Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní Nàìjíríà bèrè àfikún ọdún ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba fún àyájọ́ Workers'day

Awọn oṣiṣẹ

Oríṣun àwòrán, other

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria ti pe fun atunyẹwo ọjọ ori ifẹyinti fun awọn oṣiṣẹ lati ọgọta ọdun (60) si ọdun marundinlaadọrin (65), ati lati ọdun marindinlogoji lẹnu iṣẹ si ogun ọdun lẹnu iṣẹ.

Lasiko ayajọ awọn oṣiṣẹ to waye lọjọ Aje ni awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria gbe ẹbẹ yi jade fun awọn olori lorilẹede Naijiria.

Ayajọ ọdun yii ni yoo jẹ eyi to kẹyin labẹ iṣejọba aarẹ Muhammadu Buhari.

Ọkanojọkan awọn adari nigbakanri lẹgbẹ oṣiṣẹ mejeeji to wa ni Naijiria – NLC ati TUC- lo wa nibi ayẹyẹ ayjọ naa to waye ni gbagede Eagles Square to wa nilu Abuja.

Bakan naa ni ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ tun beere fun agbekalẹ igbimọ kan ti yoo ṣe iwadi alaga ajọ INEC, Mahmood Yakubu ati ikọ rẹ lori bi wọn ṣe ṣeto idibo apapọ ọdun 2023.

Bakan naa ni wọn tun beere fun iwadi lori bi ileeṣẹ irinna ofurufu ṣe na biliọnu mejila Naira fun rira kọ panapana mẹwaa.

Aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ni Naijiria, Kọmuredi Joe Ajaero ni aikunwọ owo oṣu, titẹ ẹtọ oṣiṣẹ mọlẹ lẹnu iṣẹ ati aisan owo oṣu deede ti gba ẹtọ oṣiṣẹ lọwọ wọn.

Akẹgbẹ rẹ lẹgbẹ oṣiṣẹ TUC, Kọmuredi Festus Osifo ni tirẹ kọminu lori ipo ti ọrọ aje Naijiria wa eleyi to ni o dabi eyi ti ko tilẹ lojutu bayii to si jẹ pe agbarakaka lo fi n mi nitori aijafafa awọn to wa nibi ijanu rẹ.

Lara awọn to wa nibẹ ni akọwe ijọba apapọ Naijiria, Boss Mustapha, minisita fọrọ oṣiṣẹ Chris Ngige, minisita fun olu ilu Naijiria, Mohammed Bello pẹlu minisita fun ọrọ awọn obinrin, Paul Tallen ati oludije ipo aarẹ fun ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi.