Gbajúmọ̀ olórin ẹ̀mí, Bolaji Olarewaju jáde láyé

Oríṣun àwòrán, @Woliagba_ayoajewole/Instagram
Gbajúmọ̀ olórin ẹ̀mí, Bolaji Olarewaju tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Big Bolaji ti jáde láyé.
Àtẹ̀jáde kan táwọn ẹbí olóògbé náà fi léde ṣàlàyé pé ọjọ́ Àbámẹ́ta ni akọrin ẹ̀mí náà dágbére fáyé.
Àtẹ̀jáde náà sọ pé pẹ̀lú ìbànújẹ́ ọkàn ni àwọn fi kéde ikú Bolaji tó jẹ́ èèkàn láàárín agbègbè tó ń gbé àti nínú ìjọ rẹ̀.
Wọ́n ní olóògbé náà, tó jẹ́ pásítọ̀ ìjọ RCCG, jáde láyé lẹ́yìn àìsàn ránpẹ́.
Ẹbí ní ikú Bolaji dá ọgbẹ́ ọkàn fáwọn àti pé ààyè rẹ̀ yóò ṣòro láti dí.
"Ìgbé ayé Bolaji ṣàfihàn ìfẹ́ tó ní sí orin kíkọ, ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Ọlọ́run àti bó ṣe ní ìfarajìn láti máa ṣe àgbéga fáwọn tó bá sún mọ́ ọn.
"Ipa rẹ̀ kò tán sára àwọn orin tó kọ nìkan bíkòṣe pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí tó fi ọwọ́ bà."
Bákan kan náà ni wọ́n dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn fún ìfẹ́ tí wọ́b fi hàn wọ́n lórí ikú akọrin náà, tí wọ́n sì gbàdúrà kí Ọlọ́run tẹ́ Bolaji sáfẹ́fẹ́ rere.
Wọ́n fi kun pé àwọn máa fi bí ètò ìsìnkú rẹ̀ yóò lọ léde tó bá yá.
Lára àwọn tó ń ṣelédè lẹ́yìn akọrin ẹ̀mí náà ni Woliagba, tó sì kọ sójú òpó Instagram rẹ̀ pé àdánù ńlá ni ikú Bolaji jẹ́ fún òun.
Àádọ́ta ọdún ni Bolaji Olarewaju kó tó jáde láyé.
Ìyàwó àtàwọn ọmọ ni olóògbé náà fi sáyé.















