Portable wọ wàhálà míì n‘Ilorin lórí gbèsè N6.3m owó eré tó gbà láì ṣe àmọ́...

Akọrin Portable to mura bii obinrin

Oríṣun àwòrán, portablebaeby/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 10

Wahala miran lo seese ko maa korajọ pọ fun gbajumọ akọrin takansufe, Habeeb Okikiola, ti ọpọ eeyan mọ si Portable.

Idi ni pe onile igbafẹ kan ti jade sita lati pe Portable lẹjọ lori ẹsun pe o gba miliọnu mẹfa ati ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira (N6.3m) lọwọ oun lai wa sere ti oun pe si ni Ilorin.

Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ Aje to kọja nile ẹjọ gba beeli Portable lẹyin ti ileesẹ ọlọpaa ni Ilorin gbe si atimọle.

Ẹsun ti wọn fi kan akọrin naa ni pe o ba gbajumọ akọrin Fuji nni, Saheed Osupa lorukọ jẹ lori ayelujara.

Amọ lẹyin ọpọ ẹbẹ, Saheed Osupa gba ẹbẹ Portable, to si ni ko maa lọ sile ni alaafia bi o tilẹ jẹ pe o nira pupọ fun Portable lati pese awọn gbedeke tile ẹjọ la kalẹ lati gba beeli rẹ.

Ni kete ti Osupa si fori jin Portable, ni onile igbafẹ naa tun fẹ mu pada si ọgba ẹwọn amọ ọpẹlọpẹ Saheed Osupa, ti ko jẹ kawọn agbofinro tun gbe Portable lọ.

Kia si ni Were Olorin naa, ẹni to mura bii obinrin wa si agọ ọlọpaa, kawọn eeyan ma baa tete da mọ, ti wọn si ti fa irun ori rẹ kodoro ninu ọgba ẹwọn to ti se ahamọ mọjumọ, ti sare ko sinu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ, to si sa lọ.

"Àti wà nínú ọgbà ilé-ẹjọ́ láti tún Portable mú, ṣùgbọ́n Saheed Osupa bẹ̀ wá ká fi yá ohun"

Eyi lo mu ki BBC News Yoruba gbera lọ si ile itura ọhun lati mọ idi ti wọn fi n wa Portable ni pato ati igbesẹ wọn lori ati mu-un.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọgbeni ti o jẹ adarí ile igbafẹ kan, Starwood 02 Arena, Ilorin, ti Habeeb Okikiola Portable jẹ ni owo N6.3 million ni diẹ loku kawọn tun were olorin naa mu ni kete ti ile ẹjọ fagile ẹsun ti Saheed Osupa fi kan an ni ọjọ Isẹgun.

Ayodele Demokun sọ pe koda ohun ti wa ninu ọgba ile ẹjọ pẹlu awọn ọlọpaa, tawọn si ti gbaradi pe ti o ba yanju iwe ominira rẹ pẹlu ile ẹjọ, awọn yoo mu lati bẹrẹ ẹjọ ni pẹrẹu lori bi yoo se da owo awọn pada.

Nigba ti adari otẹẹli naa, Ayodele n ba wa sọrọ, o ni lootọ lawọn n wa a, o si tun sọ idi ti awọn fi n waa.

Ayodele salaye pe, "ni osu kẹsan-an ọdun to kọja, ti a fẹ ṣe ifilọlẹ ẹka ile igbafẹ wa, a yan igbimọ lati joko lori olorin ti yoo wa sere, wọn si fẹnu ko pe Portable ni ki a gbe wa.

"A kan si Portable, o si ni ki ohun to le wa, a gbudọ san owo N6million fun ohun gẹgẹbi owo isẹ ati owo irinajo oun wa si Ilorin.

"Koda, o ni ka yara lati san owo naa koun to gba isẹ mii si ọjọ kan naa. A gba sii lẹnu, a si san owo ọhun fun-un.

"A bẹrẹ ipolongo lorisirisi lati pe awọn eniyan wa sibi ayẹyẹ naa."

