‘Aláàfin Adeyemi ti mọ̀ nípa ikú rẹ̀ kí ọlọ́jọ́ tó dé’

Oba Lamidi Adeyemi

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Àkọ́bí aláàfin àná, Oba Lamidi Adeyemi Kẹta, ọmọọba Isreal Adeyemi ti ṣàlàyé àwọn ìgbà ìkéyìn Aláàfin kí baba tó re ìwàlẹ̀ àṣà.

Ọmọọba Adeyemi ní Aláàfin ti mọ̀ wí pé òun ti ń palẹ̀mọ́ láti lọ darapọ̀ mọ́ àwọn babańlá rẹ̀ kó tó di wí pé ó gbéra lọ sí ilé ìwòsàn.

Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan tí ọmọọba Adeyemi ṣe pẹ̀lú iléeṣẹ́ ìròyìn Nigerian Tribune ní Aláàfin láti ìgbà tó ti ń palẹ̀mọ́ ló ti ṣàlàyé fún àwọn ènìyàn ibi tó fẹ́ kí wọ́n sin òun sí.

Ó ní lọ́jọ́ tí àwọn ń gbé Aláàfin lọ sí ilé ìwòsàn lọ́jọ́ Àìkú nínú ọkọ̀ ilé ìwòsàn olùkọ́ni Afe Babalola, Ado-Ekiti, ó ní bí Aláàfin ṣe wọ inú ọkọ̀ ló bú sígbe gbaragada.

“Bí Aláàfin ṣe wọ inú ọkọ̀ tí a fẹ́ máa lọ, tí gbogbo wa ń wú wọn lórí ni Kábíèsí bẹ̀rẹ̀ sí ní sunkún.”

“Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí mà á rí bàbá mi tó máa bú sẹ́kún, ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí mà á rí omijé lójú bàbá mi.”

Adeyemi ní lẹ́yìn tí Aláàfin kú tán ní ó ṣẹ̀ṣẹ̀ yé òun wí pé bàbá òun ti mọ̀ wí pé òun kò ní padà sílé mọ́ ló fa ẹkún tọ ń sun.

“Ọ̀kan lára àwọn àmì àti àpẹẹrẹ tí Aláàfin fi hàn kó tó jáde láyé nìyí.”

Bákan náà ló fi kun pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni Aláàfin máa ń sọ̀rọ̀ nípa ikú rẹ̀ pàápàá tó bá wà pẹ̀lú àwọn tí wọ́n sún mọ́ ọn.

“Gbogbo ìgbà ló máa ń sọ̀rọ̀ nípa ikú, ó ti sọ fún àwọn ènìyàn ibi tí òun fẹ́ kí wọ́n sin òun sí, ó ti sọ àwọn nǹkan tí òun fẹ́ kí àwọn ènìyàn ṣe lẹ́yìn ikú òun.”

“Wọ́n sọ fún mi pé ní ọjọ́ tí wọ́n papòdà, òun sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn ní ilé ìwòsàn pé òun ti ń lọ sí ilé, a ti ń múra, à ń lọ, gbogbo àwọn tó súnmọ́ wọn mọ̀ pé baba ti ń lọ ibi àgbà ń rè nìyẹn.”

A ti ń gbé ìgbésẹ̀ láti ṣe nǹkan mánigbàgbé lórúkọ Aláàfin

Oba Lamidi Adeyemi

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Bákan náà ló ṣàlàyé pé òun ti ń gbé ìgbésẹ̀ láti ṣe àwọn nǹkan mánigbàgbé lórúkọ bàbá òun láti ri pé otípa bàbá kò parẹ́.

Ó ní òun gbàgbọ́ pé lára nǹkan tí òun le ṣe láti ri dájú pé orípa bàbá òun kò parẹ́ ni láti gbé nǹkan kalẹ̀ lọ́nà ẹ̀kọ́ nítorí ẹni tó fẹ́ràn ẹ̀kọ́ ni Aláàfin jẹ́.

Ó ní òun ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti máa ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní ọdọọdún níbi tí àwọn èèyàn yóò ti máa kẹ́kọ̀ọ́ kan tàbí òmíràn.

“Lára àwọn nǹkan tí a fẹ́ máa ṣe, ọ̀kan máa wáyé ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Karùn-ún níbi tí àwọn tó nímọ̀ nípa Aláàfin yóò ti sọ̀rọ̀ nípa ìgbé ayé rẹ̀.”

“Bákan náà là ń gbèrò láti ṣe àgbékalẹ̀ àjọ ẹlẹ́yinjú àánú, mó fẹ́ kí àwọn ènìyàn ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn èrò Aláàfin, bí ó ṣe ń ṣiṣẹ́ nígbà tó wà láyé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.”

Ẹ wo ọ̀rọ̀ ìwúrí tí àwọn ènìyàn sọ̀ níbí ayẹyẹ ọdún kan tí Aláàfin Ọ̀yọ, Ọba Adeyemi wàjà

Aworan ọba Lamidi

Ọdun kan lẹyin ipapoda Kabiyesi Ọba Lamidi Adeyemi kẹta Alaafin ti ilu Oyo.

