Èèyàn méje pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàm̀bá ọkọ̀ lójú ọ̀nà márosẹ̀ Eko sí Ibadan

Oríṣun àwòrán, FRSC
Apapọ eeyan meje lo pade iku ojiji ninu iṣẹlẹ ijamba ọkọ to waye loju ọna marosẹ Eko si Ibadan.
Iṣẹlẹ naa lo waye ni owurọ ọjọ Ṣatide, ọjọ karun un oṣu kẹrin ọdun 2025, ti eeyan mẹrin miiran si tun farapa yanayana.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ninu atẹjade to fi lede, agbẹnusọ ajọ to n ri si oju ọna lorilẹede Naijiria, Florence Okupe apapọ eeyan mẹdogun ti wọn jẹ ọkunrin mẹtala ati obinrin meji lo waye ninu ijamba ọkọ naa.
Ninu awọn eeyan mẹdogun naa, mẹrin farapa yanayana (ọkunrin mẹta ati obinrin kan), ti eeyan mẹje (ọkunrin mẹfa ati obinrin kan) si padanu ẹmi wọn.
Okupe ni ere aṣapajude jẹ ọkan gboogi ohun to ṣokunfa ijamba na.
"Awọn to farapa ti w ani ile iwosan Divine Touch to wa Ni Ibafo, ti a si tig be oku lọ si ile igbeoku si to wa ni Sagamu.
"Awọn ọkọ ti ijamba naa ṣẹlẹ si ni a tig be kuro loju ọna lati ma fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ.
"Ọga agba FRSC, Fasakin Akinwumi ṣabẹwo si bi iṣẹlẹ naa fun iwadii, to sib a awọn mọlẹbi to padanu eeyan wọn kẹdun."
Ọna marosẹ Eko si Ibadan jẹ ọna kan ti ọpọ ijamba ọkọ ti ma waye lorilẹede Naijiria.















