Ayẹyẹ ìgbéyàwó ló jẹ àwọn obìnrin àsìkò yìí lógún jù ọgbọ́n láti gbé ínú ilé ọkọ lọ- Mike Bamiloye

Oríṣun àwòrán, Instagram/Mike Bamiloye
Agba ọjẹ osereOludasilẹ Mount Zion Faith Ministries, Mike Bamiloye ni pupọ awọn ọmọbinrin asiko yii ni wọn ko ni oye to peye lati di iyawo ile paapa awọn to tí balaga.
Bamiloye tun kẹkẹ ọrọ lori opo ayelujara rẹ, ni pupọ awọn ọmọbìnrin naa ni wọn gbaradi fun ayẹyẹ igbeyawo lasan.
"Pupọ wọn ni ko ẹkọ to peye lati wa ninu igbeyawo. Wọn ko mọ ohun ti igbeyawo da le lori.
"Gbogbo wọn n kanju, wọn ko si setan lati joko kọ nípa igbe aye tọkọtaya.
"Koda, ẹni ọdun mejidinlọgbọn ninu wọn ko ni imọ lati di iyawo ile."
"Pupọ wọn ni ko le dana afi oúnjẹ rira "
Bamiloye fikun pe awọn obinrin asiko yii kundun rira oúnjẹ níta kiri, tí wọn ko si le ṣe oúnjẹ fun ara wọn tabi ọkọ tí wọn fẹ.
O ni otitọ nipe ifẹ fọju sugbọn igbeyawo lo máa sìju ọpọlọpọ.
"Bayi, awọn ọdọ obìnrin wa ni wọn ti kọ lati kuro ninu igbeyawo. Pupọ wọn lo sare wọnu igbeyawo, ti wọn si tun sare jade nitori nnkan o lọ bí wọn ṣe fẹ"
"Mo lodi si fifi iya jẹ obinrin, ẹranko ni okùnrin to lu iyawo rẹ, ti ko yẹ ko ma gbe lawujọ eeyan."
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post















