Àdó olóró America pa èèyàn 74 níbùdó epo Yemen

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ado oloro kan ti wọn ni ikọ ologun ilẹ America ju si ibudo epo leti okun pupa Yemen ti ṣekupa o kere tan, eeyan mẹrinlelaadọrin (74).
Ẹka ilera Houthi to fidi iroyin yii mulẹ, sọ pe eeyan 171 lo tun farapa ninu ibugbamu to waye lẹyin ado oloro naa lalẹ Ọjọbọ.
Awijare ikọ ologun America lori ikọlu naa ni pe awọn ba ibudo epo Ras Isa naa jẹ lati dẹkun epo aitọ ti orilẹede Iran n ri nibẹ, ti wọn si n fi owo ibẹ ro awọn onijagidijagan Houthi lagbara.
Ijọba Houthi to wa ni ẹkun Ariwa-Iwọ-Oorun Yemen ni tiẹ, sọ pe araalu lo ni ibudo epo naa, ati pe ikọlu to waye yii ko ni itumọ meji ju ogun lọ.
Ikọlu yii la gbọ pe o buru ju latigba ti Aarẹ Donald Trump ti gbajọba to si ti kede pe ki wọn mura si ọrọ ado oloro to waye loṣu to kọja.
Tẹ o ba gbagbe, ikọlu ti wọn lo ni i ṣe pẹlu Houthi naa waye lori okun pupa pẹlu ọkọ oju omi nla kan, eyi ti wọn ni Ogun to n lọ lọwọ ni Gaza lo fa a .
Lẹyin ọpọ wakati ti ikọlu ṣẹlẹ si Ras Isa, ikọ ologun Israeli kede pe awọn ti dena ado oloro kan to n bọ lati Yemen.
Ọpọlọpọ iro ado oloro lo n dun lawọn agbegbe Israeli naa, ṣugbọn ko si iroyin to jọ mọ ifarapa tabi iku nibẹ.
''Àdó olóró mẹrinla ló bú gbàmù léraléra, níṣe là ń 'sa kiri''

Oríṣun àwòrán, EPA-EF/REX/Shutterstock
Ileeṣẹ amohunmaworan Houthi kan, Al-Masirah TV, royin pe ado oloro mẹrinla lo sọlẹ si Ras Isa to si n bu gbamu leralera lalẹ Ọjọbọ naa.
Awọn fidio to ṣafihan iṣẹlẹ yii fi bi awọn agba epo nla nla ṣe n bu gbamu han.
"A sa lọ. Ado oloro yẹn n bu gbamu leralera ni, lẹyin ẹ ni gbogbo nnkan bẹrẹ si i gbina."
Ọkunrin kan to ni ọkan lara awọn oṣiṣẹ ibudo naa loun lo ṣalaye bẹẹ fun ẹka iroyin yii.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ilera Houthi, Anees al-Asbahi, ṣalaye pe awọn to ti ku ti wọ mẹrinlelaadọrin, bẹẹ lawọn ṣi n wa awọn miran ti wọn farapa.
Ṣaaju ni Tẹlifiṣan Al-Masirah ti sọ pe awọn oṣiṣẹ Ras Isa lo pọ ninu awọn oku naa.
Ati pe marun-un ninu awọn oṣiṣẹ eleto itọju pajawiri naa ba ikọlu yii lọ.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ko tete ri aridaju onka awọn eeyan to ku, aworan lati Al-Masirah, ṣafihan oku mẹwaa ti wọn jona lẹgbẹẹ tanka epo.
"Ijọba ilẹ America la fi ẹsun ikọlu yii kan, a mọ pe ipadabọ ohun to ṣẹlẹ lori okun pupa ni.''
Ijọba Houthi lo sọ bẹẹ.
Lọjọ Ẹti, obitibiti awọn Houthi ṣewọde tako ikọlu ti wọn ni America lo fa a yii.
Olu ilu ti i ṣe Sanaa ni wọn ti kora jọ.
Ṣugbọn ijọba America ni oun ko ni i laju silẹ, ki Houthi ati ọga wọn ti i ṣe Iran maa gba ọna ẹburu gbe epo ati nnkan ija wọle, ki wọn si maa lo o lati fiya jẹ eeyan bii tiwọn.
Orilẹede Iran paapaa ko dakẹ lori ẹsun yii, wọn ni awọn koro oju si ikọlu ti America ṣe si Yemen.
Ọdún mẹ́wàá sẹ́yin ni nńkan kò ti fararọ ní Yemen

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ogun abẹle lo sọlẹ ni Yemen lati bii ọdun mẹwaa sẹyin, nigba ti awọn Houthi gba agbara orilẹede naa lọwọ ijọba ilẹ okeere ati Saudi Arabia ti America n ran lọwọ.
Ogun to n waye naa ti mu ẹmi eeyan to le ni 150,000 lọ, iyẹn ẹgbẹrun lọna aadọjọ.
Idaru-dapọ pẹlu aibalẹ ọkan ti ogun maa n mu wa ti ba awọn eeyan ibẹ.
Eeyan to din diẹ ni miliọnu marun-un (4.8) ni wọn ti di alainile lori, awọn 19.5 million to jẹ idaji eeyan ilu naa lo si di ẹni ti ko le da nnkan ṣe lai ri iranlọwọ ilẹ okeere gba.
Lati oṣu Kọkanla ọdun 2023 ni awọn Houthi ti n dọdẹ awọn agba oloro ati nnkan ija loju omi okun pupa.
Wọn ti ri ọkọ oju omi meji si agbami okun, wọn ja ikẹta gba, wọn si pa awọn oṣiṣẹ ọkọ mẹrin.
Awijare awọn Houthi ni pe awọn n ṣe atilẹyin fun Palestine ninu ogun to n lọ laaarin Israel ati Hamas ni Gaza ni.
Wọn ni awọn ọkọ oju omi to n lọ si Israel, US abi UK ni awọn n dojukọ.
Loṣu to kọja ni Aarẹ Donald Trump paṣẹ ikọlu si awọn agbegbe ti Houthi n dari.
Trump kilọ fun Iran naa lati yee ro awọn Houthi lagbara, bo tilẹ jẹ pe Iran ki i yee sọ pe oun ko lọwọ ninu ẹ. O dunkooko pe oun yoo jẹ ibẹ run.














