'Mi ò lọ sí ilé ẹ̀kọ́ kankan ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún mi ni mo fi ń ṣe ọkọ̀ òfurufú'

Arákùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Aliyu Damilola tó ń gbé ní ìlú Ilorin ṣàlàyé bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe ọkọ̀ òfurufú láti ìgbà tó ti wà ní ọmọdé.
Ó ní láti ìgbà tí òun ti wà ní bíi ọmọ ọdún méje ni òun ti máa ń gbìyànjú láti ṣe ọkọ̀ òfurufú nítorí ìfẹ́ tí òun ní sí ṣíṣe ọkọ̀ òfurufú.
Ó ṣàlàyé pé látara bí òun ṣe máa ń lọ wo bí ọkọ̀ òfurufú ṣe máa ń fò tó sì máa ń bà ní ilé ẹ̀kọ́ nípa ọks òfurufú ní ìlú Zaria, ìpínlẹ̀ Kaduna ni òun ti bẹ̀rẹ̀ sí ni mọ bí wọ́n ṣe ń to ọkọ̀ náà pọ̀.
Aliyu Damilola ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò ní ìmọ̀ nípa bí bàálù ṣe ń fò, tó sì máa ń bà òun máa ń lọ ṣa agolo jọ láti fi ṣe bí òun ṣe rí.
Ó tẹ̀síwájú pé nígbà tí àwọn òbí òun kó padà sí ìlú Ilorin, ìpínlẹ̀ Kwara ni òun tó ní ìmọ̀ nípa bí àwọn ọkọ̀ òfurufú tí òun ń ṣe ṣe lè fò.
Ó fi kun pé owó oúnjẹ òun ni òun dá jọ láti fi ra àwọn nǹkan tí òun lè lò láti fi gbé ọkọ̀ òfurufú náà fò nígbà àkọ́kọ́.
Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò lọ sí ilé ẹ̀kọ́ láti lọ kọ́ nípa ìmọ̀ yìí, ó ní ó wu òun láti lọ sí òkè òkun láti ló túnbọ̀ ní ìmọ̀ kíkún nípa nǹkan tí òun gbé lọ́wọ́.
Bákan náà ló ṣàlàyé pé àwọn ọkọ̀ òfurufú tí òun ń ṣe náà jẹ́ ohun tí wọ́n le máa fi fi nǹkan ránṣẹ́ láti ibìkan sí òmíràn ní èyí tí yóò yá ní kíákíá.






