N kò jẹ̀bi kíkun Afsot Yetunde wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ àti ẹ̀sùn mẹ́rin míràn tí ẹ fi kàn wá - Abdulrahman àtàwọn afurasí míì sọ̀ fún iléẹjọ́

Àwọn afurasi àti àwòrán Afsot Lawal

Oríṣun àwòrán, BBC/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ìdájọ́ Abdulrahman Bello bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu, àwọn ẹ̀sùn márùn-ún tí ilé ẹjọ́ kà si lọ́rùn rèé

Ìgbẹ́jọ́ Abdulrahman Bello, afurasi ti wọn fẹsun kan pe o ṣekupa Afsot Yetunde Lawal bẹrẹ nílé ẹjọ gíga ipinlẹ Kwara lonii ọjọ Iṣẹgun, ọjọ Kẹẹdogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2025.

Ṣaaju ni igbẹjọ naa ti kọkọ n waye ni ile ẹjọ Magistrate ilu Ilọrin losu keji ki ijọba to gbe ẹjọ naa lọ si ile ẹjọ giga nitori iwa ọdaran to jẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara lo kọkọ gbe Abdulrahman Bello lọ ile ẹjọ Magistrate lori ẹsun isekupa Afsot Yetunde Lawal ni ilu Ilọrin to si kun oku rẹ wẹlẹ wẹlẹ sinu ile rẹ.

Amọ nibi igbẹjọ to kọja ni ajọ eleto abo ọtẹlẹmuyẹ ti sọ pe awọn ti gbakoso ẹjọ naa lọwọ ileeṣẹ ọlọpaa lati le sewadii iṣẹlẹ lẹkunrẹrẹ.

Lẹyin eyi ni agbẹjọro ijọba ni ẹjọ naa yoo bẹrẹ ni ile ẹjọ gíga ijọba ipinlẹ Kwara lati ọjọ Kẹẹdogun oṣu Kẹrin.

Báyìí ni ìgbẹ́jọ́ náà ṣe lọ

Onidajọ Ajayi ló darí igbẹ́jọ naa loni ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Kwara ni ilu Ilọrin.

Amofin agba fun ipinlẹ Kwara, to tun jẹ kọmisona feto idajọ, Senior Ibrahim lo ṣiwaju awọn agbẹjọro bii F. B Alaya, D.T Adeleke lati ṣoju ijọba ipinle Kwara nibi igbẹjọ naa.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba ti A. S Hussein, Sulyman Alamayo, Yunusa Abubakar si ṣoju awọn afurasi.

Lẹyin afihan awọn agbẹjọro, wọn ka ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan Abdulrahman Bello ati awọn mẹrin to ku pe, lọjọ Kẹwaa, oṣu Keji ọdun yii ni wọn gbimọ pọ lati sekupa Afsot Yetunde Lawal eyi to si lodi sofin.

Adajọ bi wọn leere pe ṣe wọn jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn, gbogbo wọn si ni awọn o jebi.

Wọn tun ka ẹsun ikeji si wọn leti pe wọn sekupa Hafsoh Yetunde Lawal, wọn sì ge gbogbo ẹya ara rẹ wẹlẹwẹlẹ sinu ile.

Ẹsun kẹta ni pe wọn lo ẹya ara Hasfot Lawal ati gbigba ẹjẹ rẹ sinu rọba ti wọn si ba ẹjẹ naa ninu ile

Ẹsun kẹrin ni pe wọn ka ẹ̀yà ara èèyàn mọ wọn lọwọ.

Ẹsun karun-un ni pe iwọ Abdulrahman Bello fi pa ba Afsot yetunde Lawal lo pọ, eyi to lodi sofin.

Awọn afurasi maraarun sọ pe awọn ko jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan awọn.

Lẹyin eyi ni agbẹjoro ijọba, Senior Ibrahim ni awọn fẹ ki ile ẹjọ mu ọjọ ti igbẹjọ yóò bẹrẹ ni pẹrẹu.

Adajọ mu ọjọ Keje oṣu Karun-un ọdun yii fun gbigbọ ẹjọ naa ni pẹrẹu, ki wọn si mu awọn ẹlẹrii wá si ile ẹjọ.

Adajọ paṣẹ pe ki wọn da awọn afurasi pada si ọgbà ẹwọn Okekura ilu Ilọrin titi ti igbẹjọ naa yoo fi pari.