Aláwàdà ni ọ̀gá INEC nípínlẹ̀ Adamawa tó kéde olùdíje APC gẹ́gẹ́ bí olúborí ìbò gómìnà – PDP

Aworan Fintiri ati Binani

Oríṣun àwòrán, other

Ẹgbẹ oṣelu PDP ti tọka si igbesẹ ti alakoso ajọ INEC ni ipinlẹ Adamawa, Amofin Hudu Yunusa Ari gbe lati kede Aisha Binani gẹgẹbi olubori ibo gomina nipinlẹ naa gẹgẹbi awada kẹrikẹri.

Ninu ọrọ to ba BBC News sọ ni ibudo akojọpọ ibo gomina nipinlẹ naa, eyi to wa nilu Yola, aṣoju agba fun ẹgbẹ oṣelu PDP fun eto idibo naa, Aliyu Idi Hong sọ pe ohun to bani lọkan jẹ jọjọ ni pe alakoso ajọ INEC le e gbe igbesẹ bẹẹ lasiko ti awọn ọga agba ajọ agbofinro kan wa ni ijoko.

O ni adari ajọ INEC ni ipinlẹ Adamawa to kede esi ibo to n da họwuhọwu silẹ naa ko tilẹ lẹtọ lati da si eto naa ati pe Ọjọgbọn Muhammadu Mele to jẹ oludari eto idibo gomina nipinlẹ ọhun ti ofin mọ gan ko si ninu gbọngan naa lasiko ti Amofin Ari fi kede esi yii.

“Ohun ti awa mọ nipe ikede naa ko ba ofin mu, ko tọna bẹẹni ko lẹsẹ nlẹ.”

Aliyu Idi Hong to ti figbakan ri jẹ minisita lorilẹede Naijiria ni ohun ti awọn mọ bayii ni pe ki alakoso eto idibo naa, iyẹn ọjọgbọn Muhammadu Mele o pada wa pari akojọpọ awọn esi idibo lati awọn ijọba ibilẹ mẹwaa to ku ko si kede olubori ibo naa.

Wàhálà lórí ìdìbò Adamawa, ọ̀gá INEC kéde olùdíje APC gẹ́gẹ́bi gómìnà tuntun, olú iléeṣẹ́ àjọ INEC ní kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀

Aworan alaga ajọ INEC ni ipinlẹ Adamawa, Hudu Yinusa Ari

Oríṣun àwòrán, screenshot

Idarudapọ bẹ silẹ ni ibudo akojọpọ ibo fun idibo gomina nipinlẹ Adamawa eyi to wa nilu Yola nibi ti ọga agba ajọ INEC ni ipinlẹ naa, amofin Hudu Yunusa Ari ti kede oludije fun ipo gomina lẹgbẹ oṣelu APC Aisha Binani gẹgẹbi olubori idibo gomina ni ipinlẹ ọhun.

Kikede ti Amofin . Hudu Yunusa Ari kede Binani lẹyin atundi ibo to waye lọjọ Satide kede arabinrin Binani waye laisi alamojuto eto idibo, iyẹn ‘Returning officer’ ti mu ki ọpọlọpọ o maa pariwo pe ọgbọ n run lori ọrọ naa.

Ninu ọrọ to sọ nibẹ, alaga aj INEC ni ipinlẹ naa sọ pe lootọ awọn eeyan kan n sọ pe awọn fẹ ki oun yẹba ṣugbọn oun mọ pe aarẹ ati ida meji ninu mẹta ile aṣofin agba lorilẹede Naijiria nikan lo le yọ oun.

O ni akojọpọ gbogbo esi to wa latawọn ibudo idibo ti awọn atundi ibo ti waye lo mu ki un kede Binani gẹgẹbi olubori.

INEC wọgile eto akojọpọ idibo ni Adamawa

Nibayii, ajọ INEC ti paṣẹ ki wọn sio eto akojọpọ ibo nibẹ rọ naa lẹyin igbesẹ ‘ti ko lẹsẹ nlẹ’ eyi ti alaga ajọ naa ni ipinlẹ Adamawa gbe.

Ninu atẹjade kan ti kọmiṣọna fun eto iroyin ati idanilẹkọ fawọn oludibo lajọ INEC, Amofin Festus Okoye fi sita, igbesẹ naa ku diẹ kaa to ko si lẹsẹ nlẹ rara.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

“Igbesẹ ti alaga ajọ INEC ni ipinlẹ Adamawa gbe jẹ lilọ agbara gba mọ adari eto idibo gomina ni ipinlẹ naa lọwọ koda, lasiko ti eto ibo naa ṣi n lọ lọwọ laitii pari.

“nitori idi eyi a so eto akojọpọ ibo rọ.”

Ajọ INEC wa paṣẹ fun alaga ajọ naa ni ipinlẹ Adamawa, alakoso eto idibo gomina ni ipinlẹ naa atawọn ti ọrọ naa kan lati fara han lolu ileeṣẹ ajọ INEC nilu Abuja lẹyẹ o ṣọka.

INEC so kíkéde èsì ìdìbò rọ̀ ní Adamawa nítorí 'àṣẹ láti Abuja'

Awọn oludibo ni ibudo idibo

Esi atundi ibo fun ipo gomina ni ipinlẹ Adamawa ti n wọle ṣugbọn alakoso eto idibo naa, Ọjọgbọn Muhammadu Mele so kikede esi ibo naa rọ lalẹ ana nitori ohun to pe ni ‘aṣẹ lati Abuja’

Ọjọgbọn Mele ni eto kikede awọn esi ibo naa yoo pada bẹrẹ ni agogo mọkanla ọjọ Aiku.

Adari eto idibo sipo gomina ni ipinlẹ Adamawa naa kede eyi lẹyin ti awọn agbofinro kan ya wọ ibudo ikabo naa nilu Yola.

Amọṣa, ki o to so eto naa rọ, ajọ INEC ti kede esi idibo lawọn ijọba ibilẹ mẹwaa ninu ogun ijọba ibilẹ ti atundi ibo ti waye.

Awọn ijọba ibilẹ naa ni Hong, Maiha, Shelleng, Song, Ganye, Jada, Yola North, Lamurde, Yola South, Demsa,

Lapapọ ibudo idibo mẹtadinlaadọrin ni atundi ibo ti waye lọjọ Abamẹta.

Ni aṣalẹ ọjọ Abamẹta ni eto akojọpọ idibo bẹrẹ nilu Yola.

Aṣojukọroyin BBC to wa nibẹ jabọ pe gbagbagba lawọn ẹṣọ alabo bo ibudo akojọpọ ibo gomina nilu Yola naa

Awọn oṣiṣẹ eleto idibo n ka ibo nibudo idibo kan ni Yola

Ajọ INEC ṣeto atundi ibo ni ipinlẹ Adamawa lẹyin ti Alamojuto eto idibo nipinlẹ naa, Ọjọgbọn Muhammadu Mele lati fasityi Maiduguri kede pe idibo naa ko tii kẹsẹjari nitor iye ibo to wa laarin awọn mejeeji.

Lasiko idibo apapọ gomina to waye lọjọ kejidinlogun oṣu kẹta, Fintiri ni ibo ẹgbẹrun okoolerin ati ẹyọkan o le ẹẹdẹgbẹta ati mẹrinlelogun (421, 524) nigba tiBinani ni ibo ẹgbẹrun lọna irinwo o din mẹwaa ati ọrinlelugba o din marun (390, 275).

Ọpọ onwoye ati ọmọ Naijiria lapapọ ni wọn n reti bi ọrọ yoo ti ṣe lọ si ni ipinlẹ naa, paapaajulọ laarin gomina Fintiri ti PDP to n le saa keji ati Arabinrin Binani ti oun pẹlu n lepa ati di obinrin akọkọ ti yoo jẹ gomina ipinlẹ ni Naijiria.

