Wo bí o ṣe lè ṣírò owó orí tàríìfù tí Trump gbé sórí ọjà tó ń wọ Amẹ́ríkà látì ilẹ̀ òkèèrè

Aworan Aarẹ Donald Trump

Oríṣun àwòrán, EPA

    • Author, Ben Chu & Tom Edgington
    • Role, BBC Verify
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ Donald Trump orilẹede Amẹrika ti gbe owo ori tariifu ida 10% lori awọn ọja to n wọ Amẹrika lati ilẹ okeere.

Koda, tariifu yii ju ida 10% lọ lawọn orilẹede ti iroyin sọ pe ''wọn ti ta ẹṣẹ agẹrẹ.''

Amọ, bawo ni eeyan ṣe le ṣe iṣiro tariifu to wa lori ọja to n wọ Amẹrika lati ilẹ okeere yii? BBC Verify to n ṣe iwadii ṣe alaye lori iṣiro naa.

Ki ni awọn iṣiro tariifu yii?

Nigba ti Trump n sọrọ lori owo ori tariifu naa ni White House, ọpọ lo ro pe awọn tariifu to wa nilẹ tẹlẹ ni.

Amọ, nigba to ya ni ileeṣẹ ijọba Amẹrika fi iwe kan lede lori tariifu naa eyi to jẹ iṣiro to lamilaaka.

Fọmula iṣiro tariifu ti White House ṣe

Oríṣun àwòrán, White House

Atupalẹ fọmula to wa loke fi han pe o da lori iṣiro: a kọkọ maa ṣe iṣiro iye ọja to n wọ Amẹrika lati ilẹ okeere, a o wa pin si ọna meji.

Fọmula yii tun n wo owo ori tariifu lori iye ọja ati ipa ti iru tariifu naa yoo ni lori iye ọja.

Gbese okowo maa n ṣẹlẹ nigba ti ọja ti orilẹede ba n ra lati orilẹede mii ba ju eyi to n ta si iru orilẹede naa lọ.

Fun apẹẹrẹ, ọja ti Amẹrika n ra lati China ju eyi to n ta si orilẹede naa lọ.

$440bn ni iye ọja ti Amẹrika n ra lati China eyi ti gbese okowo wọn si jẹ $295bn.

Ti a ba wa pin 295 sọna 440, yoo fun wa ida 67%, eyi ni a pin si meji.

Iṣiro yii yoo fun wa tariifu ida 34% ti Amẹrika gbe le ori owo ọja to n wọ Amẹrika lati China.

Girafu BBC to ṣafihan iṣiro tariifu

Ṣe Amẹrika n fi tariifu Trump gbẹsan ni?

Ọpọ onwoye nipa ọrọaje lo ti sọ pe kii ṣe nitori pe awọn orilẹede gbe owo ori trariifu le ọja ti wọn n ko lọ Amẹrika ni Trump fi kede tariifu lori ọja to n wọ Amẹrika bayii.

Amọ, ileeṣẹ ijọba White House so pe awọn ko tii ṣe iṣiro lori tariifu lori awọn orilẹede tọrọ kan.

Ileeṣẹ aarẹ ni iṣiro tawọn sẹ da lori bi gbese okowo Amẹrika yoo ṣe dopin.

Trump ti kuro lori ilana lilo fọmula gbigbe owo ori tariifu sori awọn orilẹede ti wọn n ra ju ọja ti wọn n ko lọ Amẹrika lọ.

Fun apẹẹrẹ, Amẹrika ko ni gbese okowo pẹlu UK, sibẹ, ijọba Trump ti gbe owo ori tariifu ida 10% sori ọja to n wọle lati UK.

Lakotan, nnkan bii ọgọrun orilẹede ni ọrọ tariifu yii kan.

''Ipa to lagbara ti tariffu tuntun yoo ni''

Trump ni igbagbọ pe Amẹrika ko maa ṣowo jere daadaa ninu okowo agbaye.

Ero Aarẹ Trump ni pe ọpọ orilẹede lo n ko oniruuru ọju pọọku lowo ẹ wọ Amerika eyi to si n ṣakoba fawọn ileeṣẹ ati iṣẹ tawọn araalu le maa ṣe.

Bakan naa lawọn orilẹede yii ko faye gba Amẹrika lati maa dokowo daadaa nilẹ okeere.

Nitori naa, Trump n lo tariifu yii lati ṣe itaji awọn ileeṣẹ Amẹrika ati lati daabo bo iṣẹ awọn eeyan.

Aworan awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ti wọn ti n ṣe ọkọ

Oríṣun àwòrán, Reuters

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Amọ, njẹ o ṣee ṣe ki erongba ijọba Amẹrika wa si imuṣẹ pẹlu tariifu yii?

Ẹka to n ṣe iwadii BBC Verify ba awọn onimọ nipa ọrọaje sọrọ, ohun ti ọpọ wọn ro ni pe o ṣee ṣe ki adinku ba gbese okowo Amẹrika atawon orilẹede ilẹ okeere tọrọ kan pẹlu tariifu tuntun.

Amọ, wọn ni tariifu yii ko le mu adinku ba gbese okowo Amẹrika pẹlu gbogo agbaye.

Ọjọgbọn Jonathan Portes lati King's College ni London sọ pe ''loootọ ni pe yoo mu adinku ba gbese okowo laarin Amẹrika atawọn ti ijọba gbe owo ori tariifu tuntun le lori, amọ, awọn ipa to lagbara kan wa ti igbesẹ naa yoo ni eyi ti ko si ninu iṣiro ijọba.''

Awọn onimọ nipa ọrọ aje fidi rẹ mulẹ pe ọpọ eeyan l'Amẹrika lo n na owo ti wọn si n dokowo ju owo oṣu wọn lọ.

Eyi tumọ si pe Amẹrika n ra nnkan lati ilẹ okeere ju nnkan ti wọn n ta si ilẹ okeere lọ.

Awọn onimọ nipa ọrọ-aje naa sọ pe niwọn igba ti eyi ba si n ṣẹlẹ, Amẹrika ko ni ṣai ma ni gbese okowo laarin rẹ atawọn orilẹede to ba dowo pọ.

Thomas Sampson lati ile ẹkọ giga imọ nipa ọrọ-aje sọ pe ''fọmula ti ileeṣẹ aarẹ Amẹrika fi n ṣe iṣiro tariifu tako alakalẹ eto ọrọ-aje, o si maa pa eto ọrọ-aje agbaye lara.''