Àdó olóró Russia pa ọmọdé mẹsàn án ní Ukraine, ọ̀pọ̀ farapa yánayàna

Oríṣun àwòrán, Володимир Зеленський
Ado oloro Russia to balẹ siluu Kryvyi Rih, ni Ukraine, ti pa eeyan mejidinlogun o kere tan, ti ọpọ awọn mii si farapa.
Iroyin ni ilu ti wọn ti bi Aarẹ Volodymyr Zelensky gangan ni iṣẹlẹ ọhun ti waye.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Zelensky ni ọmọde mẹsan an lo wa lara awọn to ba iṣẹlẹ ọhun lọ.
Awọn aworan to jade lati ibẹ ṣafihan ẹnikan to sun nilẹ nigba ti fidio mii ṣafihan ile alaja mẹwaa kan ti apakan rẹ ti parun, ti ọpọ eeyan si sun nilẹ.
Lẹyin ikọlu naa ni ileeṣẹ ologun Russia sọ pe oun sọ ado oloro si ipade awọn olukọni ologun to n waye nile ounjẹ kan nibi ti nnkan bii eeyan marundinlaadọrun ti jae laye.
Amọ ileeṣẹ ologun Ukraine ti fesi pe irọ ni Russia n pa lọna ati bo awọn iwa ọdaran to n fi ogun aarin wọn wu mọle.
Ikọlu yii jẹ ọkan lara eyii to buru julọ ti Russia ti ṣe siluu Kryvyi Rih ni Ukraine lati igba ti ogun naa ti bẹrẹ lọdun 2022.
Ikọlu yii lo tun waye lasiko ti Aarẹ Amẹrika, Donald Trump n pe ipe jogunomi laarin orilẹede mejeji.
Zelensky kọ loju opo ayelujara rẹ pe, o kere tan, ile marun un lo ba ikọlu tuntun naa lọ.
O ni "Ko si eredi mii ti Russia fi n wu iwa yii, ko fẹ ki ogun naa pari."
Olori eto abo lagbegbe Kryvyi Rih, Oleksandr Vilkul, sọ pe ile gbigbe awọn eeyan ni ado oloro ọhun ti ṣọṣẹ.
Vilkul sọ pe "Oju ofurufu ni ado oloro naa ti bu gbamu.... lọna ati ṣe ipalara fun ọpọ eeyan... awọn ọmọde to n ṣere lagbegbe ibẹ tun padanu ẹmi wọn."















