BBC tú àṣírí gbájúẹ̀ tó ń gba owó lọ́wọ́ ọmọ Nàíjíría fún ìpèsè iṣẹ́ ní UK
- Author, Tamasin Ford
- Role, BBC Global Disinformation Unit and Africa Eye
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8
BBC ṣèwádìí àwọn iléeṣẹ́ tó máa ń lu àwọn èèyàn ní jìbìtì láti báwọn wá iṣẹ́ sí ẹ̀ka ìlera ní UK.
Lára àwọn èèyàn yìí ni dókítà ọmọ Nàìjíríà kan tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àjọ ìlera ilẹ̀ UK, NHS ní ẹ̀ka àwọn tó máa ń rí sí ààrùn ọpọlọ.
Iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè ní UK sọ pé ó ṣeéṣe káwọn èèyàn máa lo ìlànà náà láti fi u àwọn èèyàn ní jìbìtì, tí ìwádìí BBC sì ṣe àfihàn báwọn oníjìbìtì yìí ṣe le gbá àwọn èèyàn láì ní fura sí wọn, tí wọ́n sì ń mú u jẹ.
Lára nǹkan tí ìwádìí ṣàfihàn ni:
Títa iṣẹ́ ní àwọn iléeṣẹ́ ètò ìlera UK
Ṣíṣe ayédèrú ìwé tí wọ́n fi ń san owó oṣù láti fi pamọ́ pé irọ́ ni àwọn iṣẹ́ kan
Pípàrọ̀ iṣẹ́ láti ẹ̀ka ìlera sáwọn ẹ̀ka mìíràn bíi ilé kíkọ́, tó jẹ́ pé àwọn náà kò ní òṣìṣẹ́ tó nǹkan
Láti ìgbà tí ìjọba UK ti ṣe àtúnṣe sí bí físà táwọn òṣìṣẹ́ ìlera láti ilẹ̀ òkèèrè le fi gba iṣẹ́ sí orílẹ̀ èdè láti ṣàfikún àwọn tó ń tọ́jú arugbó ni bí àwọn tó ń lu àwọn èèyàn ní jìbìtì láti gba iṣẹ́ ní orílẹ̀ òkèèrè ti lé kún.
Kí èèyàn tó le gba físà láti ṣiṣẹ́ ní UK, o nílò láti gba ìwé kan tí wọ́n ń pè ní "Certification of Sponsorship" (CoS) látọwọ́ ẹni tó ń ṣiṣẹ́ ní UK tí Home Office fún láṣẹ láti ṣiṣẹ́. Ìnílò CoS yìí ni àwọn oníjìbìtì yìí máa ń lò láti fi lu àwọn èèyàn ní jìbìtì.
Dora-Olivia Vicol, tó jẹ́ adarí iléeṣẹ́ Work Rights Centre, àjọ ẹlẹ́yinjú àánú tó máa ń ṣe ìrànwọ́ fáwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé UK àtàwọn tó kù díẹ̀ káàtó fún sọ pé bí wọ́n ṣe máa ń lu jìbìtì ní ẹ̀ka ètò ìlera jẹ́ ohun tó fojú hàn gidi gan.

"Ó ti di dàbí ohun tó jẹ́ wàhálà ní orílẹ̀ èdè yìí."
Ó ní àwọn ewu tó wà nínú gbígba ìwé àtìlẹyìn lọ́wọ́ ẹni tó ń ṣiṣẹ́ ní UK pọ̀ díẹ̀ nítorí ó fún ẹni tó ń pèsè iṣẹ́ ní agbára tó pọ̀ tó sì ń fún àwọn oníjìbìtì ní à]nfàní láti le máa ṣe iṣẹ́ ibi wọn.
BBC ran àwọn òṣìṣẹ́ méjì láti ṣe ìwádìí àwọn òṣìṣẹ́ tó ń bá èèyàn wá iṣẹ́ sí UK.
