Afurasí darandaran jí akẹ́kọ̀ọ́ fásítì mẹ́wàá tó ń lọ fún ìpàdé Ajinde gbé lọ, méjì fara gbọta, wọn ń bèèrè N15m lọ́wọ́ ẹbí

Aworan akẹkọọ to fara gbọta

Oríṣun àwòrán, Sahara Reporters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn afurasi darandaran ni a gbọ pe wọn ti ji akẹkọọ ile ẹkọ giga ipinlẹ Rivers, Rivers State University ati ile ẹkọ giga olukọni, Ignatius Ajuru University of Education gbe lọna mọrosẹ Benin-Ore l'Ọjọru.

Awọn akẹkọọ ọhun ni a gbọ pe ile ẹkọ giga fasiti Babcock Unniversity nipinlẹ Ogun lawọn akẹkọọ naa ti wọn jẹ ọmọ ijọ Seventh Day Adventist n lọ fun ipade ọdun Ajinde ti wọn fi bọ sọwọ awọn ajinigbe.

Ṣadeedee ni a gbọ pe awọn afurasi darandaran naa bẹrẹ si ni yinbọ si bọọsi tawọn akẹkọọ naa wa ninu rẹ lati dẹru ba wọn.

Bayii ni ọkọ naa duro, tọrọ si di boo lọ ya n mi, meji ninu awọn akẹkọọ naa lo fara gbọta nibi ti wọn ti n saa lọ.

Ọpọ ninu awọn akẹkọọ naa sa wọ inu igbo lọ, nigba ti awakọ naa mori bọ.

Ọkan lara awọn akẹkọọ meji to fara gbọta ni a gbọ pe o wa lẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun bayii nile iwosan nibi ti wọn ti ṣe iṣẹ abẹ pajawiri lati yọ ọta ibọn lara rẹ.

Ọpọ awọn akẹkọọ naa lawọn ẹbi wọn si n wa bayii lati igba ti iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ.

Awọn ajinigbe ọhun lo ti n beere fun miliọnu mẹẹdogun naira fun owo itusilẹ awọn akẹkọọ mẹwaa to wa lakata wọn bayii.

Iṣẹlẹ ijinigbe wọpọ lopopona marosẹ Ore si ilu Benin.

Kii ṣe Ofosu nipinlẹ Ondo ni ijinigbe awọn akẹkọọ fasiti ti ṣẹlẹ - Ọlọpaa Ondo

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti sọ pe kii ṣe agbegbe Ofosu nipinlẹ Ondo lopopona ilu Eko si Ore ni iṣẹlẹ ijinigbe awọn akẹkọọ fasiti to n bọ lati ipinlẹ Rivers toi waye.

Ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, DSP Alayande Olayinka Olushola, fi sita, ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye pe iroyin ti ileeṣẹ ori ayelujara kan, Intel Region News, gbe jade wi pe Ofosu ni iṣẹlẹ ọhun ti waye kii ṣe otitọ.

DSP Olushola fi idi rẹ mulẹ pe iwadii ileeṣẹ ọlọpaa fi han pe agbegbe Ugbogui lopopona Benin si Okada nipinlẹ Edo ni iṣẹlẹ naa waye kii ṣe ni Ofosu nipinlẹ Ondo.

''A fi asiko yii rọ araalu ati awọn ileeṣẹ iroyin lati maa ṣe iwadii daadaa ki wọn to gbe iroyin jade.

Eyi ṣe pataki lati le dena gbigbe iroyin ofege kaakiri eyi to le da ibẹru-bojo silẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa Ondo ko ni kaarẹ nipa pipese eto abo to yanranti fawọn eeyan ipinlẹ naa.

A ko si ni dawo iṣẹ duro lati ri pe alaafia jọba kaakiri ipinlẹ Ondo,'' Olushola lo sọ bẹẹ.

DSP Olushola ni ileeṣẹ ọlọpaa mo riri ifọwọsowọpọ awọn eeyan ipinlẹ Ondo pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa.

O wa rọ araalu lati fi to ọlọpaa leti ti wọn ba ti kẹfin irin ẹnikẹni to mo ifura dani.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post