẹyin Kristi to ti wa fun ẹgbẹgbẹrun ọdun.
Asiko ọdun Ajinde ni awọn onigbagbọ ma n ṣe ajọdun ajinde Jesu Kristi kuro ni ipo oku.
Iwe Mimọ Bibeli sọ wipe Jẹsu Kristi ku lori igi agbelebu ni Ọjọ Ẹti rere, Good Friday.
Gẹgẹ bi Bibẹli ṣe sọ, Jesu Kristi jinde ni ọjọ kẹta kuro ni ipo oku, ti o si ja si Ọjọ Ajinde.
Ni ọdọọdun, ọdun Ajinde ma n yatọ to si ṣeeṣe ko waye lọjọ kan laarin ọjọ kọkanlelogun, Oṣu Kẹta si Ọjọ karundinlọgbọn, Oṣu Kẹrin, eleyii ti awọn kan gbọgbọ wipe o niiṣe pẹlu bi oṣupa ba ṣe tan imolẹ si(Full Moon).
Lasiko ọdun Ajinde, awọn Kristẹni maa n darapọ lati gbadura ki wọn si jọ jẹun papọ, nitori pe ṣaaju asiko naa, wọn ti wa ninu awẹ Lẹnti ogoji ọjọ gẹgẹ bi Jesu Kristi naa ṣe gba a ninu iwe mimọ.
Ki lo wa n jẹ "Ẹyin" ọdun Ajinde?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni Ilẹ Yuroopu, ọpọlọpọ eniyan lo maa n jẹ ṣokoleeti ẹlẹyin lasiko ọdun Ajinde lati fi ṣe ayẹyẹ ajinde Jesu Kristi.
Ni igba ti asa ẹyin bẹrẹ, awọn adari ẹsin ni igba naa lọhun kii gba ki awọn eniyan jẹ ẹyin lasiko ọsẹ ijiya Jesu, ti awọn oloyinbo n pe ni Holy Week.
Nitori naa ohun ti awọn eniyan maa n ṣe ni lati ko awọn ẹyin ti adiye ba ye ni asiko yii pamọ, ti wọn a si ṣe e ni ẹṣọ, ti wọn a si fun awọn ọmọde gẹgẹ bi ẹbun ni ọjọ Ajinde.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Titi di oni ni awọn eniyan ṣi n ṣe e, ti wọn si n fun awọn eniyan ni ẹbun ẹyin ni ọdun Ajinde.
"Ehoro" nkọ, kini wọn fi n ṣe ni Ọjọ Ajinde?
Itan ehoro ajinde ni o wọpọ ni awujọ awọn eniyan nibii ọdun 1900 lọhun.
Awọn ehoro maa n bi ọmọ to maa n tobi ti awọn oloyinbo n pe ni (kitten), ti awọn eniyan si ri wọn gẹgẹ bi ibẹrẹ igbe aye tuntun.
Itan sọ fun wa pe awọn ẹyin ti ehoro ba ye ni asiko yii, ehoro ma n ṣe e ni ẹsọ, ti yoo si lọ gbe e pamọ.
Nitori naa awọn ọmọ kekeeke ma n wa ẹyin ehoro kaakiri lasiko ọdun ajinde.