Ẹ̀rí owo ti ile itura Starwood 02 Arena san fun Portable

Oríṣun àwòrán, Starwood 02 Arena

"Titi ti ilẹ ọjọ ariya fi su, Portable ko yọju, ṣe ni gbogbo awọn to ti ra tikẹti iwọle n yọsẹ lọkọọkan, titi ti wọn fi lọ tan"

Ayodele Demokun tẹsiwaju pe nigba to di ọjọ kọkandinlọgbon, osu kẹsan-an ọdun 2024 ti ayẹyẹ naa yoo waye, awọn ti ṣe gbogbo eto lati lọ gbe olorin naa ni papakọ ofurufu ati lati gba alejo rẹ, sugbọn, awọn ko rii.

Demokun ni "Ayẹyẹ ọhun yẹ ko bẹrẹ ni aago mejila ọsan, awọn eeyan si ti wa nikalẹ lati ago mẹwaa aarọ, ti wọn n reti Portable.

"Igba to di ago mọkanla, a pee lori ago, o si sọ pe ilu Eko ni oun wa. O ni koun to le wa, a tun gbọdọ san N600,000 gẹgẹbi owo epo.

"Bo tilẹ jẹ pe eleyi ko si lara adehun wa, a san N300,000 fun-un pe ko sa maa bọ nitori awọn alejo to n reti rẹ, pe to ba de, a o san iyoku fun-un.

"Iyalẹnu lo jẹ, wi pe titi ilẹ ọjọ yẹn fi su, Portable ko yọju, ṣe ni gbogbo awọn to ti ra tikẹti iwọle n yọsẹ lọkọọkan, titi ti wọn fi lọ tan."

Oludari ile igbafẹ naa fikun pe nigba to di aarọ ọjọ keji, ṣe ni Portable yọ de, ti wọn si ni ko da owo wọn pada pe awọn ko se mọ.

Sugbọn o bẹbẹ pe ki a tun ariya naa ṣe. O ni oun yoo kaakiri igboro ilu Ilorin lati kede fun awọn ololufẹ oun wi pe ki wọn pade oun ni Starwood 02 Arena ni dede ago mẹrin irọlẹ.

"Ibi ti Portable ti n polongo kaakiri fun ariya lo ti fi moto gba eeyan, amọ o kọ lati duro, ni wọn fi tọpasẹ rẹ wa ọdọ wa sile itura"

Demokun ni awọn tun gba si Portable lẹnu, o si lọ kaakiri lati se ipolongo gẹgẹ bi o se sọ, sugbọn o tun ṣe awọn ni kayefi pe oun pẹlu awọn janduku rẹ jọ pada si ile itura.

"Wọn ni ibi to ti n polongo kaakiri lo ti fi moto gba eeyan, amọ o kọ lati duro, ni wọn fi tọpasẹ rẹ wa ọdọ wa.

Ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa, sọja ati awọn ẹsọ alaabo ilu ti ati seto kalẹ, ni wahala ko se sọ lọjọ naa.

"Bi a se n gbaradi lati bẹrẹ ere ni Portable ba tun wa ba mi pe oun fẹ lọ jẹun ni ita, mi o gba a laye.

Idi ni pe gbogbo nkan to nilo lati pese kalẹ, mo ni gbogbo ohun to ba fẹ jẹ, la o pese fun-un, ko saa ti darukọ ẹ.

Portable yọ́ jáde ní ilé ìgbafẹ́, sá kúrò ní Ilorin.

"Igba to di bi ago mẹrin ti ere yoo bẹrẹ, a de yara ti a fi si, a o baa nibẹ. Ase Portable ti yọ jade kuro lotẹẹli, o si ti kuro ni Ilorin."

Demokun ni awọn pe Ifa Dollar, to ṣe alarina laarin awọn mejeeji, amọ onitọun ni Portable ko sọ fun oun pe oun fẹ kuro ni Ilọrin.

O ni bi Portable tun se kọju awọn soorun alẹ lẹẹkeji ni yẹn.

