"Àpá tó so sí àgbọ̀n mi (Keloid) ló fa iṣẹ́ abẹ, mo lọ tan iná sójú ọgbẹ́ náà àmọ́ UCH fọ́ mi lójú"

Àkọlé fídíò, "Àpá tó so sí mi lẹ́yìn ọrùn (Keloid) ló fa iṣẹ́ abẹ, mo lọ UCH láti tan iná sójú ọgbẹ́ náà àmọ́ UCH fọ́ mi lójú"
"Àpá tó so sí àgbọ̀n mi (Keloid) ló fa iṣẹ́ abẹ, mo lọ tan iná sójú ọgbẹ́ náà àmọ́ UCH fọ́ mi lójú"

Ilera ni ọrọ, ko si si ẹda to wa nile aye ti ko gbadura fun alaafia to peye.

Ilera pipe naa ni ọkunrin yii, Ayoola Idowu wa lọ sile iwosan amọ ọtọ ni aisan to gbe lọ, ọtọ si tun ni adikun aisan to gbe pada lai ri iwosan.

Nigba to n salaye ohun to n la kọja fun BBC Yoruba, Idowu Ayoola ni abarapa, ti ara rẹ ji pepe ni oun, ki isoro yii to de.

O ni oun wa daadaa, ti oun maa n sisẹ oun deede amọ ile iwosan UCH lo sọ oun di ẹni ti ko le se ohunkohun mọ.

O ni isoro naa si lo ti gba oju lọwọ oun, koda, oun ko wulo fun nkankan mọ.

Idowu Ayoola

"Mo ti kọkọ se isẹ abẹ lati fa apa to so naa, amọ o tun pada so, ni wọn se ni ki n lọ si UCH lati lọ tan ina soju egbo naa"

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Ayoola Idowu ni apa to so jingbinni, to si ga, lo so mọ agbọn oun mọ ẹyin ọrun, ti oun ko si le yin ọrun oun.

Idi ree ti oun fi lọ sile iwosan ijọba apapọ, Federal Medical Center to wa ni ilu Owo nipinlẹ Ondo, ti wọn si se isẹ abẹ fun oun nibẹ ni ọjọ kọkandinlogun osu kẹrin ọdun 2021.

"Mo ti kọkọ se isẹ abẹ naa tẹlẹ nigba kan, amọ se ni o tun pada so, mo si sọ fun wọn nile iwosan naa.

Wọn wa sọ fun mi pe maa lọ sile iwosan UCH nilu Ibadan lati lọ tan ina soju egbo naa, eyiun Radiotheraphy, ki apa naa ma baa so mọ.

"UCH gbe mi wọ inu ẹrọ wọn, wọn tan ina si oju mi lai bo oju mi"

Ayoola tẹsiwaju pe oun lọ sile iwosan UCH lootọ lati se Radiotheraphy naa ni ọjọ kọkanlelogun.

"Mo lọ UCH lootọ, wọn gbe mi wọ inu ẹrọ wọn, wọn tan ina si oju mi lai bo oju mi.

Mo tun pada lọ lẹyin ọsẹ keji, wọn tun gbe mi wọ inu ẹrọ wọn amọ wọn bo oju mi.

A pada sile amọ nigba to di ọjọ kẹta si ikẹrin ni oju ọtun mi bẹrẹ si se baibai, ti n ko si fi ri nnkankan mọ.

Oju kan ni mo gbe pada si UCH lẹyin ọsẹ meji, mo si salaye bi oju naa ti n se.

Wọn wa sọ fun mi pe ki n salaye fun wọn nibi ti mo ti se isẹ abẹ.

Nigba ti mo pada de ile iwosan ijọba ni Owo, wọn ni Radiotheraphy lo fa ẹfọju naa, ti n ko si mọ pe oju mi osi gan si maa fọ.

Ayoola Idowu

"Mo n rọ ijọba pe ki wọn saanu fun mi lati wadi ọrọ naa, nitori n ko wulo lati se nkankan mọ bayii"

Nigba to di 2022, Ayoola ni oun ro pe se bi oun se maa ba ọrọ aye oun lọ ree, nigba ti oju mejeeji ti fọ.

"Idi ree ti mo se gbe agbẹjọro mi dide pe ko kọ iwe si UCH amọ wọn ko da mi lohun.

Igbe aye mi bayii ko dara rara, mo maa n wo ara mi pe se emi naa ree.

Mo n rọ ijọba pe ki wọn saanu fun mi lati wadi ọrọ naa, nitori n ko le se nkankan bayii.

Emi ti mo ti n jade, ti mo ti n wọle tẹlẹ wa di ẹni ti ko le da se ohunkohun mọ.

Keloid yii lasan ni mo gbe lọ sile iwosan UCH, ki wọn to fọ mi loju.

Mo wa fẹ ki ijọba ba mi gba ọrọ mi ro, ki wọn saanu fun mi."

Iwe esi UCH

BBC kan si UCH lati gbọ esi wọn lori ẹsun yii amọ

Awọn ẹsun ti Ayoola Idowu fi kan ile iwosan UCH yii lo mu wa kan sile iwosan naa lati gbọ ti ẹnu wọn, ka ma baa da bi agba osika, agbọ ẹjọ ẹnikan da.

Amọ osisẹ alarina fun ile iwosan UCH fesi ninu iwe kan to kọ pe iwadi ti bẹrẹ lori awọn ẹsun naa.

"Ẹjọ naa ti wa lọdọ ẹka ijọba to n ri si eto ilera ni Naijiria fun iwadii, a n duro de esi iwadii, a ko si le fesi kankan lori ọrọ naa."