Ìdí táwọn ọkùnrin fi ń kú ikú àìtọ́jọ́ ju àwọn obìnrin lọ àti ọ̀nà àbáyọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn onimọ nipa eto ilera ti sọ pe iwadii ti fidi rẹ mulẹ wi pe awọn ọkunrin n ku iku aitọjọ ju awọn obinrin lọ.
Ibeere tawọn akọṣẹmọṣẹ lẹka eto ilera n beere ni pe ko lo ṣokunfa iṣoro ailera yii fawọn ọkunrin ati pe ki ni ọna abayọ?
Iwadii awọn onimọ nipa eto ilera fi han pe ọpọ awọn ọkunrin lo n ṣe awọn nnkan to le ṣakoba fun ilera wọn.
Bakan naa ni iwadii ọhun tun fidi rẹ mulẹ pe ọpọ ọkunrin ni ko bitika lati wa itọju lọ si ile iwosan nibi ti wọn ti le gba itọju.
Iku aitọjọ
Fun apẹẹrẹ, awọn ọkunrin lorilẹede UK maa n fa siga, mu ọti, bakan naa ni wọn maa n lo ogun oloro.
Ọpọ ninu awọn ọkunrin yii ni iwadii sọ pe aisan ẹjẹ ruru n ba finra.
Awọn nnkan wọnyii lo n ṣapejuwe idi tawọn ọkunrin fi n tete ku ju awọn obinrin lọ.
Iwadii kan fi han pe ida 60% awọn ọkunrin ni UK lo ṣee ṣe ki wọn ku nigba ti wọn ba pe ẹni ọdun marundinlọgọrin pẹlu arun ọkan, arun jẹjẹre fuku ati arun inu ẹdọ.
Iwadii naa tun sọ pe irufẹ awọn ọkunrin yii naa ni wọn tun maa n ku ninu oniruuru ijamba.
Ọjọgbọn Alan White to jẹ ọkan lara awọn to da ajọ ti kii ṣe ti ijọba to n ri si ọrọ ilera awọn ọkunrin silẹ sọ pe ọrọ naa n fẹ amojuto ni kiakia.
Ọjọgbọn White fi ajakalẹ arun covid-19 ṣe apẹẹrẹ pe ẹgbẹrun mọkandinlogun ni iye awọn ọkunrin ti Covid-19 pa fi ju awọn obinrin lọ.
Ọjọgbọn White sọ pe ailera yii ko ni ṣe pẹlu iru igbeaye tawọn ọkunrin n gbe nikan, o ni ọrọ naa lagbara ju bẹẹ lọ.
Iyatọ laarin ara ọkunrin ati obinrin
Ọjọgbọn White sọ pe ara obinrin le kọju ija si arun ju ara awọn ọkunrin lọ.
''Ọpọ ọkunrin ni kii sọ nipa eto ilera wọn, bakan naa ni wọn kii tete gbe igbesẹ lori awọn apẹẹrẹ arun kan tabi omiran ti wọn ba ti ri.
Oju kan naa ni eto ilera ọpọ ọkunrin maa n wa lati akoko ti wọn ba ti balaga titi ti wọn yoo fi ju ọmọ ogoji ọdun lọ.
Ọpọ ninu awọn ọkunrin ni ko de ile iwosan fun ayẹwo ara wọn fun ọpọlọpọ ọdun.
Ara awọn obinrin yatọ. Awọn obinrin maa n lọ fun oriṣiiriṣii ayẹwo.
Ọmọ bibi tun tumọ si pe awọn obinrin maa n ri awọn dokita ju ọkunrin lọ,'' Ọjọgbọn White lo sọ bẹẹ.
Mark Brooks to jẹ oludamọran lori ọrọ awọn ọmọdekunrin atawọn agba ọkunrin naa sọ pe bi awọn ọkunrin ṣe maa n ri ara wọn naa wa lara nnkan to n ṣakoba fun ilera wọn.
Brooks ni gbagbọ ọpọ eeyan lawujọ ni pe ibi to ba le la n ba ọmọkunrin.
O fi kun ọrọ rẹ pe nigba mii, awọn ọkunrin kii lanfaani si eto ilera bi awọn obinrin.
Fun apẹẹrẹ, eto ayẹwo ti ajọ eleto ilera NHS n ṣe lọdun marun-un marun-un fawọn ti ọjọ ori wọn bẹrẹ lati ogoji ọdun si ọdun mẹrinlelaadọrin jẹ ọna kan ti ijọba fi n ṣe iranwọ lati gbogun ti awọn arun to n ge ẹmi ọpọ ọkunrin kuru.
Amọ, mẹrin ninu mẹwaa awọn ọkunrin lo le jẹ anfaani yii.
Ọgbẹni Brooks sọ pe ''ọkunrin to n ṣiṣẹ nibi ti wọn ti n kọ ile ko le ri aye lati lọ fun ayẹwo ara rẹ tabi lati lọ ri dokita nile iwosan.
Iyatọ laarin ẹya tabi iran naa ni ṣe pataki pẹlu iru arun to maa n ṣe awọn ọkunrin.
Fun apẹẹrẹ, iwadii sọ pe awọn alawọdudu ti wọn n gbe ni UK maa n saba ni arun jẹjẹrẹ woropọn nigba tawọn ọkunrin to wa lati orilẹede India tabi Bangladesh maa n ni arun itọ ṣuga.
Ọna abayọ fawọn ọkunrin lori eto ilera wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọjọgbọn Paul Galdas to jẹ onimọ nipa eto ilera awọn ọkunrin ni ile ẹkọ giga fasiti New York sọ pe awọn ọkunrin ni lati taji lori ọrọ ilera wọn.
Ọjọgbọn Galdas sọ pe eto iranwọ kan ti wa fawọn ọkunrin lorilẹede UK lati maa ṣe akiyesi ipa ti ihuwasi wọn n ni lori ero wọn.
O ni awọn ọkunrin ni lati maa ṣe akiyesi awọn nnkan ti wọn n ṣe pẹlu agọ ara wọn.
''O le jẹ pe ki wọn kan maa rin kaakiri adugbo, tabi ki wọn lọ ri awọn ọrẹ wọn.
Wọn le ṣe ere idaraya pẹlu, koda, wọn tun le maa kọ ẹkọ lati wa ojutuu si iṣoro eyi ti yoo daabo bo ilera ọpọlọ wọn.
Ọjọgbọn White ni asiko itaniji niyii fawọn ọkun lori ọrọ ilera wọn.
''O le jẹ wi pe irin ni iwọ le maa gbe eyi ti yoo jẹ ki ara rẹ duro deede.
Ti o ba yọ ikun banba, o ni lati wa nnkan ṣe si i.
O le maa rin kaakiri ki o maa lọ, ki o maa bọ, ki o si maa bawọn eeyan sọrọ bi o ti n rin yii.
Gbiyanju lati maa lọ fun ayẹwo ara rẹ loorekoore. Ti o ba ri nnkan to ku diẹ kaato ninu ara rẹ, tete wa iranwọ lọ sọdọ awọn dokita,'' Ọjọgbọ White ṣalaye.















