Ṣé lóòtọ́ọ́ ní pé gbèsè ló lé Segun Olanrewaju, abẹ̀sẹ́kùbíòjò tó kú lójú ìjà, padà sídìí ẹ̀ṣẹ́ kíkàn? Àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ sọ̀rọ̀

Aworan Segun Olanrewaju

Oríṣun àwòrán, Brila FM/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2025 yii ni Segun 'Success' Olanrewaju di ẹru lọ si orilẹede Ghana fun idije ẹṣẹ kikan pẹlu ireti pe yoo pada wale pẹlu owo.

Amọ oku rẹ ni wọn gbe tọ awọn ẹbi rẹ lẹyin idije ọhun.

Ni ṣe ni ẹni ogoji ọdun naa ṣubu nibi ti n ja lọwọ pẹlu Jon Mbanugu ni gbagede ija, to si gba ibẹ dagbere faye.

Iroyin ni oloogbe ọhun lo n lewaju ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun, ki iṣẹlẹ laabi naa to waye.

Fidio ija naa to wa lori ayelujara ṣafihan bi Success ṣe n gbiyanju lati ju ẹṣẹ, to si n ṣe bii ẹni ti okun ko si ninu rẹ mọ, ko to sadede ṣubu lulẹ laarin ija.

Gbogbo igbiyanu awọn alakoso ija naa lati gbe dide lo ja si pabo, ki wọn to gbe digba-digba lọ ile iwosan Korle Bu Teaching Hospital, nibi ti wọn ti kede pe ẹlẹmi ti gba a.

A ko fọwọ si ija naa – ijọba Naijiria

Ajọ to n ṣakoso ẹṣẹ kikan ni Naijiria, Nigeria Boxing Board of Control, sọ pe oun ko fọwọ si ija ti oloogbe naa ti padanu ẹmi rẹ.

Akọwe ajọ ọhun, Remi Aboderin, sọ fun akọroyin Punch pe ọtọ ni ija ti awọn fọwọ si fun ko lọ ja ni Ghana amọ ija naa ko waye latari pe o ti sanra ju fun ẹni to yẹ ko koju.

Aboderin ni o ti n pada bọ ni Naijiria ko to yan lati kopa ninu ija mii latari pe yoo ri $500 nibẹ lọna ati gbọ awọn bukata iwaju rẹ.

O ni "Segun sọ fun olukọni to wa pẹlu rẹ pe ko ni rọrun fun oun lati pada wale nitori oun ko mu owo kankan kuro ni Naijiria, oun si ni awọn gbese kan lati san, fun idi eyii oun nilo owo naa."

Segun ko jẹ gbese kankan, o ṣẹṣẹ fẹ bẹrẹ owo irinkerindo ọkọ ni – Awọn mọlẹbi oloogbe

Amọ ṣa nigba ti awọn akọroyin kan si iya ati iyawo oloogbe naa, wọn ni ko si gbese kankan lọrun rẹ.

Iyawo rẹ, Adebusola Olanrewaju, sọrọ pẹlu omije loju pe oloogbe naa sọ fun oun pe ni kete ti oun ba ti pada de lati Ghana loun yoo lọ gba nọmba si ọkọ akero to ṣẹṣẹ ra ti oun yoo si maa fi ṣiṣẹ.

Obinrin naa ni nnkan bii ọdun marun un sẹyin ni wọn pade, ti wọn si ti wa gẹgẹ bii tọkọtaya fun ọdun meji ṣaaju iṣẹlẹ naa.

Nigba ti iya rẹ n sọrọ, o ni lati ọdun 1993 ti baba rẹ ti jade laye loun ti n danikan tọju rẹ.

Iya rẹ ọhun pari ọrọ rẹ pe ọmọ daadaa ni oloogbe naa ati pe ko jẹ gbese ko to fi aye silẹ.

Abẹ̀sẹ́kùbíòjò ọmọ Nàìjíríà Olanrewaju ṣubú lulẹ̀ lásìkò tó ń jà lọ́wọ́, ó sì jáde láyé

Ọfọ nla ṣẹ lagbo ẹṣẹ kikan lorilẹede Naijiria lẹyin ti ilumọọka abẹsẹkubiojo, Segun ''Success'' Olanrewaju ṣadeede ṣubu lulẹ lasiko to n ja lọwọ ti o si gba ibẹ dagbere faye.

Olanrewaju to wa ni ipo kinni lagbo ẹṣẹ kikan lẹkun iwọ oorun Afirika ati ni Naijiria tẹlẹ ṣubu ni gbagede ija Bukom Boxing Arena lorilẹede Ghana lanaa ọjọ Abamẹta ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹta yii nigba to n ja lọwọ pẹlu alatako rẹ to jẹ ọmọbibi orilẹede Ghana.

Ko si ami tabi apẹẹrẹ kankan to le ṣafihan bo ya Olanrewaju ni ailera kan tabi omiran to n da a laamu ninu ara tori oun lo si n gba alatako rẹ, Jon Mbanugu, ni ẹṣẹ julọ ṣaaju akoko to ṣadeede ṣubu lulẹ.

Fidio ija Olanrewaju ati Mbanugu ti a ri lori itakun ayelujara fi idi rẹ mulẹ wi pe oun gan an lo n lewaju pẹlu ami ayo to pọju ninu ija ọhun ki o to ṣubu lulẹ.

Gẹgẹ bi fidio ija naa ṣe ṣafihan rẹ, kete ti Olanrewaju ṣubu lulẹ lawọn oṣiṣẹ eleto ilera bẹrẹ si ni du ẹmi rẹ.

Oniruuru itọju pajawiri ni wọn fun un nibi to ṣubu si lati le ri wi pe o ji pada, amọ, pabo ni gbogbo igbiyanju wọn jasi.

Ọfọ nla ni iku ojiji Olanrewaju jẹ fawọn eeyan lagbo ẹṣẹ kikan lorilẹede Naijiria ati lẹkun iwọ oorun Afirika.

Olanrewaju ti gba oriṣiiriṣii ami ẹyẹ ninu ẹṣẹ kikan ni Naijiria ati lẹkun iwọ oorun Afirika nigba aye rẹ.

Ọpọ eeyan lagbo ẹṣẹ kikan ni wọn ti n ṣe idaro rẹ lati ọjọ Satide ti o ti jẹ Ọlọrun nipe.

Iku Olanrewaju si n ṣe ọpọ ololufẹ ẹṣẹ kikan ni kayeefi titi di akoko yii.