Twitter ń gbọn “blue tick” yọ, wo àwọn àgbà òṣèlú, olórin, òṣèré fíìmù Yorùbá tí kò sanwó “blue tick” fún Elon Musk

Awọn eekan

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Oju opo ikansiraẹni agbaye Twitter ti bẹrẹ si ni gbe igbesẹ lori ọrọ ti wọn fi lede nigba diẹ sẹyin pe awọn eeyan yoo bẹrẹ si ni san owo lati le ni maaki alawọn buluu.

Maaki buluu yii lo maa n ṣamii idamọ fun awọn eeyan pataki lawujọ̀ latori awọn adari orilẹede titi de gbogbo eeyan to ba ti di ilumọọka lori ayelujara twitter atawọn oju opo ayelujara ikansiraẹni miran.

Ni orilẹede Naijiria, ko yọ awọn adari ati oloṣelu silẹ rara koda ko yọ awọn adari ẹsin, awọn ileeṣẹ to lorukọ to fi mọ awọn gbajugbaja oṣere silẹ.

Koda, ọpọlọpọ wọn lo ti n fi ọrọ sita loju opo wọn ti ko ni “blue tick”.

Awọn oloṣelu

Bola Tinubu

Nigba ti a wo oju opo ikansiraẹni awọn oludije sipo aarẹ ni ẹgbẹ oṣelu mẹtẹta to ga ju, ileeṣẹ Twitter ti gbọn maaki buluu yọ loju opo wọn.

Ẹni ti o jẹ aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ni Naijiria, Ahmed Bola Tinubu naa wa lara awọ́n ti oludasilẹ Twitter fa maaki buluu yọ loju opo rẹ.

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Tinubu/Twitter

Atiku Abubakar

Bakan naa la ba loju opo Twitter oludije ipo aarẹ fun ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, Alhaji Atiku Abubakar.

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, Atiku/Twitter

Peter Obi

Ko yọ oludije ẹgbẹ oṣelu Labour Party naa silẹ, loju opo tirẹ naa, oludasilẹ Twitter ti yọ maaki buluu to wa nibẹ.

Peter Obi

Oríṣun àwòrán, Peter Obi/Twitter

Bakan naa, awọn eekan ilẹ Gẹẹsi ko gbẹyin o.

- Aarẹ Amẹrika tẹlẹ ri Donald Trump fara gba a

-Justin Bieber, gbajumọ olorin Canada

-Adari gbogbo ijọ Katoliiki lagba

- Ogbontagi agbabọọlu Cristiano Ronaldo

Ki ni eleyi yoo tumọ si nipa “blue tick” yiyọ?

Blue tick

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọpọlọpọ ẹda orukọ oju opo ikansiraẹni awọn eeyan lo wa to jẹ bii ayederu to si jẹ pe maaki buluu yii nikan ni ẹ le tete fi mọ eyi to jẹ ojulowo gangan amọ aparo kan o ga ju kan lọ mọ bayii laarin gbogbo awọn to n lo oju opo ayelujara.

Oludasilẹ oju opo ikansiraẹni Twitter, elon Musk ti sọ ṣaaju akoko yii pe oun fun gbogbo eeyan to ni “blue tick” loju opo Twitter ni ooreọfẹ asiko diẹ yii ni lyin eyi ti wọn yoo bẹrẹ si ni san owo lati ni maaki buluu naa.

Ẹnikẹni ti ko ba maa san owo loṣooṣu eyi to kọkọ fi iye rẹ pe owo Dollar mẹjọ, ko ni ni maaki buluu lẹgb orukọ rẹ lori Twitter.

Nibayii, ko tii pẹ ti wọn gbọn gbogbo maaki buluu ọhun yọ ti iroyin jade pe iye owo ti wọn yoo san lati nii pada ti di Dollar mọkanla.

Ni Ọjọbọ ogunjọ oṣu kẹrin bẹrẹ si ni ku giri yọ ọgọọrọ maaki buluu lara oju opo awọn eeyan koda to fi mọ ti awọn oniroyin ati akaroyin naa.

Wo awọn gbajumọ oṣere Yoruba, Gẹẹsi ati olorin to ni "blue tick" amọ ti wọn ti di alaini bayii

Naira Marley

Oríṣun àwòrán, Twitter

Toyin Abraham

Oríṣun àwòrán, Twitter

Funke Akindele

Oríṣun àwòrán, Twitter

Davido

Oríṣun àwòrán, Twitter