Ọ̀pọ̀ Ọba tó ń gbé ẹ̀sìn Krìstẹ́nì àti Islam sórí ní gbangba, ló ń bá òrìṣà jẹ ní kọ̀rọ̀- Bàbá Osun Osogbo

Oríṣun àwòrán, Others
Olori ojubọ oriṣa Osun ni ilu Osogbo, Oloye Ọlayiwọla Adigun ti sọ wi pe gbogbo awọn ọbalaye to n gbe ẹsin atọhunrinwa ga dipo ẹsin ibilẹ yoo ri pipọn oju awọn alalẹ ilẹ yii.
Oloye Adigun ti ọpọ mọ si Baba Ọlọṣun ṣalaye ninu ifọrọwọrọ kan nilu Ọkinni, l’ẹgbẹ Osogbo BẸẸ.
O ni pe bi o ti wu ko ri gbogbo awọn lọbalọba ni yoo jiya bi wọn ṣe pa ẹsin abalaye ti si apa kan nitori ẹsin Kristẹni ati Islam eyi to pe ni awọn ẹsin ajeji.
Oloye Adigun to ti jẹ olori awọn Ọlọṣun ni ilu Osogbo lati nnkan bii ogoji ọdun ṣalaye pe alabosi lawọn ọbalaye to n pe ara wọn ni Kristẹni ati Alfa ni gbangba
Nigba to si jẹ pe awọn at’awọn oriṣa abalaye gbogbo ni wọn jijọ n jẹ ti wọn si n mu ni kọọrọ.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ ọpọ awọn ọba to n pe ara wọn ni Pasitọ tabi Alfa wọnyi li jẹ wi pe nitori owo ti wọn n ri gba lati ọdọ awọn ilẹ okeere kan tabi awọn eeyan kan lawujọ ni wọn tori n ṣe bẹẹ. O ni ewu nla leyi si lee mu ba ori itẹ ti wọn joko le.
Bakan naa lo fi kun un pe idi ti ẹsin abalaye ko tii fi ri oju rere ijọba lorilẹede Naijiria bii ti ẹsin Kristẹni ati Islam ko yẹ ni iwa agabangebe to ni awọn ọbalaye to yẹ ko maa gbe e soke nhu nipa iwa ati ọrọ wọn.
“Mo mọ pe ẹlẹsin abalaye pọnbele ni gbogbo awọn lọbalọba to n oe ara wọn ni Pasitọ ati Alfa tabi kristeni ati musulumi, wọn ko si le e ya ara wọn sọtọ kuro lara awọn oriṣa wa.
Bo pẹ bo ya, yoo lẹyin, ori awọn ọmọ wọn ni yoo si da ke nitori pe wọn ko tẹle iṣẹṣe
Baba Ọlọṣun ilu Osogbo tun ṣalaye oe ulẹ adulawọ nikan lo n ta ẹṣin abalaye rẹ nu nigba ti awọn orilẹede miran kaakiri agbaye n ko ẹsin tiwọn mọra.
“Awọn nnkan daradara to wa lati ilẹ ajeji ni wọn n gba, wọn ko ta aṣa ati ẹsin wọn nu.”















