Ọkùnrin tó wọ aṣọ ẹ̀há láti kópa nínú ìdíje àwọn obìnrin kó sí páńpẹ́ òfin

Bernard Omondi

Oríṣun àwòrán, KENYA CHESS

Ńṣe ni ọ̀rọ̀ dàbí àwàdà kẹríkẹrí nígbà tí ọkùnrin kan wọ aṣọ bí ẹlẹ́hàá láti lọ kópa nínú ìdíje àwọn obìnrin.

Stanley Omondi wọ aṣọ àwọn ẹlẹ́hàá, dé ìgò sójú, tó sì tún forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ Illicent Awour láti kópa níbi ìdíje náà.

Ní orílẹ̀ èdè Kenya ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé níbi ìdíje Chess tó wáyé níbẹ̀.

Àmọ́ àṣírí Omondi tú nígbà tí àwọn tó ṣàgbékalẹ̀ ìdíje náà rí bí ó ṣe ń ta ayo náà dára púpọ̀ tí àwọn kò sì mọ̀ ọ́n rárá.

"Mo nílò owó ní kíákíá ni mo ṣe da bí ọgbọ́n"

Omondi ní nítorí pé òun nílò owó ni òun ṣe rò ó láti ṣe bí obìnrin lọ síbi ìdíje náà.

Ó sọ èyí nínú ìwé kan tó kọ láti tọrọ àforíjì lórí ìgbésẹ̀ rẹ̀.

Bákan náà ló ní òun ti setan láti kojú gbogbo ìjìyà tí yóò bá tẹ̀yìn ìgbésẹ̀ òun yọ àmọ́ ó kọ̀ láti bá BBC sọ̀rọ̀.

Omondi kò ní láǹfàní láti kópa nínú ìdíje Chess fún ọdún díẹ̀

Ààrẹ ìdíje Chess ní Kenya, Bernard Wanjala ní ó ṣeéṣe kí àwọn fi òfin dé Omondi láti má lè kópa nínú ìdíje náà fún bí ọdún mélòó kan àmọ́ àwọn kò ní le nínú ìdíje náà pátápátá.

Wanjala sọ fún BBC Sport Africa pé àwọn ti ẹ̀ kọ́kọ́ fura rárá pé ọkùnrin ni nítorí kì í ṣe ohun tuntun fún àwọn obìnrin láti wọ hijab wá sí ìdíje náà.

"Ohun tó jẹ́ ka fura ni pé níṣe ló ń na àwọn olùdíje tó dára púpọ̀, kò sì wọ́pọ̀ kí ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kópa nínú ìdíje náà fún ìgbà àkọ́kọ́ láti na àwọn ènìyàn wọ̀nyí.

"Bàtà rẹ̀ àti pé Omondi kò sọ̀rọ̀ rárá bí ìdíje náà ṣé ń tẹ̀síwájú náà jẹ́ kí ara fu wá."

"A fura pé bàtà ọkùnrin ló máa ń wọ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà ju ti bàtà obìnrin lọ tí kìí sì bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ kódà àwọn tí wọ́n jọ ń díje."

Awon oludije

Oríṣun àwòrán, KENYA CHESS

Wanjala pẹ̀lú gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí, àwọn ṣì gba Omondi láti tẹ̀síwájú àmọ́ nígbà tó dé ipele kẹrin ni àwọn tó yọ si pé ọkùnrin ni.

"Òun náà kò lè jiyàn rẹ̀ nígbà tí a yọ si tó sì ń bẹ̀bẹ̀ pé ìṣòro owó kan tí òun nílò láti yanjú ní kíákíá ló jẹ́ kí òun gbé ìgbésẹ̀ náà."

Ọdọọdún ni ìdíje Chess náà máa ń wáyé ní Nairobi, orílẹ̀ èdè Kenya.

Ó lé ní irínwó àwọn olùdíje tó kópa nínú rẹ̀ láti orílẹ̀ èdè méjìlélógún tí àwọn olùdíje obìnrin sì jẹ́ 99.

Ní abala ti àwọn obìnrin, ẹgbẹ̀rún mẹ́ta dọ́là ni ẹni tó bá gbégbá orókè máa gbà.

Wanjala ní Omondi jẹ́ ènìyàn tí àwọn mọ̀ tẹ́lẹ̀ nínú ìdíje Chess.

Bákan náà ló ní ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí ènìyàn máa dá irú ọgbọ́n yìí láti kópa nínú idije náà.

Ó fi kun pé ìgbìmọ̀ olùwádìí yóò gbé ìdájọ́ wọn kalẹ̀ láìpẹ́ ọjọ́.