Àlàyé rèé lórí bí mo ṣe móríbọ́ níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn ní ìlú Uromi

Àwọn méjì nínú àwọn ọdẹ tó kú

Oríṣun àwòrán, HUSAINI TORONKAWA

Àkọlé àwòrán, Àwọn méjì nínú àwọn ọdẹ tó kú
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

"Àwọn ọmọ wa kìí ṣe èèyàn burúkú, kódà wọn ò jalè rí. Ọdẹ tó ń wá ọ̀nà àtijẹ àtimu ni wọ́n."

Èyí ni àwọn ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu Sadiya Sa'adu tó jẹ́ ìyá Haruna Hamidan, ọ̀kan lára àwọn ọdẹ mẹ́rìndínlógún tó pàdánù ẹ̀mí wọn ní ìlú Uromi, ìpínlẹ̀ Edo lọ́jọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹta lásìkò tí wọ́n ń ṣe ìrìnàjò lọ sí ìpínlẹ̀ Kano láti Part Harcourt, ìpínlẹ̀ Rivers.

Sadiya ní Haruna ló ń tọ́jú ẹbí àwọn láti ìgbà tí bàbá rẹ̀ ti jáde láyé.

"Òun ló ń tọ́jú mi àtàwọn àbúrò rẹ̀. Mi ò mọ bí a ṣe fẹ́ gbáyé báyìí tó ti jáde láyé."

Ó ní ó ku ọjọ́ mẹ́rin tó jáde láyé ni àwọn sọ̀rọ̀ gbẹ̀yìn nígbà tó fi owó aṣọ ọdún àwọn ọmọ rẹ̀ ránṣẹ́ sí òun, pé kí òun ra aṣọ kalẹ̀ fún wọn.

"Haruna ti ṣáájú sọ pé òun kò ní wálé fún ọdún pé òun kàn máa fi owó ránṣẹ́ ni àti pé òun máa fi kún owó aṣọ ọdún àwọn ọmọ tí mo sọ pé kò tó."

Àwọn ọdẹ tó pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìkọlù Uromi

Oríṣun àwòrán, HUSAINI TORONKAWA

Àkọlé àwòrán, Gbogbo àwọn tí a kò bo ojú wọn lọ pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìkọlù náà

Láàárín àwọn èèyàn mẹ́rìndínlógún tí wọ́n ṣekúpa níbi ìkọlù náà, mẹ́fà nínú wọn ló jẹ́ ọmọ ìlú Toronkawa ní ìpínlẹ̀ Kano

Sadiya ṣàlàyé pé ẹnu àwọn aráàlú ni òun ti kọ́kọ́ gbọ́ pé wọ́n wà nínú ewu, kí wọ́n tó wá túfọ̀ ikú Haruna fún òun.

Ó fi kun pé àwọn ọmọ àwọn kìí ṣe olè tàbí ọ̀daràn rárá, tó sì ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba pé kí wọ́n ri dájú pé àwọn rí ìdájọ́ òdodo lórí ikú àwọn ọdẹ náà.

Láàárín àwọn èèyàn mẹ́rìndínlógún tí wọ́n ṣekúpa níbi ìkọlù náà, mẹ́fà nínú wọn ló jẹ́ ọmọ ìlú Toronkawa ní ìpínlẹ̀ Kano.

BBC bá ẹbí àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìkọlù náà àti ẹnìkan tó móríbọ́ sọ̀rọ̀.

Inú ọ̀fọ̀ ni àwọn èèyàn ìlú Toronkawa wà láti ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.

Iṣẹ́ ọdẹ jẹ́ ohun tó gbilẹ̀ ní ìlú yìí, tí wọ́n sì máa ń lo iṣẹ́ náà láti fi mọ́ bí ọmọkùnrin ṣe ní akíkanjú sí.

Inú ìbànújẹ́ àti ọ̀fọ̀ ni BBC bá àwọn èèyàn ìlú náà nígbà tí wọ́n ṣe àbẹ̀wò sí wọn.

Àwọn ọmọ ìlú Toronkawa tó pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà

  • Abdulkadir Umar – Ó fi ìyàwó méjì, ọmọ mẹ́ta àti ìyá sáyé.
  • Zaharaddeen Tanko – Ó fi ìyàwó kan àti ọmọ mẹ́rin sáyé.
  • Haruna Hamidan – Ó fi ìyàwó kan àti ọmọ mẹ́rin sáyé.
  • Usaini Musa – Ó fi ìyàwó méjì àti ọmọ méjì sáyé.
  • Abdullahi Harisu – Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìgbéyàwọ ní oṣù mẹ́rin sẹ́yìn.
  • Ya'u Umaru & Abubakar Ado – Àpọ́n tí kò ì tíì ni aya nílé ni àwọn méjéèjì.