"A ti ṣe ohun to yẹ ni ibamu pẹlu ofin, a si ti wa ninu ọgba ile ẹjọlati mu Portable ṣugbọn Osupa pe mi lori ago wi pe ki n jọọ, ká ma tii mu ni ọtẹ yii"

Ayodele Demokun salaye pe awọn mu ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti, ẹẹmẹta ọtọọtọ ni wọn si ti ransẹ si Were Olorin amọ ti ko dawọn loun.

"Eyi lo fa a ti awa naa fi wa ni igbaradi lati mu-un to ba pari ẹjọ ti Saheed Osupa pe e, ki a ba le e gba owo wa lọwọ rẹ.

"A ti ṣe ohun gbogbo to yẹ ka ṣe ni ibamu pẹlu ofin, a si ti wa ninu ọgba ile ẹjọ ni gbogbo igba to n seto lati fagile ẹjọ rẹ lẹhin ti Osupa ti forijin.

Ṣugbọn Osupa pe mi lori ago wi pe ki n jọọ, ká ma tii mu ni ọtẹ yii.

"Osupa ni ipe to oun n gba lori ọrọ rẹ ti pọju, pe koda oun o le sun mọju lori pe ki oun forijin.

"O ni ti awa naa ba tun gbe lẹyin toun sọ pe oun forijin, aye maa ro pe oun loun tun seto bi wọn ṣe tun gbe ni.

"Ọrọ naa kọja agbara mi, sugbọn igba ti ọga wa patapata naa tun pe mi lati orile-ede Jamani pe ki n fi silẹ.

O ni nitori Osupa wi pe eto ti n lọ lori bi yoo se san owo wa pada, mo ni lati gba si wọn lẹnu.

"Bí ori ṣe ko Portable yọ le yi o" Ayodele ṣalaye.

Lakotan, ọgbẹni Ayodele sọ pe, ko si ohun ti awọn fẹ fi Portable ṣe, ju ko san owo awọn lọ.

O ni ti o ba ti san owo naa, ko le si wahala kankan nitori ko si nnkan ti awọn fẹ gba ninu fifi iya jẹ.

Àkọlé fídíò, "N kò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ilé kíkùn pẹ̀lú owó gbígbà, owó ọkọ̀ àti oúnjẹ Noodles nìkan ni wọn ń fún mi"

Àlàyé rèé lórí bí Portable ṣe jáde lọ́gbà ẹ̀wọ̀n bí alaga ẹgbẹ́ olórin ní Kwara, tó yẹ kó jẹ́ onídùróó láti gba béèlì Portable, ṣe yarí

Portable

Oríṣun àwòrán, Portable

Alaga ẹgbẹ awọn olorin, Performing Musician Association of Nigeria, PMAN, ẹka ti ipinlẹ, Alhaji Adisa Owala ti sọ wi pe ohun o lee wa se oniduro fun Badmus Habeeb Okikiola, Portable ni ile ẹjọ lai lai.

Adisa Owala sọ eyi nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ lori ago lọjọ Isẹgun, ọjọ kẹẹdogun, osu yii, ko to di pe Portable gba idande lọgba ẹwọn.

Portable ti o jẹ olorin takasufe lo n jẹjọ lọwọ lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti olorin Fuji n ni, Saheed Osupa fi kan-an.

Ni ọjọ Aje ni ile ẹjọ sọ pe ki Portable pese millionu kan naira, eeyan kan to ni dukia ori ilẹ ati alaga PMAN Kwara fun ile ẹjọ, ki wọn to lee gba beeli ati oniduro rẹ.

Ati igba naa, ni awọn ẹbi olorin naa ti n gbiyanju lati ri awọn gbendeke yii yanju sugbọn ti alaga PMAN kọ lati fi ara rẹ kalẹ gẹgẹ bi oniduro fun-un.

