Africa Eye- Wọ́n dábẹ́ fún Fatmata tán ló kú lọ́jọ́ kejì- Olólùfẹ́ Fatmata

Àkọlé fídíò, FGM

Ikọ asewadii iroyin ile ise BBC, ti a mọ si BBC Africa Eye se iwadii ipa ti abẹ dida n ko fun omobinrin lasiko yii lorile ede Sierra Leone nile Adulawo.

Asa dida abẹ fun omobinrin ni ajọ United Nations ti koro oju si lati ọpọ ọdun seyin.

Ololufẹ Fatmata Turay to doloogbe lẹyin to dabẹ salaye ohunt o ṣele ki wọn to dabe fun Fatmata ati leyin ti won dabẹ fun un lẹni ọdun mọkandinlogun.

Egbe Bondo ni won sọ pe o maa n dabẹ fun awọn ọdọbinrin ni Sierra Leone ṣaaju igbeyawo wọn ni Sowei.