Ọwọ́ ọlọ́pàá tún ti tẹ pásítọ̀ míì ní Kenya lórí ikú àwọn ọmọ ìjọ

Ezekiel Ombok Odero

Oríṣun àwòrán, @Goddie_Ke

Ileeṣẹ ọlọpaa orilẹ-ede Kenya ti fi ṣikun ofin mu pasitọ kan, wọn si ti gbe agadagodo sẹnu ọna ile ijọsin rẹ.

Igbesẹ yii lo waye bi iwadii ṣe n lọ lori pasitọ kan to ni ki awọn ọmọ ijọ oun gbawẹ lati pade Jesu, eyii ti ẹmi eeyan bii ọgọrun lọ si.

Pasitọ Ezekiel Odero dero atimọle lẹyin ti iwadii gbe awọn agbofinro lọ sile igbokupamọsi kan lagbegbe ibi ti ijọ rẹ, New Life International Church wa ni Mavueni.

Ọlọpaa ni awọn fidi rẹ mulẹ pe awọn oṣiṣẹ ile igbokupamọsi naa maa n ko oku wọ ibẹ lati inu ile ijọsin ọhun.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ fun awọn akọroyin pe “Laarọ oni, a ti fi ṣikun ofin mu pasitọ Ezekiel Odero latari awọn eeyan to n ku ni sakani rẹ.”

Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, pasitọ naa ko tii fi atẹjade kankan lede nipa ẹsun ọhun.

Ọlọpaa tun ni awọn n sẹwadii ibaṣepọ to wa laarin Odero ati pasitọ Paul Mackenzie Nthenge, to ni ki awọn ọmọ ijọ oun gba awẹ titi ti wọn yoo fi jade laye lọna ati pade Jesu Kristi.

O kere tan, oku eeyan marundinlọgọrun ni ijọba Kenya ti ṣawari latari aṣẹ ti Nthenge pa fun awọn ọmọ ijọ rẹ lati gbawẹ ki wọn le ri Jesu.

Iroyin ni ọpọ ninu awọn to ku naa lo jẹ ọmọde, ti wọn si sin oku wọn sinu igbo kan ti ko jina si ṣọọṣi rẹ ọhun.

Bo tilẹ jẹ pe Nthenge ti wa latimọle ijọba bayii, o ti sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.