Ọlọ́pàá ya bo ilé tí wọ́n ti ń ṣòwò ọmọ títà l'Eko, dóòlà ọmọdé mẹ́ta

Police

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinle Eko ti ṣawari ile kan ti awọn obinrin ti n bi ọmọ fun tita lagbegbe Ijegun.

Ọlọpaa doola eeyan mẹwaa nibẹ, o si fi ṣikun ofin mu afurasmi mẹta.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin sọ pe akara awọn to n ṣiṣẹ laabi naa tu sepo lẹyin ti awọn araalu sin awọn ni gbẹrẹ ipakọ.

Hundeyin ni kete ti ọrọ naa to awọn leti lawọn lọ fi ofin gbe awọn afurasi naa; Mariam Vincent, to jẹ ẹni ọdun marundinlogoji, Orie Ruth, to jẹ ẹni ọdun mẹtalelogun ati Ujunwa Ifeanyi to jẹ ọmọ ọdun mejidinlogun.

Lapapọ, agbalagba meje ati ọmọde mẹta ni wọn doola nibẹ.

Gẹgẹ bii ohun ti ọlọpaa sọ, awọn ti wọn doola ni Precious, Magdalene, Adaobi, Princess, Ifeanyi ati Amaka, ti ọjọ ori wọna wa laarin ọdun mejilelogun si ọdun marundinlọgbọn.

Ọlọpaa tun doola ọmọ ọdun meji, ọmọ ọdun marun un ati ọmọ ọdun meji mii nibẹ.

Gẹgẹ bii alaye Hundeyin, gbogbo awọn ti ọlọpaa doola lo ti n gba itọju to peye bayii.

Yatọ si awọn to n ṣowo ọmọ tita yii, Hundeyin ni ileeṣẹ naa nipinlẹ ọhun tun ti ṣe awọn aṣeyọri mii latari bi ọwọ wọn ṣe tẹ oniruru ọdaran lẹnu lọlọ yii.

Lara awọn aṣeyọri naa ni bi ọwọ ọlọpaa ṣe tẹ awọn ajinigbe lagbegbe Ikorodu, to fi mọ awọn afipabanilopọ.

Ko tan sibẹ, o ni awọn tun mu awọn afurasi to ni ohun ija oloro lọwọ lọna aitọ, ẹni to ji ọmọ kekekre gbe atawọn adigunjale.

Hundeyin pari ọrọ rẹ pe gbogbo afurasi naa ni yo foju bale ẹjọ lẹyin ti iwadii ẹsun wọn ba ti pari.