" Ọkọ mi sọ pé àwọn ti wà lójú ọ̀nà, pé àwọn ti ń bọ̀ wá sílé, pé kí n ṣe àdúrà fún òun kí Ọlọ́run ṣọ́ àwọn"

Lára àwọn opó tí ọkọ wọn bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ
Àkọlé àwòrán, Lára àwọn opó tí ọkọ wọn bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ

"Ọkọ mi sọ fún mi pé àwọn ti ń bọ̀ wá sílé, pé kí n ṣe àdúrà fún òun kí Ọlọ́run ṣọ́ àwọn, ìgbà tí mo gbọ́ kẹ́yìn láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ nìyẹn"

Hadiza Muhammad, tó jẹ́ ọ̀kan lára ìyàwọ méjì tí Abdulkadir Umar fi sáyé sọ pé òun bá ọkọ òun sọ̀rọ̀ lórí fóònù lọ́jọ́ tí wọ́n ṣekúpa á.

"Ó sọ fún mi pé àwọn ti wà lójú ọ̀nà, pé àwọn ti ń bọ̀ wá sílé, pé kí n ṣe àdúrà fún òun kí Ọlọ́run ṣọ́ àwọn.

Ìgbà tí mo gbọ́ kẹ́yìn láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ nìyẹn."

Hadiza ní nǹkan bíi aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́ ni wọ́n wá sọ fáwọn pé àwọn ọkọ òun ní ìjàmbá àmọ́ wọn ò sọ pé àwọn kan ló ṣe ìkọlù sí wọn.

"Nígbà tó yá ni wọ́n padà sọ fún wa pé àwọn ló pa wọ́n.

Mi ò tíì gbádùn ara mi láti ìgbà náà. A ò ní dárí ji àwọn tó ṣokùnfà ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ọlọ́run máa fìyà jẹ gbogbo àwọn tó pa ọkọ wa.

"Èèyàn dáadáa ni ọkọ mi, tó máa ń ṣe gbogbo nǹkan láti mú inú wa dùn."

Hadiza Muhammad, ìyàwó Abdulkadir Umar

Báyìí ni mo ṣe móríbọ́

Abubakar Shehu

"Bí a ṣe ń bọ́lẹ̀ nínú ọkọ̀ ni wọ́n ń lù wá láì bèèrè ohunkóhun lọ́wọ́ wa, mo sa mọ wọ lọwọ lọ sinu ilé àkọ́kù kan, mo ń gbọ́ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ọ̀rẹ́ mi"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Abubakar Shehu, ọ̀kan lára àwọn ọdẹ ọ̀hún tí orí kó yọ, ṣàlàyé pé ìgbà àkọ́kọ́ tí òun yóò ṣọdẹ lọ sí ìlú Port Harcourt rèé.

Ó ní báwọn ṣe dé ìlú Uromi ni àwọn fijilanté dá àwọn dúró, tí wọ́n sì ní káwọn bọ́lẹ̀ nínú ọkọ̀ tí àwọn wà.

"Bí a ṣe ń bọ́lẹ̀ nínú ọkọ̀ ni wọ́n ń lù wá láì bèèrè ohunkóhun lọ́wọ́ wa.

"Nígbà tí mo ri pé ọ̀rọ̀ náà ti ń lágbára ni mo sá àsálà fún ẹ̀mí ara mi.

"Bí wọ́n ṣe ń nà wá ni àwọn kan ń sọ níbẹ̀ pé kí a máa sá lọ ló jẹ́ kí n sa."

Ó ṣàlàyé pé àwọn méjì kan gbìyànjú láti dá òun dúró nígbà tí òun sá lọ àmọ́ wọn kò ri òun mú.

"Inú ilé àkọ́kù kan ni mo sá sí tí mo ti ń gbọ́ gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ọ̀rẹ́ mi."

Abubakar Shehu sọ pé aago mẹ́wàá alẹ́ ni òun tó jáde níbi tí òun sá sí, tí òun sì rí ọkọ̀ ńlá kan gbé òun dé ìlú Kano, tóun sì wà ọ̀nà láti dé ilé láti ibẹ̀.

Ó ṣàlàyé pé ọ̀rẹ́ òun, Abdulkadir Umar ti ṣubú lulẹ̀, tó sì dákún kí òun tó sá kúrò níbẹ̀.

"Àwọn fijilanté náà kò ti ẹ̀ bèèrè irú èèyàn tí a jẹ́, wọ́n kọ̀ ṣe ìkọlù sí wa.

