Obìnrin tí wọ́n bí láì ní ilé ọmọ, padà bímọ lẹ́yìn tí wọ́n gbé ilé ọmọ ẹlòmíì sínú rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Grace Davidson, ẹni ọdun mẹrindinlogoji (36), ko ni ile ọmọ to le fi loyun gẹgẹ bi obinrin, ṣugbọn pẹlu iṣoro yii naa, o ti bimọ bayii.
Ọmọbinrin ni Grace bi lorilẹede Britain, ibatan rẹ obinrin lo fi ile ọmọ tirẹ silẹ ni 2023, wọn si gbe e sinu Grace.
Ọmọ ti wọn gba ilana ile ọmọ ẹlomiran bi yii ni akọkọ iṣẹ abẹ iru rẹ lorilẹede Britain.
Lẹyin ọdun meji ti wọn ṣiṣẹ abẹ yii, Grace bimọ obinrin loṣu Keji.
Oun ati ọkọ rẹ, Angus, ẹni ọdun mẹtadinlogoji (37) si kun fun ayọ gidi.
Amy ni wọn sọ ọmọ wọn ọhun, wọn fi bu ọla fun ibatan Grace ti orukọ rẹ n jẹ Amy, to fi ile ọmọ tirẹ silẹ fun obinrin ti ko ni ile ọmọ rara yii.
Grace nigba to gbe ọmọ rẹ naa dani, sọ pe inu oun dun lati di abiamọ fun igba akọkọ laye oun.

Grace ati Angus ọkọ rẹ jẹ ọmọ bibi Scotland, ṣugbọn ilu London ni wọn n gbe.
Wọn tun ti n gbero lati bi ọmọ keji bayii, nitori ẹnikan tun ti fi ile ọmọ silẹ fun Grace lati gbe oyun rẹ.
Awọn tọkọ-taya yii ko kọkọ fẹẹ sọ ohun to n ṣẹlẹ laye e wọn fun gbogbo aye, ṣugbọn lẹyin ti wọn bi Amy, wọn pinnu lati ba BBC sọrọ lori ọmọbinrin wọn kekere naa.
A ti ṣe iṣẹ́ abẹ mẹ́ta nípa lílo ilé ọmọ àwọn obìnrin tó ti kú- Àwọn dókítà

Oríṣun àwòrán, WTUK
Nigba ti wọn n sọrọ lori iṣẹ abẹ ile ọmọ ti wọn n gbe sira wọn yii, awọn dokita to ṣiṣẹ abẹ fun Grace, ṣalaye pe awọn ti ṣe mẹta iru rẹ mii, to si jẹ ile ọmọ awọn obinrin to ti ku ni awọn lo.
Wọn ni afojusun awọn ni lati gbe ọlẹ ọmọ mẹẹdogun sinu awọn iya lasiko tawọn n dan iṣẹ abẹ naa wo lọwọ .
Grace ti wọn ṣiṣẹ abẹ fun yii, jẹ obinrin ti wọn bi pẹlu aisan kan ti wọn n pe ni 'Mayer-Rokitansky-Küster-Hauser' (MRKH) syndrome, eyi ti wọn yoo bimọ obinrin ṣugbọn ti ko ni i ni ile ọmọ.
Nigba ti BBC kọkọ ba wọn sọrọ ni 2018, Grace ro pe mama oun ni yoo fi ile ọmọ tirẹ silẹ ni, ṣugbọn wọn pada ri i pe ile ọmọ iya naa ko ba ti Grace mu.
Ṣugbọn ti ibatan rẹ, Amy Purdie, ni awọn dokita ri i pe o pada le ṣiṣẹ.
Wọn ṣalaye fun wọn nigba naa nipa iṣẹ abẹ yii ati ohun gbogbo to da le lori ki wọn to o ṣiṣẹ abẹ naa
Amy to ran Grace lọwọ yii ti bimọ meji ni tiẹ pẹlu ọkọ rẹ, wọn ko si fẹẹ bimọ mọ.
Grace funra rẹ ṣalaye pe wọn beere pe ṣe oun yoo jẹ ki wọn ba oun gbe ọmọ naa ni abi oun yoo lọ ọ gba ọmọ tọ.
Kí n finú mi gbé oyún fúnra mi ló wù mi- Grace

Oríṣun àwòrán, WTUK
"Ipinnu to ṣe pataki si mi ju ni pe ki n finu mi loyun ki n si gbe e funra mi.
"O ti wu mi tipẹ lati di iyalọmọ, ṣugbọn mo gba kamu nitori ipo ilera mi."
Grace lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.
Dokita bii ọgbọn (30) lo ṣiṣẹ lara Grace lasiko iṣẹ abẹ ti wọn fi gbe ile ọmọ miran si ara rẹ loṣu Keji, ọdun 2023.
Wakati mẹtadinlogun ni wọn fi gbe ile ọmọ Amy si inu Grace.
Iṣẹ abẹ naa ni wọn pada fi bi ọmọ ikoko ti wọn sọ ni Amy, nileewosan Queen Charlotte's, to wa ni West London, lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Keji.
Grace ati ọkọ rẹ ni awọn yoo bimọ keji bawọn dokita ba ti ni Grace ti le loyun mii.
Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, wọn yoo yọ ile ọmọ naa kuro bi Grace ba ti bimọ lẹẹmeji.
Eyi yoo fun un ni anfaani lati dawọ oogun to n lo lojoojumọ ki ile ọmọ naa le ṣe rẹgi pẹlu ara a rẹ, duro.
Lilo oogun yii lojoojumọ le fa jẹjẹrẹ, paapaa to ba lo o fun ọpọlọpọ ọdun.
Ṣugbọn Dokita Isabel Quiroga, sọ pe ewu to ro mọ jẹjẹrẹ yoo fo Grace da, to ba ṣiwọ awọn oogun naa ni lilo.














