Àlàyé rèé lórí ogun tó ń wáyé ní Sudan táwọn ènìyàn fí ń sá kúrò níbẹ̀

Àlàyé rèé lórí ogun tó ń wáyé ní Sudan táwọn ènìyàn fí ń sá kúrò níbẹ̀
Awọn ọmọ ogun

Ìjà àwọn alágbára méjì ló ń wáyé ní orílẹ̀ èdè Sudan báyìí.

Àwọ adarí Ikọ̀ ọmọ ogun méjì ló ń jà sí ta ni yóò máa ṣe àkóso orílẹ̀ èdè náà èyí tó sì ti fa kí olú ìlú orílẹ̀ èdè náà ti di agbo ogun báyìí.

Bákan náà ni ọ̀p̣ọ̀ ènìyàn tó ti lé ní irinwo ti pàdánù ẹ̀mí láti ìgbà tí ogun ọ̀hún ti bẹ̀rẹ̀ báyìí.

Àkọ́kọ́ nínú àwọn ọ̀gágun méjì tó wà nídìí ogun yìí ni Ọ̀gágun Abdel Fattah al-Burhan tó jẹ́ olórí ọmọ ogun ilẹ̀ àti ààrẹ orílẹ̀ èdè Sudan láti ìgbà tí wọ́n ti gba ìjọba lọ́wọ́ ààrẹ Omar al-Bashir.

Ẹnìkejì ni Ọ̀gágun Mohammed Hamdan Dagalo tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Hemedti tó jẹ́ igbákejì Abddel Fattah al-Burhan.

Hemedti tún jẹ́ adarí ikọ̀ ètò ààbò kan tí orúkọ rẹ̀ n jẹ́ Rapid Support Forces, RSF.

Ohun tí àwọ Ọ̀gágu méjéèjì yìí n jà sí ni ọ̀rọ̀ bí wọ́ yóò ṣe máa darí orílẹ̀ èdè Sudan àti pé ẹnu wọn kò kò lórí ikọ̀ RSF nítorí àwọn ẹ̀sùn tí àwọn ènìyàn n fi kan ikọ̀ RSF pé wọ́n n tẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú mọ́lẹ̀.

Ogun tó n lọ lọ́wọ́ yìí bẹ́ sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́ pín ikọ̀ ọmọ ogun RSF káàkiri sí gbogbo ìlú tí iléeṣẹ́ ọmọ ogun sì rí ìgbésẹ̀ bíi ìdúnkokò.

Láti ìgbà tí wọ́n ti gba ìjọba lọ́wọ́ Omar al-Bashir lọ́dún 2019 ni wàhálà oṣèlú tí n wáyé ní orílẹ̀ èdè náà.

Nṣe ni ìbẹ̀rù wà báyìí pé ogun tó ń wáyé ní Sudan yìí le ṣokùnfà ìpínyà orílẹ̀ èdè náà tó sì tún le ṣàkóbá fún àwọn orílẹ̀ èdè tó múlé tìí.