Bí ìgbẹ́jọ́ Alfa AbdulRahman tí wọ́n fẹ̀sùn ikú Hafsot Lawal kàn, ṣe lọ n'Ilorin

Igbejo AbdulRahman Bello, afurasi ti wọn fi ẹsun kan pe o sekupa Hafsoh Yetunde Lawal bẹrẹ pada loni ni ile ẹjọ majisreeti to wa ni ilu Ilọrin, olu-ilu ipinlẹ Kwara.
Igbẹjọ naa waye labẹ Onidajọ. S B Muhammed.
Nigba ti igbẹjọ naa bẹrẹ, agbẹjọro ijọba sọ fun ile-ẹjọ pe, iwadii ajọ alaabo otẹlẹmuyẹ DSS ti fẹ ẹ pari.
Ṣaaju ni iroyin jade ni ọsẹ diẹ sẹyin pe, awọn oṣiṣẹ ajọ DSS wa a gbe afurasi naa kuro ni ọgba ẹwọn to wa ni Oke Kura niluu Ilorin, ti wọn si gbe lọ si ibi ti ẹnikẹni ko mọ.
Agbẹjọro ijọba ni oun rọ Onidayo Muhammed pe ko faaye gba ki ẹjọ na bẹrẹ ni ile-ẹjọ giga ipinlẹ Kwara to lasẹ lati gbọ ẹjọ naa.
O salaye pe, ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹrin, ni igbẹjọ naa yoo bẹrẹ ni pẹrẹu ni ile-ẹjọ giga.
O rọ ile ẹjọ naa lati fun awọn ni ọjọ mii ti wọn yoo wa fagile ẹjọ to wa ni iwaju rẹ.
Awọn nnkan to ti ṣẹlẹ sẹyin
Nibi igbẹjọ to kọja ni agbẹjọro ijọba, Isa Sakare ti sọ fun ile-ẹjọ pe, ajọ eleto aabo otẹlẹmuyẹ DSS ti gbakoso iwadii iṣẹlẹ naa, nitori pe iwadii ti ajọ ọlọpaa se lori iṣẹlẹ ọhun, ko kun to.
O fikun ọrọ rẹ pe, ki ile-ẹjọ fun ajọ DSS laaye lati sewadi lẹkunrẹrẹ, ki igbejọ to o le tẹsiwaju, ki wọn si da awọn afurasi naa pada si ahamọ ajọ eleto abo ọlọtẹmuyẹ DSS.
Ninu ọrọ ti ẹ, agbẹjọro fun awon afurasi mẹta to ku ti wọn n jẹjọ ati agbẹjọro ẹni kẹrin rọ ile ẹjọ lati jẹ ki ẹjọ naa o tẹsiwaju ni Ile ẹjọ giga.
O ni awọn ti ṣaaju ri iwe gba pe ẹjọ yoo bẹrẹ ni ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹrin ọdun yii.
Awọn agbẹjọro naa duro wi pe ajọ ọlọpaa ti pari iwadii wọn, lo mu ki wọn gbe awọn afurasi naa wa ile-ẹjọ.
Lasiko to n ba akọroyin BBC Yoruba sọrọ, agbẹjọro awọn obi ọmọ ti wọn seku pa, Hussein Sadam ni ki iwadii naa le kun dada, ni ajọ eleto abo ọtẹlẹmuyẹ DSS ṣe gba ẹjọ naa lọwọ ajọ ọlọpaa.
O fidi ẹ mulẹ pe, wọn ko gbe Abdurahman Bello lọ Abuja, o si wa ni Ilọrin ṣugbọn ọọfisi ajọ eleto abo otẹlẹmuyẹ DSS ló wa bayii.
Kini adajọ lori ẹbẹ awọn agbẹjọro?
Nibi igbẹjọ to waye l'Ọjọru, Onidajọ Muhammed fọwọ si ki wọn fagile ẹjọ na ni ile-ẹjọ majisireeti lọjọ kejilelogun osu yii ki igbẹjọ si bẹrẹ ni ile-ẹjọ giga ipinlẹ Kwara lọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹrin bakan naa.
Gbogbo awọn agbẹjọro to wa ni ile-ẹjọ loni losi gba bẹẹ.
Oṣu to kọja ni ile-ẹjọ paṣẹ fun ajọ DSS lati fi afurasi naa ati awọn mẹrin yooku si ihamọ.
Abdurahman Bello ati awọn mẹrin mi, Ahmed Abdulwasiu, Suleiman Muyideen, Jamiu Uthman,ati Abdurahman Jamiu ni wọn jijọ jẹ jọ lori ẹsun sise kupa Hafsah Yetunde Lawal l'osu Kini ọdun 2025, ti wọn si kun un wẹlẹwẹlẹ sinu ile..
Ninu ọrọ rẹ Baba oloogbe, Ọgbẹni Lawal sọ pe ohun fara mọ gbigbe ẹjọ na lọ si ile-ẹjọ giga ipinlẹ Kwara.
O salaye pe, ohun to jẹ oun logun ju ni idajọ ododo.












