Ààrẹ Buhari ní kí alákoso àjọ INEC ní Adamawa, Hudu Yunusa Ari lọ rọọ́kún níle

Oríṣun àwòrán, other
Aarẹ Muhammadu Buhari ti fọwọ si aṣẹ fun alakoso ajọ INEC nipinlẹ Adamawa, Amofin Hudu Yunusa Ari lati lọ rọọkun nile titi di igba ti ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria yoo fi pari iwadii lori iwa to hu lasiko atundi ibo gomina to waye nipinlẹ naa.
Ninu atẹjade kan, aarẹ Buhari paṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ ni kiakia lori iṣẹlẹ naa, ki wọn si gbe Amofin Hudu Yunusa Ari lọ si ile ẹjọ bi iwadii ba fihan pe o lẹbọ̀ lẹru.
Oludari eto iroyin ni ọfiisi akọwe ijọba apapọ Naijiria, Willie Bassey lo kede aṣẹ ti aarẹ orilẹede Naijiria pa ninu atẹjade naa.
Bakan naa ni aarẹ Muhammadu Buhari tun paṣẹ fun ọga ọlọpaa ni Naijiria, oludari agba ileeṣẹ alaabo DSS pẹlu ọga agba ajọ sifu difẹnsi, NSCDC lati ṣe iwadii ipa ti gbogbo awọn oṣiṣẹ wọn ko ninu ṣiṣe atilẹyin fun Amofin Hudu ninu igbesẹ kotọ naa ki wọn si gbe igbesẹ ibawi yoowu to ba yẹ fun eyikeyi to ba jẹbi ninu wọn.








