Taa ni gbajúgbajà Wòólì Kekere Jesu tí ikú rẹ̀ n milẹ̀ tìtì lórí ayélujára?

kekere Jesu

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Mọlẹbi ati ọrẹ gbajugbaja olorin ẹmi, to tun jẹ oniwaasu, Ayodeji David, ẹni ti ọpọ mọ si Kekere Jesu ni wọn ti wa ninu ibanujẹ bayii lẹyin to pade iku ojiji ninu ijamba ọkọ.

Kekere Jesu, ogbufọ rẹ, Iyanu Joseph ati eeyan mejilelogun mii lo padanu ẹmi wọn ninu ijamba to waye loju opopona Sagamu si Ibadan, nipinlẹ Ogun.

Isaac Morianugba, ọkunrin kan to sunmọ oloogbe gbe soju opo ayelujara Facebook pe, Kekere Jesu, Iyawo afẹsọna rẹ, Iyanuoluwa ati iyawo ẹgbọn rẹ kan, lo padani ẹmi wọn ninu ijamba naa.

Morianugba ni ko ki n ṣe igba akọkọ rẹ ti Kekere Jesu yoo ṣagbako ijamba ọkọ ṣugbọn eyi jẹ ohun ti Ọlọrun lọwọ si.

"Laipẹ yii ni mo wa ninu ijamba ọkọ pẹlu oloogbe pẹlu igbakeji rẹ, ti ori si ko wa yọ ṣugbọn bayii, ko si mọ.

"Ki Ọlọrun tẹ wọn si afẹfẹ rere."

Woli Sam Olu Alo ni, iroyin iku Kekere Jesu jẹ ohun to ba ọpọ lojiji ṣugbọn wọn ko le da Ọlọrun lẹbi.

Adesanya Idowu ni ana ode yii ni Oloogbe gbe fọnran sita nibi to ni ki awọn eeyan gba adura lori iku ojiji.

"Wakati diẹ ṣeyin, ẹni Ọlọrun, Woli Ayodeji Kekere Jesu, iyawo rẹ, olutuọrọ rẹ, Iyanu Joseph ati iya wa ninu oluwa, Iyafin Matanmi padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ"

Oloogbe ni ori ko yọ ninu ijamba ọkọ lọdun 2022.

Lara awọn akọsilẹ ti BBC ri nipa oloogbe naa, ọmọde lo wa nigba to ti bẹrẹ iṣẹ iranṣẹ, ti awọn ile ijọsin si ma n pe e si isọji.

Koda, Kekere Jesu ma n ṣe awọn isọji alagbeka kaakiri awọn ile ẹkọ giga.