''Òní ni àwoͅn oͅmoͅ Naijiria tó há sí Sudan yóò dé si Naijiria oͅmoͅogun''

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Alaga Ajo to n risi oͅroͅ awoͅn oͅmoͅ Naijiria ni oke okun, Abike Dabiri-Erewa ti fidireͅ muleͅ pe awoͅn oͅmoͅ Naijiria to ha si Sudan ti de Egypt ti woͅn yoo si de si Naijiria ni oni.

Dabiri- Erewa lo fi idi oͅroͅ naa muleͅ loju opo Twitter reͅ.

O ni ibode ti wa ni titi pa nigba ti awoͅn yoo fi de ibode ilu naa, ti woͅn yoo si maa loͅ si papakoͅ ofurufu ni aaroͅ.

‘’Awoͅn to saaju ti de orileͅede Egypt, ti woͅn yoo si gba ibeͅ loͅ si papakoͅ ofurufu ti ile oni ba moͅ.

Bakan naa ni ijoͅba apapoͅ naa fikun un pe ikoͅ oͅmoͅogun Naijiria ti ofurufu peͅlu ileeseͅ oͅkoͅ ofurufu Air Peace ti gba iwe irinna lati baleͅ si Egypt ki woͅn ko awoͅn oͅmoͅ Naijiria naa wa si ile.

Ijoͅba apapoͅ fikun un pe awoͅn n sa gbogbo ipa woͅn lati ri pe woͅn ko awoͅn oͅmoͅ Naijiria kuro nibeͅ ni kiakia.

Woͅn ni gbogbo ikoͅ lo n siseͅ poͅ peͅlu ileesͅeͅ ofurufu miran lati ri pe awoͅn oͅmoͅ Naijiria naa de ile ni ayoͅ ati alaafia.

Amoͅ saaju ni awoͅn oͅmoͅ Naijiria naa ti kede pe ko si oͅkoͅ ti yoo gbe woͅn, ti awoͅn kan si tun soͅ pe oͅkoͅ taku si aarin oͅna.

Àwọn ọmọ Nàìjíríà tó ti kúrò ní Sudan yóò balẹ̀ sílé lọ́la - Abike Dabiri

Àwọn ọmọ Nàìjíríà tó ń kúrò ní Sudan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Àwọn ọmọ Nàìjíríà tó ń kúrò ní Sudan

Ìjọba Nàìjíríà ti sọ̀rọ̀ lóri fídíò kan tó gba orí ayélujára kan pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń kó bọ̀ láti orílẹ̀ èdè Sudan ti há sí ibìkan.

Fọ́nrán tó gba orí ayélujára náà ṣàfihàn pé àwọn awakọ̀ tí wọ́n ń wa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣàdédé dúró lójú ọ̀nà pé àwọn kò ní lọ mọ́ àyàfi tí ìjọba bá san owó àwọn pé pérépéré.

Àtẹ̀jáde kan tí alága àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà nílẹ̀ òkèrè, Abike Dabiri-Erewa fi sórí Twitter rẹ̀ ní òun ti bá ọ̀gá àgbà àjọ NEMA sọ̀rọ̀ tó sì ti sọ àrídájú rẹ̀ fún òun pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti gbéra padà.

Ó ní gbogbo ìfaǹfà tó wáyé láàárín NEMA àti àwọn awakọ̀ náà ti ní ìyanjú tí àwọn ènìyàn náà sì ti ń padà bọ̀ nílé.

Ṣaájú ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ni àwọn wà nínú aṣálẹ̀ kan fún wákàtí márùn-ún níbi tí kò sí oúnjẹ tàbí omi fún àwọn àti pé ibi tí àwọn wà léwu púpọ̀.

Èyí sì ti ń fa awuyewuye láàárín àwọn ọmọ Nàìjíríà pé wọ́n ń fi ẹ̀mí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà wéwu.

Ọjọ́ Ẹtì ni àwọn tó bá kọ́kọ́ kúrò yóò dé Nàìjíríà

Abike Dabiri-Erewa nígbà tó ń bá àwọn aọ̀ròyìn sọ̀rọ̀

Oríṣun àwòrán, NiDCOM

Ṣáájú ni Abike Dabiri-Erewa nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ Ẹtì ni ìrètí wà pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ti kó kúrò ní Sudan yóò balẹ̀ sí Nàìjíríà.

Dabiri-Erewa ní mẹ́tàlá nínú àwọn ọkọ̀ ogójì tí ìjọba gbà láti fi kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kúrò ló ti kúrò ní Sudan láti ọjọ́rú tí ìrètí sì wà pé wọn yóò balẹ̀ sí Egypt ní ọjọ́bọ̀.

