Àwọn dókítà tún fún ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà ní gbèdéke tuntun, tàbí kí wọ́n gùn lé ìyanṣẹ́lódì

Aworan dokita kan ati aworan idanimọ ẹgbẹ NARD

Oríṣun àwòrán, other

O dabi ẹni pe o tun ti n rugbo bọ bayii laarin awọn dokita ile iwosan ijọba ti a mọ si ‘Resident Doctors’ ati ijọba apapọ bayii.

Igbimọ adari ẹgbẹ awọn dokita ile iwosan agba to jẹ tijọba lorilẹede Naijiria, NARD ti fun ijọba apapọ Naijiria ni gbedeke ọsẹ meji bayii lati fi wa nnkan ṣe lori adehun to wa laarin awọn ati ijọba.

Ninu atẹjade kan ti wọn sita lẹyin ipade lọjọ mẹta igbimọ oludari to ga julọ lẹgbẹ naa eyi to waye ni ileewosan nla Federal Medical Center to wa nilu Abẹokuta ni ipinlẹ Ogun ni wọn ti yọju gbendeke naa sita.

Gẹgẹbi atẹjade naa ṣe sọ, gbedeke ọhun bẹrẹ lati ọjọ Satide, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹrin dun 2023, yoo si pari ni ọjọ kẹtala oṣu karun un dun 2023 kan naa.

Awọn dokita naa ni bi gbedeke naa ba pari laijẹ pe igbesẹ to yanranti waye latọdọ ijọba, ko daju pe awọn yoo le ‘fọwọ sọya pe alaafia yoo waye lori ọrọ iṣẹ lẹka naa jakekado orilẹede Naijiria’

Kini awọn ẹbẹ ati adehun ti awọn dokita ọmọ ẹgbẹ NARD n tọka si?

Lara awọn ibeere awọn dokita ileewosan agba naa ni afikun ilana owo oṣu awọn oniṣegun oyinbo ti a mọ si CONMESS pẹlu ida igba iye ti wọn n gba bayii.

Bakan naa lawọn dokita naa tun n beere fun yiya ida marundinlogun (15%) gbogbo eto iṣuna apapọ Naijiria sọtọ fun ẹka eto ilera dipo ida mẹfa din diẹ ninu ọgọrun (5.7%) to wa bayii.

Wọn tun n fẹ ki ijọba mojuto bi ohun amayedẹrun lẹka naa ṣe n fojojumọ jo ajorẹyin, pẹlu gbigba awọn oṣiṣẹ ilera si iṣẹ lati dipo ọgọọrọ awọn to ti gbe ẹrun wọn roke okun.

Bakan naa ni wọn tun n fẹ ki ijọba jami lori abadofin kan to wa ni ile aṣojuṣofin bayii eyi to fofin de awọn dokita pe wọn ko gbọdọ fi orilẹede Naijiria silẹ lọ ṣiṣẹ loke okun laijẹ pe wọn ti ṣiṣẹ fun iye gbedeke ọdun kan lorilẹede Naijiria.

NARD tun ke sijọba ko san awọn ajẹẹlẹ owo oṣu ti wọn jẹ wọn lọdun 2014, 2015, ati 2016.