Kí ló mú kí àrá sán pa ọ̀pọ̀ màálù l'Ondo, tí ariwo fi sọ? Ohun tí a mọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Others
Lọjọ Aiku, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin ọdun 2025 ni ara kan to ya ọpọ eeyan lẹnu, san lagbegbe Ori-Ohin, Ifon, nipinlẹ Ondo, to si pa maalu ti ko din ni mẹfa.
Ijọba ibilẹ Ose ni iṣẹlẹ naa ti waye, ohun ti awọn agbaagba ilu naa si n sọ ni pe awọn Fulani darandaran lo ti huwa ibajẹ si ori ilẹ, eyi to fa a ti ara fi san pa maalu wọn.
Bo tilẹ jẹ pe ko si ẹni to le fidi eyi mulẹ, ohun ti a gbọ ni pe ilẹ Ori-Ohin jẹ ibi kan ti awọn ẹya Ebira, lati ipinlẹ Kogi ti n dako, ṣugbọn wọn ki i ri ere oko naa ko nitori awọn afurasi Fulani to n fi maaluu jẹ oko naa.
Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ, to jẹ olugbe agbegbe ọhun, ṣalaye pe o ti pẹ ti awọn darandaran ti n ko maaluu wọ inu oko ni Ori-Ohin, ti wọn si n ba iṣẹ oko awọn agbẹ jẹ.
O ni o jọ pe ẹbọ ti awọn agbẹ pese sori ilẹ naa lo fa ara to san pa awọn maalu.
Bakan naa ni awọn kan sọ pe awọn agbẹ Ebira ko ṣee ba ṣe erekere ti awọn darandaran n ṣe ninu oko pẹlu fifi maalu jẹko.
Wọn ni eyi lo jẹ kawọn Ebira ṣe ipese to le pa awọn maaluu naa ti awọn Fulani ko si ni i le wọbẹ mọ.
Kí ni ọlọpaa Ondo wí?
BBC Yoruba kan si Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Alayande Olushola Adeyinka, lati fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.
Alayande sọ pe, "Mo le fidi ẹ mulẹ fun yin pe ara san lalẹ ọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin ọdun 2025, o si pa maaluu bii mẹfa .
"Eyi waye nitori ojo nla to rọ lọjọ naa ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ alẹ.
"Amuwa Ọlọrun ni iṣẹlẹ naa, ko ṣee maa ro pe nnkan kan lo fa a.
"Nigba to ṣẹlẹ, DPO agbegbe ọhun pe awọn olori Fulani darandaran ati awọn ọba alaye ibẹ lati lawọn loye, pe amuwa Ọlọrun ni, ti a ko le sọ pe eeyan kan lo fa a.
"O rọ wọn lati ma ṣe fa wahala kankan lori iku awọn maalu naa, ki wọn si ma ṣe huwa ti yoo da omi alaafia ilu ru"
Alukoro ọlọpaa Odò ni awọn ko ri iṣẹlẹ naa bi eyi to le fa wahala.
O ni awọn ọlọpaa ti wa nigboro lati ọsẹ meji sẹyin, ti wọn n ri i daju pe rogbodiyan kankan ko ṣẹlẹ.
Èyí kọ́ ni ìgbà àkọ́kọ́ tí àrá yóò sán pa màálù l'Ondo
Ni 2019, irufẹ iṣẹlẹ yii waye ni Oke-Owa, eyi to wa ni ilu Ijare, nijọba ibilẹ Ifedore, ipinlẹ Ondo.
Maalu mẹrindinlogoji (36), ni ara san pa nigba naa.
Ohun ti awọn ara abule sọ nigba naa ni pe awọn alalẹ lo n binu.
Ko ju oṣu kan lọ lẹyin eyi ti ara tun fi san pa awọn maalu ni Oyinmo quarters, Ikare Akoko ti i ṣe olu-ilu ijọba ibilẹ Ariwa Akoko, nipinlẹ Ondo.
Maalu mẹjọ ni ara ojiji kan tun san pa lori oke kan nigba naa.
Awọn maalu ọhun n jẹko ni lasiko ti ara san, to si pa wọn, ẹsẹkẹsẹ ni awọn Fulani to da wọn lọ sibẹ si fẹsẹ fẹẹ.

