Ó ní Egypt ni àwọn yóò ti lọ fi bàálù kó àwọn ènìyàn náà kúrò àti pé àwọn bàálù náà ti ń gbéra kúrò ní Nàìjíríà láti lọ pàdé wọn báyìí.

Ó fi kun pé kò sí ọmọ Nàìjíríà kankan tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ ogun tó ń wáy;e ní Sudan lọ àti pé àwọn ní ìgbàgbọ́ pé kò sí ẹni tí yóò nù nínú àwọn tó ń bọ̀ lanà náà.

Kìí ṣe NIDCOM ló wà nídìí owó tí wọ́n fi gba ọkọ̀

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí bí àwọn ènìyàn ṣe ń bu ẹnu àtẹ́ lu owó tabua tí ìjọba fi gba ọkọ̀ tó ń àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bọ̀ padà sílé, ó ní àjọ òun kò mọ nǹkankan nípa rẹ̀.

Ó ní àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì, NEMA àti iléeṣẹ́ Humanitarian Services ló wà nídìí rẹ̀.

“₦‎150m ni ìjọba àpapọ̀ fi yá ọkọ̀ láti kó àwọn ọmọ Naijiria kúrò ní Sudan”

Minisita fun ọrọ ilẹ okeere, Zubairu Dada, ti sọ pe ẹmi ọmọ Naijiria kankan ko sọnu ninu rogbodiyan to n waye lorilẹ-ede Sudan.

Dada lo sọ ọrọ naa nibi ipade awọn akọroyin kan to waye lẹyin ipade igbimọ isaejọba Naijiria l’Abuja.

O fi kun pe iṣẹ ti n lọ lọwọ lati ko awọn ọmọ Naijiria ti iye wọn to ẹgbẹrun marun un kuro lorilẹ-ede ọhun.

Dada sọ siwaju si pe abala akọkọ awọn ti wọn yoo ko kuro nilẹ naa ti wa loju ọna, ati pe ọkọ akero bọọsi lawọn yoo fi ko awọn eeyan ọhun lọ si Egypt, nibi ti wọn yoo ti fi ọkọ ofurufu gbe wọn wa si Naijiria.

Gẹgẹ ohun to sọ, awọn aṣoju Naijiria, awọn ọmọde atawọn obinrin ni wọn yoo kọkọ doola ko to kan awọn to ku.

₦‎150m ni ijọba Naijiria fi ko awọn ọmọ Naijiria kuro ni Sudan

Ẹwẹ, ijọba apapọ ti fidi rẹ mulẹ pe owo ti iye rẹ to ₦‎150m lawọn ti na gẹgẹ bii owo ọkọ lati fi ko awọn Naijiria kuro ni Sudan.

Ọgbẹni kan, Okezie Atani lo kede bẹẹ loju opo Twitter rẹ, eyii ti alaga ajọ to n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijiria nilẹ okeere, Abike Dabiri-Erewa ṣapinlo rẹ.

Abike Dabiri-Erewa

Oríṣun àwòrán, Abike Dabiri

O ni “Ẹṣeun ọlọla Abike Dabiri-Erewa, adupẹ lọwọ ajọ NEMA ati Aarẹ Muhammadu Buhari.”

“Wọn ṣẹṣẹ san ₦‎150m gẹgẹ bii owo ọkọ lati ko awọn ọmọ Naijiria ti ogun ka mọ Sudan kuro nibẹ.

Bi ogun Sudan ṣe bẹrẹ

Ọpọ eeyan lo ti ku ni Sudan latari ija to n waye nibẹ, koda, oku awọn eeyan kan ti n jẹra lẹba oju popo, ti ọpọ dukia si ti ṣofo.

Ija naa lo n waye latari aigbọraẹniye laarin awọn ọmọ ogun to n ṣatilẹyin fun ọgagun Abdel Fattah al-Burhan, ati igbakeji rẹ nigba kan ri, ọgagun Mohamed Hamdan Daglo to ko awọn ọmọ ogun RSF sọdi.

Awọn ọmọ ogun RSF ọhun lo ti fi akoko igba kan ri jẹ ọmọ ogun agbesumọmi Janjaweed.

Nnkan bii ogun ọdun sẹyin ni Aarẹ tẹlẹ, Omar al-Bashir, da awọn ọmọ ogun agbesumọmi Janjaweed naa si agbegbe Dafur, nibi ti ọpọ ẹmi ti sọnu.