A ní káàdì ìdánimọ̀ tó fi hàn pé ọdẹ ni wá lọ́wọ́ àmọ́ wọn ò bèèrè rẹ̀ lọ́wọ́ wa.

"Owó tí wọ́n bá nínú ọkọ̀ jẹ́ owó àwọn ọdẹ tí kò ì tíì fi owó wọn ránṣẹ́ sílé.

"Gbogbo àwọn ìbọn àti ajá tí a kó dání ni wọ́n ní ìwé àṣẹ. Ọdẹ lásán ni wá, a kìí ṣe agbébọn.

Ó ní òun kò gbàgbọ́ pé òun le móríbọ́ nínú ìkọlù náà.

Ìjọba gbọdọ̀ gbẹ̀san ikú àwọn èèyàn wa – Alága ọdẹ Toronkawa sọ̀rọ̀

Mustapha Usman, alága ẹgbẹ́ àwọn ọlọ́dẹ ìlú Toronkawa

Ẹgbẹ́ àwọn ọlọ́dẹ ìlú Toronkawa táwọn ọdẹ náà jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ ti dá sí ọ̀rọ̀ náà.

Alága ẹgbẹ́ náà, Mustapha Usman sọ pé ìjọba gbọdọ̀ fojú àwọn tó ṣiṣẹ́ ibi náà winá òfin.

Ó ṣèkìlọ̀ pé nǹkan le bàjẹ́ tí ìjọba kò bá gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ lásìkò.

Inú fu àyà fu la fi ń gbé láti ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn náà ti wáyé - Àwọn ará ìlú Uromi kọminú

Ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ìlú Uromi ní inú fu, àyà fu ni àwọn fi ń gbé ayé báyìí nítorí àwọn kò mọ ohun tó le ṣẹlẹ̀ sí àwọn.

Àwọn ará ìlú náà ń fẹ̀sùn kan àwọn ọlọ́pàá pé wọ́n kàn ń nawọ́ gán ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá rí, tí wọ́n sì ń gba owó lọ́wọ́ wọn.

Ìròyìn ní bí ọjà ìlú Uromi ṣe dá lọ́jọ́rú tó jẹ́ ọjọ́ tí wọ́n máa ń ná ọjà náà ṣàfihàn nǹkan tó ń lọ níbẹ̀.

Ọjà náà tó jẹ́ pé ẹsẹ̀ kìí gba èrò àti ọkọ̀ níbẹ̀ ló dá páro, tí èèyàn sì lè ka iye ọkọ̀ tó ń kọjà.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ló ń fi ẹ̀dùn ọkàn wọn hàn lórí bí wọ́n ṣe ní àwọn ọlọ́pàá ń lo ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní ìpínlẹ̀ náà láti máa fi mú àwọn ọ̀dọ́ láì ṣẹ̀.

Wọ́n fẹ̀sùn kan pé àwọn ọlọ́pàá máa ń sọ fáwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n bá ti mú pé àwọn máa gbé wọn lọ sí ìlú Abuja pé wọ́n lọ́wọ́ nínú ìpànìyàn náà tàbí kí wọ́n fún àwọn lówó.

Ṣùgbọ́n, agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Edo, Moses Yamu ti ní ẹnikẹ́ni táwọn ọlọ́pàá báti mú, tí wọ́n sì gba owó lọ́wọ́ rẹ̀ lọ́nà àìtọ́ mú ẹ̀rí lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá láti lọ fẹjọ́ sùn, táwọn yóò sì wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ náà.

Yamu ṣàlàyé pé ẹnìkan tí wọ́n ní àwọn ọlọ́pàá gba mílíọ̀nù kan náírà lọ́wọ́ rẹ̀, tó wà lórí ayélujára ni òun ti kàn sí pé kó fi ẹ̀rí owó tó fi ránṣẹ́ sáwọn ọlọ́pàá náà sí òun àmọ́ tí kò fi ránṣẹ́ títí di àsìkò tí ìròyìn ń jáde

Ó ní òun kò sọ pé àwọn èèyàn parọ́ mọ́ àwọn ọlọ́pàá àmọ́ àwọn nílò ẹ̀rí láti fìdí àwọn ẹ̀sùn wón múlẹ̀.

