Ọdún kan lẹ́yìn ikú Alaafin, àgbéyẹ̀wò bí nǹkan ṣe rí rèé

Oríṣun àwòrán, Alaafin of Oyo Facebook
Iku Baba yeye, igbakeji orisa, Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi jẹ Alaafin fun ọdun mọkanlelaadọta ati osu marun-un, to si jẹ ọkan lara Ọba ilẹ Yoruba to laami-laaka ni ilẹ Naijiria ati oke okun.
Ti a ba sọrọ nípa asa, Oba Adeyemi gan an ni o yẹ ka pe ni asa nítorí bo se ni ijinlẹ imọ ninu asa ati ise ilẹ Yoruba ati oke okun.
Odun 1938 ninu osu kẹwaa ni a bi Ọba Adeyemi si idile Alowolodu, to si jẹ ọmọ Alaafin ana, eyiu Ọba Adeyemi II ti wọn ro lo ye lọdun 1954.
Adeyemi III bọ sori itẹ Baba rẹ lọdun 1970, ti wọn si gbe Ade Ọba fun lọdun 1971.
Ni ilẹ Yoruba, Ọba kii ku, Ọba maa n waja ni.
Lọdun 2022, ninu osu kẹrin, Ọba Adeyemi III da gbere fun aye lẹni ọdun mẹtalelọgọrun ni ile wosan Afe Babalola niluu Ekiti.

Oríṣun àwòrán, Arewa Omooba
Ìtùnú awẹ́ láìsí Baba wa dá yàtọ̀ - Ọmọọba Arẹwa
Ọkan lara ọmọ Alaafin ìlu Oyo to waja, Ọmọọba Arẹwa ni idile Adeyemi mọ lara pe Kabiyesi ko si laye mọ.
Sugbọn ipa tí wọn ko nínu igbesi aye awọn ọmọ ati awọn eeyan nipinlẹ Oyo lo jẹ manigbagbe.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba, Ọmọọba Arẹwa ni o ṣe ni laanu pe iru ọjọ oni to jẹ ọdun itunu awẹ, baba ko si laye.
"Iru ọjọ oni lasiko ti wọn wa laye, lẹyin Eid ni ilu ati ìjo yoo ti bẹrẹ ti gbogbo wa yoo si ijo pade wọn ti wọn ba tí n bọ lati mọsalasi.
"N ko gbogbọ o ti pe ọdun kan, o da bi ana sugbọn adupẹ pe gbogbo idile ni wọn ṣe arawọn lọkan.
"igbesi aye baba rọnu pupọ, ti mo fẹràn wọn pupọ

Oríṣun àwòrán, Omooba Arewa
"Ko da ju pe a le ri irufẹ Alaafin Adeyemi niluu Oyo mọ"
Arẹwa tẹsiwaju pẹlu omije pe yoo nira lati irufẹ Ọba Lamidi Adeyemi III gẹgẹ Ọba alade ni ile Yoruba nitori ohun mere mere ti Ọba gbe aye ṣe.
Yatọ si pe Ọba Adeyemi jẹ Ọba, Arẹwa sapejuwe baba rẹ gẹgẹ bii baba to nifẹ awọn ọmọ pupọ.
"Iru Ọlọrun ni ko si sugbọn yoo nira lati ri irufẹ Alaafin Lamidi Atanda Olayiwola Adeyemi mọ.
"Ọpọ igba ni Baba ko gbogbo wa rin irinajo, pẹlu ni a fi gbe papọ
"Ninu osu kẹta lọdun to kọja, n ko mọ pe wọn da gbere ni ode ti a jọ lọ gbẹyin to jẹ ọjobi Iyawo Baba Ladigbolu.
"Mo lọ kí wọn ní Baba ba sọ fun mi pe ki n kì awọn ni ti ibilẹ, ti mo sì kí wọn ni iki ibilẹ lai mọ pe wọn dagbere fun mi nìyẹn.
"Mo fẹran àkókò naa pupọ sugbọn gbogbo rẹ lo ye Ọlọ́run."
Gbogbo ilu Oyo lo n daro Ọba Adeyemi - Oyomesi
Olori Oyomesi ati adele Alaafin Oyo, Basorun Akinade Ayoola Yusuf ni gbogbo ilu ni saro ipapoda Ọba Adeyemi ati bí ko ṣe Ọba niluu Oyo lasiko yii.
Barosun ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ileeṣẹ BBC News Yoruba, ni ọpọ nnkan ni ko le waye niluu nítorí ko si Ọba lori itẹ.
Bákan naa, Basorun ni ìjọba nipinlẹ Oyo nìkan lo ni anfani lati kede Ọba tuntun niluu Oyo ati pe Oyomesi ti ṣe ojuṣe rẹ lati fi ọrọ wa awọn ọmọ ọba lẹnu wo lori tan gan an ni ipo naa tọ si.
"Gbogbo ilu lo daro Ọba Adeyemi, awa Oyomesi gan ń daro Ọba nitori Olori wa ni.
"Ọpọ nnkan ni a ko le se nitori ko Ọba lori itẹ lọwọlọwọ bayi.
"Chief Imam wa naa ku, a ko le yan ẹlẹlomiiran nitori Ọba nìkan lo le yan Imam wa tuntun.
"Ati fi esi wa ransẹ sì ìjọba nitori awọn nìkan lo ní asẹ lati kede Ọba tuntun niluu Oyo."















