Wo àwọn fóònù tí WhatsApp kò ní bá ṣiṣẹ́ mọ́ láti oṣù tó ń bọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aapu WhatsApp ko ni ṣiṣẹ mọ lori awọn foonu kan lati oṣu Karun -un to n bọ, eyi yoo ṣẹlẹ lẹyin ti ileeṣẹ Meta to ni WhatsApp pinnu lati yọ irufẹ awọn foonu kan kuro lori aapu wọn.
Ileeṣẹ Meta n ṣe eyi lati daabo bawọn to n lo aapu WhatsApp ati lati ri pe awọn onibaara n gbadun aapu naa daadaa.
Aapu WhatsApp ati WhatsApp Business ni ọrọ yii kan tori amuyẹ kan naa lawọn eeyan fi n darapọ mọ mejeeji.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ Meta ṣe ṣalaye, igbesẹ yii ṣe pataki tori ki WhatsApp le maa ṣisẹ daadaa lori awọn foonu tuntun to ṣẹṣẹ jade.
Amọ, diẹ lara awọn to n lo foonu to ti jade fun bi ọdun mẹwaa ni ọrọ naa kan.
WhatsApp ko ni ṣiṣẹ mọ lori awọn iPhone kan
WhatsApp ko ni ṣiṣẹ mọ lori awọn iPhone kan to ti jade ṣaaju irufẹ foonu 15.1.
Wọnyii ni awọn iPhone ti aapu WhatsApp ko ni ṣiṣẹ mọ lori wọn:
iPhone 5s
iPhone 6
iPhone 6 Plus
Nigba ti o ṣee ṣe lati ṣe isọdọtun awọn iPhone kan, iPhone 5s, iPhone 6 ati iPhone 6 Plus ko lagbara ju iOS 12.5.7 lọ eyi ti ko si ni amuyẹ fun lilo WhatsApp.
Lọdun 2013 ati 2014 ni wọn ṣe iPhone 5s, iPhone 6 ati iPhone 6 Plus jade.
WhatsApp ko ni ṣiṣẹ mọ lori foonu Android to jade loṣu kinni ọdun 2025
Ṣaaju lọjọ kinni oṣu Kinni ọdun 2025 yii ni ileeṣẹ Meta yọ WhatsApp kuro lori foonu Android KitKat 4.4.
Awọn foonu to n lo KitKat kan si le maa ṣiṣẹ lori WhatsApp ti wọn ba le isọdọtun wọn.
Awọn foonu wọnyii ko ni ibamu pẹlu WhatsApp mọ lati ọjọ kinni oṣu Kinni ọdun 2025:
Samsung
Galaxy S3
Galaxy Note 2
Moto E (2014)
Razr HD
HTC
One X
One X+
Desire 500
Desire 601
LG
Optimus G
G2 Mini
L90
Nexus 4
Sony
Xperia Z
Xperia SP
Xperia T
Xperia V
Mini
L90
Nexus 4
Sony
Xperia Z
Xperia SP
Xperia T
Xperia V
Ileeṣẹ Meta ti rọ awọn to n lo irufẹ awọn foonu yii lati ṣe isọdọtun wọn ki wọn le maa ri aapu WhatsApp lo lọ lori awọn foonu naa.