Àkọlé fídíò, "Ilé tó lé ní igba ni wọ́n jó ní Erin-ile, ìgbà kejì tí wọn yóò jó ilé mi rèé, n kò ní aṣọ kankan lọ́rùn mọ́"

Ìjọba Kano lahùn lórí ohun tó fẹ́ kí ìjọba Edo ṣe nípa ọdẹ 16 táwọn èèyàn Uromi dáná sun lásìkò tí wọn ń bọ̀ fọ́dún Ìtúnu Ààwẹ̀

Gómìnà Kano, Abba Yusuf àti gómìnà ìpínlẹ̀ Edo, Monday Okpebholo

Oríṣun àwòrán, KSGH

Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano, Abba Kabir Yusuf ti rọ gómìnà ìpínlẹ̀ Edo, Monday Okpebholo láti pèsè ẹ̀bùn gbà má bínú fáwọn ọdẹ tí wọ́n ṣekúpa ní ìpínlẹ̀ náà, lásìkò tí wọ́n ń lọ sílé ọdún.

Gomìnà Yusuf sọ èyí lásìkò tí Gómìnà Okpebholo kó àwọn aláṣẹ ìpínlẹ̀ Edo sòdí lọ sí ìpínlẹ̀ Kano láti báwọn kẹ́dùn lórí ikú àwọn èèyàn náà.

Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni àwọn ọdẹ kan tí wọ́n ń rin ìrìnàjò lọ sí ìpínlẹ̀ Kano láti ìpínlẹ̀ Rivers lọ ṣọdún ìtúnu ààwẹ̀, ko àgbákò ikú lọ́wọ́ àwọn aráàlú Uromi, ìpínlẹ̀ Edo, lẹ́yìn táwọn fijilanté ìlú Uromi dáná sun wọ́n fẹ́sùn pé ajínigbé ni wọ́n.

Gómìnà Abba kan sáárá sí gómìnà Edo fún àwọn ìgbésẹ̀ tó ti gbé láti ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé, tó sì ní àwọn ń sa gbogbo ipa àwọn láti ri dájú pé àwọn èèyàn Kano kò gbìyànjú láti gbẹ̀san ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

"A fẹ́ kí wọ́n fi ojú àwọn afurasí tó ṣiṣẹ́ ibi náà hàn fún aráyé, kí ìjọba Edo sì san owó gbà má bínú fáwọn ẹbí àwọn èèyàn tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà"

"Púpọ̀ lára àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ló jẹ́ ọmó ìpínlẹ̀ Kano.

Wọ́n dá wọn dúró ní ìpínlẹ̀ Edo nígbà tí wọ́n ń bọ̀ láti Port Harcourt, wọ́n lù wọ́n, wọ́n sì dáná sun wọ́n láàyè."

Bákan náà ló tún gbóríyìn fún ìjọba Edo fún bí wọ́n ṣe ri dájú pé wọ́n ṣàwárí òkú àwọn èèyàn náà, tí wọ́n sì sin wọ́n ní ìlànà mùsùlùmí.

Àti pé àwọn afurasí tí wọ́n lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wà ní àhámọ́ páńpẹ́ ọba."

Gómìnà Yusuf wá bèèrè fún nǹkan méjì lọ́wọ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Edo, tó ní ó wu òun pé kí ó ṣe àmúṣẹ rẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

"A fẹ́ kí wọ́n fi ojú àwọn afurasí tó ṣiṣẹ́ láabi náà hàn sí gbogbo ayé, kí gbogbo èèyàn rí ojú wọn."

Ó ní òun gbàgbọ́ pé èyí máa tu àwọn ẹbí èèyàn tó pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà nínú, tó sì òun gbàgbọ́ pé gómìnà náà máa mú ìbéèrè náà wá sí ìmúṣẹ.

Ó ní nǹkan kejì tí òun ń fẹ́ ni pé kí wọ́n san owó gbà má bínú fáwọn ẹbí àwọn èèyàn tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, kó sì wáyé lásìkò.

Ọkọ tirela ti wọn dana sun eeyan ninu rẹ

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Okpebholo sọ fún àwọn èèyàn ọ̀hún pé òun kò ní sinmi àyàfi tí ìdájọ́ òdodo bá wáyé lórí ikú àwọn èèyàn wọn

Ṣáájú ni Gómìnà Monday Okpebholo ti kọminú lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, tó sì sọ pé àwọn afurasí mẹ́rìnlá tí wọ́n lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni wọ́n ti fi páńpẹ́ ọba mú.

Ó ní òun máa ṣe àrídájú rẹ̀ pé ìdájọ́ òdodo wáyé lórí ẹjọ́ náà.

Lẹ́yìn ìpàdé náà ni Gómìnà Abba Yusuf mú Gómìnà Okpebholo lọ sí ìjọba ìbílẹ̀ Bunkure láti lọ bá àwọn ẹbí àwọn èèyàn tó pàdánù ẹ̀mí wọn kẹ́dùn.

Okpebholo sọ fún àwọn èèyàn ọ̀hún pé òun kò ní sinmi àyàfi tí ìdájọ́ òdodo bá wáyé lórí ikú àwọn èèyàn wọn.