Awọn ẹgbẹ olorisa ti Aafin Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta, aṣoju aṣa fun Aafin Oyo, Paula Gomes, awọn ọmọ Kabiyesi to waja, ati awọn iyawo rẹ lo peju pesẹ sibi ayẹyẹ ọhun.

Ayẹyẹ isin iranti naa ni o bẹrẹ ni Bara, loju oori Kabiyesi, nibi ti awọn ẹlẹsin abalaye ti ṣe adura ati Isure loju oori Kabiyesi, pẹlu fi fọn Ekọ ati akara gẹgẹ bi aṣa àti iṣe ilẹ Yoruba.

Aworan ayaba Kabiyesi

Laara awọn ọmọ Alaafin to gbeṣe, ọmọ ọbabìnrin Adejoju Adeyemi to ba ileeṣẹ BBC sọrọ, koro oju si bi ijọba ipinlẹ Oyo, ati awọn ti Kabiyesi iku baba yeye ti sore fun, ṣe ta idile naa nu. Adejoju ni, "pẹlu iru ipo ti Kabiyesi Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi dimu nilẹ Yoruba,o yẹ ki Ijọba ṣe ayẹyẹ nla lọdọọdun, lati ṣe iranti Kabiyesi ki wọn si tun ṣe eto ti yo sọ gbogbo idagbasoke ti Kabiyesi ti ṣe fun ilu Oyo ati ilẹ Yoruba lapapọ silẹ ". Rukayat Adeyemi ọkan lara awọn ayaba Kabiyesi ni iku baba yeye bi aala lori nigba ti Kabiyesi darapọ mọ n awọn baba wọn. Rukayat ni" ẹniti o ṣoju ko dabi ẹniti o ṣe ẹyin,ti imole ba wa dudu diẹ naa ma wa,gbogbo awọn ọmọ n gbiyanju, ṣugbọn ko le ma si kanda ninu irẹsi.

Àwọn òrìṣà ààfin kó jẹ́ kí nsun ...Ọmọọba Adejoju

Awon Ọmọọba

Adejoju ni"inu mi o dun wi pe ko si eeyan laafin, mi n mo ninu itan bọya wọn ma n ti aafin,ko ba wu mi ki ilẹkun aafin wa ni sisi nitori awon isedalẹ wa ninu aafin".

"Ṣugbọn Oosa kan wà ninu ile ti wọn nilo bibọ lojoojumọ,ọmọ alaafin ni awa,awa ọmọ alafin la mọ riri rẹ àti ipa ti wọn n ko, bi a ti si ni aafin yii wọn wa ń bawa nibiti awa wa,wọn si ti ilẹkun mọ wọn, awọn oosa ọhun ko lọ ba awọn to ti ilẹkun mọ wọn, awa ọmọ alafin ni wọn yọju si".

Ọrọ ijọba lati ṣi aafin, kí awọn ara ilu le ma wọle sinu aafin nigba ti o wu wọn.

Kabiyesi Ọba Lamidi gbe aṣa larugẹ- Gomez

Alaga aṣa orisa alafin ilu Oyo, Oke Adejare ni iku Kabiyesi mu adinku ba bi awọn oniṣeṣe tí n ṣe eto wọn, nitori lati igba ti Kabiyesi ti ku alafia wa nilu Oyo sugbọn nkan ó lọ bose yẹ.

Adejare ni"gbogbo nkan o lọ bo ti ma n lọ,ọja gan-an ko ta bose yẹ, paapaa awọn ọdun ibilẹ ti a ma n ṣe ni ko dabi ti tẹlẹ mọ".

Paula Gomes aṣoju aṣa aafin Kabiyesi iku baba yeye ni "iku kabiyesi ko rọrun, ọpọ iṣẹ ni Kabiyesi fi silẹ fún oun.

Paula Gomes

Paula ni"mo n tẹsiwaju lati ṣe iṣẹ ti Kabiyesi gbe lemi lọwọ,gbogbo eto iranti Kabiyesi ta ṣe loni ko sẹyin awa olorisa,a pin akara ati ẹko lati ṣe iranti Kabiyesi iku baba yeye ".

Nigba ti oun sọrọ lori ibasepọ rẹ pẹlu Kabiyesi Ọba Lamidi Adeyemi Olayiwola kẹta Paula ni,"Ọdun mejila ni mọ lọ pẹlu Kabiyesi mọ feran rẹ gan, o gbe aṣa rẹ larugẹ, a ó le gbagbe Olayiwola, gbogbo igba ni oun ko mi ni nkan titun lori asa Yoruba".

Paula ni "Mo fẹ tẹsiwaju ninu iṣẹ to fun mi, igbagbọ mi ni wi pe Kabiyesi tuntun yoo tẹlẹ ilana ti olayiwola fi silẹ,a o le gbagbe Olayiwola ko ṣeeṣe,nkan ti mọ gbọdọ ṣe fun ni wi pe ki n pari iṣẹ to gbe fun mi, ka si ri wi pe orukọ rẹ ko parun".