Portable kii se ọmọ ẹgbẹ olorin PMAN, koda, ko ni kaadi idanimọ, ìdí niyi tí mi ò fi le gba onidúró rẹ - Alaga PMAN

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, alaga PMAN ni Kwara, Alhaji Adisa Owala sọ pe, ko si ẹni to wa ba oun wi pe koun wa duro fun Portable.

"Ko si ẹni to wa ba mi sọ pe ki n wa duro fun Portable ni ile ẹjọ.

Wọn kan n ba mi sọrọ lori ago lasan ni.

"Bẹẹ si ni Portable kii se ọmọ ẹgbẹ, mo bi wọn wi pe so ni kaadi idanimọ, wọn o lee dahun.

Idi niyi ti mi o fi lee wa duro fun nitori kii se ọmọ ẹgbẹ olorin"

Lori awuyewuye wi pe Saheed Osupa ti pe alaga PMAN naa lati maa yọju si ile ẹjọ, Adisa Owala sọ wi pe ẹnikẹni to ba sọ bẹẹ, orii wi.

"Olorin fuji ni mi, olorin fuji si ni Saheed Osupa, ti wọn ba ni o pe mi ki n ma lọ duro fun-un, wọn rii wi.

"Portable kii se ọmọ ẹgbẹ, hip hop lo n kọ, fuji ni Saheed Osupa n kọ, o si tun jẹ ọmọ ẹgbẹ PMAN.

Saheed Osupa nìkan ló lè mu mi dúró fún Portable.

"Idi kan ti mo fi le duro fun Portable ni ti Saheed Osupa ba sọ pe oun ko sẹjọ mọ.

"Ti Osupa ba ni oun ko sẹjọ mọ bayii, maa yọju sile ẹjọ lati duro fun-un" Adisa Owala salaye.

Lẹyin o rẹyin, Saheed Osupa fori jin Portable, ko maa lọ ni alaafia

Saheed Osupa lo pe Portable lẹjọ ni Ilorin fun ẹsun ibanilorukọjẹ, idunkokomoni ati bẹẹ bẹẹ lọ

Lati ọjọ Aje ni wọn ti wa lori ọrọ naa, ti Portable si ti wa lati mọle ile atunse Oke-Kura ni Ilorin lẹyin to kuro nile ẹjọ lọjọ Aje.

Portable lọ naju ni ọgba ẹwọn naa nigba ti ko ri gbogbo awọn gbendeke beeli rẹ pese fun ile ẹjọ.

Amọ irọlẹ ọjọ Isẹgun ni Saheed Osupa sọ pe ohun ko sẹjọ mọ.

Agbẹjọro rẹ, Ademọla Ajasa fidi eyi mulẹ fun BBC News Yoruba.

Ajasa sọ wi pe Osupa sọ pe kawọn kọwe sile ẹjọ wí pe ohun ko se ẹjọ naa mọ.

O ni idi ni wí pe awọn eniyan ti baa ohun sọrọ lọtun losi ati wi pe aanu Portable n se ohun.

"Portable mura bi obìnrin ki awọn eeyan ma baa da mọ, o wọ aṣọ obinrin, o si fi ijaabu bo ori rẹ"

Ajasa sọ pe Portable ati awọn pẹlu awọn agbẹjọro rẹ ti pade ni ile ẹjọ, ile ẹjọ si ti fagile ẹjọ naa.

Agbẹjọro naa ni se ni Portable mura bi obìnrin ki awọn eeyan ma baa da mọ.

"O wọṣọ obinrin o si fi ijaabu bo ori rẹ.

" Bi wọn ṣe sare ṣe gbogbo rẹ papaapa ni mọto gbee sare jade" Ajasa salaye.

Bi wọn ṣe gbe Portable kuro ni ile ẹjọ ni iroyin kan, ti a ko le fidi rẹ mulẹ sọ pe ṣe ni awọn ọlọpaa fẹ tun-un mu lọna mii.

A o mọ awọn to wa nidi ẹsun tuntun yii ni pato, sugbọn o see ṣe ko jẹ igbesẹ ibudo igbafẹ Starwood 02 Arena, ti Portable jẹ ni millionu mẹfa Naira.