Ọ̀kan lára ẹni tí wọ́n rí ni Dókìtà Kelvin Alaneme, tó jẹ́ dókìtà ọmọ Nàìjíríà àti olùdásílẹ̀ àjọ CareerEdu, tó wà ní Harlow, Essex.
Ó kọ sórí ìkànnì ayélujára rẹ̀ pé iṣẹ́ òun ń pèsè ọ̀nà fáwọn ọ̀dọ́ ilẹ̀ Africa láti ṣiṣẹ́ káàkiri ilẹ̀ òkèèrè àti pé òun ní àwọn oníbàárà 9,800 tí inú wọn dùn sí iṣẹ́ òun.
Ìgbàgbọ́ rẹ̀ pé òṣìṣẹ́ BBC yìí mọ ọ̀pọ̀ èèyàn ní ẹ̀ka ètò ìlera UK, Dókìtà Alaneme gbìyànjú láti gbà á síṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀, bó ṣe sọ fún pé ó máa rí èrè tó pọ̀ jẹ níbẹ̀.
"Bá mi àwọn ilé ìgbé tí wọ́n ti ń tọjú arúgbó. Mo lè sọ ẹ́ di olówó rẹpẹtẹ," ó sọ.
Òṣìṣẹ́ wa bẹ̀rẹ̀ sí ní mọ àṣìrí nípa báwọn iléeṣẹ́ yìí ṣe máa ń lu àwọn èèyàn ní jìbìtì, bí i irú èyí tí Dókítà Alaneme ń ṣe. Dókítà Alaneme sọ pé òun yóò máa san £2,000 ($2,600) fún iṣẹ́ ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó tó bá ń mú wa fún òun pẹ̀lú àlékún £500 ($650) lórí rẹ̀.
Iṣẹ́ yìí ló máa ń tà fáwọn èèyàn ní Nàìjíríà, tí yóò máa gba owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn lórí iṣẹ́ tí kò sí ní UK.
"Kò yọ kí àwọn èèyàn máa sanwó fún àwọn iṣẹ́ yìí. Ọ̀fẹ́ ló yẹ kó jẹ́," ó sọ pẹ̀lú ohùn ìrẹ̀lẹ̀.
"Wọ́n ń sanwó nítorí ọ̀nà kan ṣoṣo tí wọ́n rò pé ó jẹ́ ọ̀nà fáwọn nìyẹn."
BBC bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe ìwádìí Dókítà Alaneme lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ń fẹ̀sùn kan iléeṣẹ́ rẹ̀ lórí ayélujára.
Praise láti ẹkùn ìlà oòrùn gúúsù Nàìjíríà sọ pé òun san owó tó lé £10,000 ($13,000) fún dókítà Alaneme láti bá òun wá iṣẹ́ sí UK. Ó ní Dókítà Alaneme sọ fún òun pé òun máa ma ṣiṣẹ́ nílé ìtọ́jú kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Efficiency for Care tó wà ní Clacton-on-Sea àmọ́ ìgbà tó dé UK ló rip é kò sí iṣẹ́ kankan tó jọ bẹ́ẹ̀ fún òun.
"Tó bá jẹ́ pé mo mọ̀ pé kò sí iṣẹ́ ni, mi ò ní wá sí ibi yìí rárá," ó sọ. Tó bá jẹ́ pé Nàìjíríà ni mo wà ni, tí mi ò bá ní owó lọ́wọ́, mo lè lọ jẹun lọ́dọ̀ àwọn òbí tàbí ẹ̀gbọ́n mi àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ níbí."
Praise sọ pé òun kọ̀wé ránṣẹ́ sí iléeṣẹ́ Efficiency for Care àti Dókítà Alaneme fún ọ̀pọ̀ oṣù láti bèèrè ìgbà tí òun yóò bẹ̀ẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àmọ́ òun kò sí èsì kankan. Ó ní lẹ́yìn ọdún kan ni òun tó rí iléeṣẹ́ ìtọ́jú kan tó gbà láti ṣe àtìlẹyìn fún òun láti dúró ní UK.