EFCC kó òṣìṣẹ́ 100 ránṣẹ́ s'bi àtúndì ìbò ní Kano, Katsina, Jigawa láti dènà dìbò ko sebẹ̀

Awọn oludibo ni ibudo idibo kan ni Yola

Ọgọrun ọtẹlẹmuyẹ ni ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ to n tigi boju iṣuna ni Naijiria, EFCC ko ranṣẹ sibi eto idibo atundi to n waye ni ipinlẹ Kano, Katsina ati Jigawa lọjọ Satide.

Ọga agba ajọ naa lẹkun kano, Ọgbẹni Farouk Dogondaji lo ṣalaye eyi ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ akoroyinjọ Naijiria, NAN nilu Kano.

Dogondaji ni ogun ọtẹlẹmuyẹ EFCC ni yoo wa ni Kafur, Kankara ni ipinlẹ Katsina lati mojuto atundi ibo ile igbimọ aṣofin ipinlẹ nibẹ.

O tun ṣalaye pe wọn tun ko awọn ọtẹlẹmuyẹ to to lọsibi atundi ibo to n waye fun ijoko aṣojuṣofin ni ẹkun Tundun wada/Doguwa ati Takai tofimọ awọn atundi ibo sile igbimọ aṣofin ipinlẹ ni ipinlẹ Kano.

Bakan naa ni Ọga agba ajọ EFCC naa tun ṣalaye pe wọn fi awọn oṣiṣẹ ajọ naa kan ṣọwọ si ipinlẹ Jigawa ati Katsina lati dena iwa dibo ko sebẹ nibẹ atundi ibo sile aṣofin ipinlẹ nibẹ.

Àtúndì ìbò ti bẹ̀rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Oyo àtàwọn ìpínlẹ̀ míràn ní Nàìjíríà

Awọn oludibo n ṣe ayẹwo orukọ wọn ni ibudo idibo kan ni Yola, ipinlẹ Adamawa

Awọn ẹgbẹ oṣelu lorilẹede Naijiria yoo tun pada si ori papa lati takangbọn nibi awọn atundi ibo lẹlẹkunjẹkun eyi ti ajọ eleto idibo Naijiria, INEC gbe kalẹ lati waye lọjọ Satide ọjọ karundinlogun oṣu kẹrin ọdun 2023.

Awọn ibo wọn lawọn ibo ti ajọ naa ko lee fi ẹnu wọn jona sibikan lasiko idibo apapọ to kọja.

Ajọ INEC kede awọn eto idibo kan lasiko idibo apapọ naa pe wọn ko kẹsẹjari to si pe wọn ni ‘inconclusive’ lede oyinbo ti o si wọgile awọn esi miran lawọn ẹkun idibo kan.

Awọn idibo wo lọrọ kan?

Awọn oludibo n ṣe ayẹwo orukọ wọn ni ibudo idibo kan ni Yola, ipinlẹ Adamawa

Lara awọn atundi ibo ti yoo waye ni ibo si ijoko ile aṣofin mẹrinlelaadọrun lẹka apapọ atawọn ipinlẹ.

Bakan naa ni idibo si ipo gomina yoo waye lawọn ipinlẹ meji, iyẹn ipinlẹ Adamawa ati Kebbi.

Atundi ibo yoo waye lawọn ẹkun aṣofin apapọ sẹnetọ marun un, ẹkun idibo apapọ mọkanlelọgbọn fun ijoko ile aṣojuṣofin ati idibo si ijoko ile aṣofin mejidinlaadọta to jẹ ti ile aṣofin ipinlẹ kaakiri Naijiria.

Awọn ipinlẹ ti atundi ibo si ijoko ile aṣofin apapọ agba yoo ti waye ni ipinlẹ sokoto, Kebbi ati Zamfara.

