Afurasí obìnrin kan gún àbúrò rẹ̀ pa, ṣe ìyá rẹ̀ àti ọmọ àbúrò rẹ̀ léṣe

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Iroyin to tẹ wa lọwọ lati ipinlẹ Enugu ti fi idi rẹ mulẹ pe afurasi obinrin kan, Oluchukwu Odo, ti gun aburo rẹ obinrin pa, ti o si tun ṣe iya ati ọmọ aburo rẹ leṣe.
Laarọ Ọjọru ọjọ keji oṣu Kẹrin yii ni deedee ago meji oru ni a gbo pe iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ niluu Umuidenyi Aji Enugu Ezike to wa ni ijọba ibilẹ Ariwa Igbo Eze nipinlẹ Enugu.
Akọroyin kan ti ko fẹ ka da oruko rẹ, ẹni to ba iya Oluchukwu sọrọ ṣalaye pe ifọrọwanilẹnuwo toun ṣe pẹlu mama naa fidi rẹ mulẹ pe Olochukwu fun iya rẹ ni ọti ẹlẹrindodo mu, o si fun aburo rẹ obinrin naa mu pẹlu.
O ni lẹyin iṣẹju meloo kan ni Oluchukwu bẹrẹ si ni wo o boya iya ati aburo rẹ obinrin ti n sun.
Akọroyii naa ṣalaye pe nigba ti Oluchukwu ri pe iya rẹ ti sun, o lọ mu ọbẹ, ti o si fi gun iya rẹ ni ori ati ọrun.
''Iya Oluchukwu ke irora lati oju oorun, o si sa asala fun ẹmi rẹ.
Bayii ni Oluchukwu wọ yara ti aburo rẹ sun si pẹlu ọmọ rẹ.
Nibẹ ni Oluchukwu ti gun aburo rẹ lọbẹ pa ti o si tun gun ọmọ rẹ naa lọbẹ lọrun,'' akọroyin naa ṣalaye.
Lẹyin naa ni wọn gbe iya Oluchukwu ati ọmọ-ọmọ rẹ lọ si ile iwosan nibi tawọn mejeeji ti n gba itọju.
Fidio kan to lu ori ayelujara pa ṣe afihan bi awọn ọlọpaa ṣe n fọrọ wa Oluchukwu lẹnu wo lori iṣẹlẹ naa.
Ohun to sọ fawọn ọlọpaa ni pe Eṣu lo wọ inu oun lo jẹ koun ṣe nkan toun ṣe.
A si n reti ẹkunrẹrẹ alaye lati ọdọ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Enugu, Daniel Ndukwe, lori iṣẹlẹ naa.