Ìwádìí wa ṣàfihàn pé Efficiency for Care gba èèyàn mẹ́rìndínlógún ní 2022 àti 152 ní 2023. Ìwé àkọránṣẹ́ kan tí Home Office fi ránṣẹ́ sí iléeṣẹ́ náà tí BBC rí fi hàn pé èèyàn 1,234 ni iléeṣẹ́ náà fi CoS ṣọwọ́ sí nílẹ̀ òkèèrè láàárín oṣù Kẹta 2022 àti May 2023.
Ní oṣù Keje, ọdún 2023 ni wọ́n gba ìwé àṣẹ láti gba èèyàn láti ilẹ̀ òkèèrè kúrò lọ́wọ́ iléeṣẹ́ náà àmọ́ tí wọ́n sì ṣì lè máa ṣiṣẹ́.
Iléeṣẹ́ náà jiyàn pé àwọn kò máa ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú Dókítà Alaneme, pé àwọn máa ń tẹ̀lé ìlànà àti òfin tó yẹ láti gba èèyàn síṣẹ́ láti ilẹ̀ òkèèrè. Wọ́n ní àwọn ti pe bí wọ́n ṣe gba ìwé àṣẹ àwọn lẹ́jọ́ àti pé ọ̀rọ̀ náà ti wà nílé ẹjọ́.
Nígbà tí òṣìṣẹ́ wa tún ṣèpàdé mìíràn pẹ̀lú Dókítà Alaneme, ó tún sọ àṣìrí mìíràn nípa bí wọ́n ṣe máa ń lu àwọn èèyàn ní jìbìtì lórí gbígba ìwé iṣẹ́ tí kò sí.
Ó ní àǹfàní tó wà pẹ̀lú àwọn gbígba CoS fún iṣẹ́ tí kò sí ni pé èèyàn le mú ìlú tó bá wù ú láti gbé.
"Ó lè lọ sí Glasgow, ó lè máa gbé ní London, ó lè gbé ní ibikíbi."
Irọ́ ńlá ni èyí. Bí èèyàn bá fi físà iṣẹ́ ètò ìlera Health and Care wọ UK, tí kò sì ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n bá yàn án sí, ó ṣeéṣe kí wọ́n gba físà náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí wọ́n sì le padà sí orílẹ̀ èdè tó ti ń bọ̀.
Bákan náà ló sọ fún BBC bó ṣe máa ń ṣe ìwé owó lọ́nà àìtọ́ láti fi tan ìjọba pé àwọn iṣẹ́ náà kò sí.
Dókítà Alaneme sọ fún BBC pé àwọn iṣẹ́ tí CareerEdu ń pèsè kìí ṣe jìbìtì tàbí purọ́ láti ṣe bíi iléeṣẹ́ tó ń pèsè iṣẹ́ láti fi gba owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn.
Ó ní owó tí Praise fún òun ni òun fi ránsẹ́ sáwọn iléeṣẹ́ tó ń gba èèyàn síṣẹ́ láti fi ṣe owó ìrìnnà, ilé ìgbé àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún un. Ó ní òun gbìyànjú láti ran Praise lọ́wọ́ láti wá iṣẹ́ mìíràn lọ́fẹ̀ẹ́.
BBC tún ṣe ìwádìí iléeṣẹ́ tó ń bá èèyàn wá iṣẹ́ sí UK mìíràn, Nana Akwasi Agyemang-Prempeh lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn fẹ̀sùn kàn-án pé àwọn tis an ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó fún un láti báwọn wá iṣẹ́ sẹ́ka ìtọ́jú àmọ́ tó jẹ́ pé irọ́ ló gbé lé àwọn lọ́wọ́.