Ni ipinlẹ Sokoto atundi ibo yoo waye ni ibudo idibo ọrinlelọdunrun o le ẹyọkan, (389) kaakiri ẹkun ariwa Sokoto, ila oorun Sokoto ati gusu sokoto.

Awọn oludibo to le diẹ lẹgbẹrun lọna Okoolelugba ati meje (227,743) ni ireti wa pe yoo kopa ninu eto idibo naa.

Awọn oludibo n ṣe ayẹwo orukọ wọn ni ibudo idibo kan ni ipinlẹ Rivers

Bakan naa ni atundi ibo yoo waye ni ibudo idibo mẹtalelogun ni ẹkun idibo apapọ fun ijoko sẹnetọ lẹkun ariwa Kebbi lati mọ ẹni ti awọn oludibo to le ni ẹgbẹrun mẹtala nibẹ yoo dibo fun.

Ẹwẹ, atundi ibo yoo si tun kan awọn ibudo idibo mẹtalelọgọrin ni ẹkun idibo apapọ fun ijoko sẹnetọ lẹkun aringbungbun Zamfara.

Eto atundi ibo si ijoko ile aṣojuṣofin apapọ yoo waye lawọn ẹkun idibo mọkanlelọgbọn kaakiri ipinlẹ Marundinlogun.

Awọn ipinlẹ ti ọrọ kan ni Ebonyi (ẹyọkan), Anambra (ẹyọkan), Rivers (Meji), Sokoto (mọkanla), Taraba (ẹyọkan), Bayelsa (ẹyọ̀kan), Edo (ẹyọkan), Imo (Ẹyọkan, Kano (meji), Kebbi (meji), Kogi (ẹyọ kan) Ọyọ (meji), Zamfara (meji), Jigawa (ẹyọ kan) ati Akwa Ibom (meji).

Fun ti awọn ijoko ile aṣofin ipinlẹ, ẹkun idibo mejidinlọgọta ni atundi ibo yoo ti waye kaakiri awọn ipinlẹ mẹtadinlogun.

Binani tabi Fintiri – ṣe Naijiria yoo lanfani obinrin akọkọ gẹgẹbi gomina?

Awọn oludibo n ṣe ayẹwo orukọ wọn ni ibudo idibo kan ni Yola, ipinlẹ Adamawa
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ipinlẹ Adamawa ati Kebbi ni gbogbo oju yoo dojukọ bayii fun atundi ibo gomina.

Ni Adamawa ni gomina Ahmadu Fintiri ti ẹgbẹ oṣelu PDP yoo ti maa waako pẹlu Arabinrin Aisha Binani ti ẹgbẹ oṣelu APC.

Alamojuto eto idibo nipinlẹ naa, Ọjọgbọn Muhammadu Mele lati fasityi Maiduguri kede pe idibo naa ko tii kẹsẹjari nitor iye ibo to wa laarin awọn mejeeji.

Lasiko idibo apapọ gomina to waye lọjọ kejidinlogun oṣu kẹta, Fintiri ni ibo ẹgbẹrun okoolerin ati ẹyọkan o le ẹẹdẹgbẹta ati mẹrinlelogun (421, 524) nigba tiBinani ni ibo ẹgbẹrun lọna irinwo o din mẹwaa ati ọrinlelugba o din marun (390, 275).

Aṣeyọri Binani lee fun Naijiria lanfani lati ni obinrin akọkọ ni ipo gomina, amọṣa bi Fintiri ba bori, yoo fun un lanfani saa keji lori oye.

Ni Kebbi, bakan naa ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP ni yoo maa waako fun atundi ibo gomina nibẹ.

Ajọ INEC kede pe ibo naa ko tii kẹsẹjari lẹyin ti wọn wọgile awọn esi ibo kaakiri awọn ibudo idibo ni ijọba ibilẹ ogun ninu mọkanlelogun to wa ni ipinlẹ ọhun.