Wọ́n ní àwọn CoS tí Agyemang-Prempeh fún àwọn ló jẹ́ ayédèrú sí èyí tí àwọn iléeṣẹ́ náà ń pèsè gangan.

A ṣàwárí rẹ̀ pé Agyemang-Prempeh ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fún àwọn èèyàn ní CoS fún iṣẹ́ ilé kíkọ́ - ẹ̀ka mìíràn tó fààyè gba gbígba àwọn òṣìṣẹ́ láti ilẹ̀ òkèèrè. Ó ti dá iléeṣẹ́ ilé kíkọ́ tirẹ̀ sílẹ̀, tó sì ti gba ìwé àṣẹ láti máa gba èèyàn láti òkèèrè ní Home Office.
Akọ̀ròyìn wat ó ṣe bí oníṣòwò ọmọ ilẹ̀ Uganda tó ń gbé ní UK sọ fún Agyemang-Prempeh pé òun fẹ́ kó àwọn èèyàn wá láti Uganda láti ṣiẹ́ ilé kíkọ́ ní ọ̀dọ̀ rẹ̀.
Ó ní òun máa gba £42,000 ($54,000) fún èèyàn mẹ́ta.
Agyemang-Prempeh sọ fún wa pé òun bọ́ sí ẹ̀ka ilé kíkọ́ nítorí òfin gbígba èèyàn sẹ́ka ìtọ́jú ti ń lágbára púpọ̀.
Kò dín ní ìwé àṣẹ 470 tí ìjọba UK gba padà láàárín oṣù Keje 2022 sí oṣù Kejìlá 2024 lẹ́ka ètò ìlera àti ìtọ́jú. Àwọn iléeṣẹ́ náà gba òṣìṣẹ́ ètò ìlera àti ìtọ́jú tó lé ní 39,000 láti oṣù Kẹwàá ọdún 2020.
Agyemang-Prempeh ní kí òṣìṣẹ́ BBC san owó sílẹ̀ fún àwọn CoS náà àmọ́ a kò san owó kankan.
Home Office ti gba ìwé àṣẹ Agyemang-Prempeh padà tó sì sọ fún BBC pé àwọn iléeṣẹ́ tó ń gba èèyàn síṣẹ́ ló ń gba òun àti pé òun kò mọ̀ pé ayédèrú CoS ni òun ń tà.

Nínú àtẹ̀jáde kan sí BBC, Home Office sọ pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti gbógunti àwọn iléeṣẹ́ tí wọ́n ń lo físà láti fi lu àwọn èèyàn ní jìbìtì.
Wọ́n ní gbogbo àwọn iléeṣẹ́ tí àwọn bá ti ṣàwárí pé ó lọ́wọ́ nínú ìwà bẹ́ẹ̀ ni àwọn kò ní fààyè gbà láti kó èèyàn wọ UK mọ́ láti ilẹ̀ òkèèrè.
Ìwádìí BBC ti ṣáájú ṣàwárí irúfẹ́ ìwà lílu àwọn èèyàn ní jìbìtì báyìí ni Kerala, India àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilẹ̀ òkèèrè tó wà ní UK tí wọ́n fẹ́ ṣiṣẹ́ lẹ́ka ètò ìlera.
Nínú oṣù Kọkànlá 2024, ìjọba UK kéde kíkọ ojú oro sáwọn iléeṣẹ́ tó ń gba èèyàn láti ilẹ̀ òkèèrè. Bákan náà, láti ọjọ́ Kẹsàn-án, oṣù Kẹrin, àwọn iléeṣẹ́ tó ń pèsè ìtọ́jú gbọdọ̀ máa gba àwọn èèyàn ilẹ̀ òkèèrè tó wà ní UK, kí wọ́n tó máa gba àwọn tí kò sí orílẹ̀ èdè náà.
Àwọn olùwádìí: Olaronke Alo, Chiagozie Nwonwu, Sucheera Maguire, Nyasha Michelle, and Chiara Francavilla













