Ọkùnrin tó bu igbáàyà obìnrin lọ́nà àìtọ́ rí ẹ̀wọ̀n he

aworan

Oríṣun àwòrán, others

Ileẹjọ Magistrate kan to n joko niluu Badagry nipinlẹ Eko, ti palasẹ pe ki Ibrahim Lemo, ẹni ọdun mọkanlelogoji lọ maa gba atẹgun lọgba ẹwọn fun ẹsun o bu igbaya ọmọ binrin kan.

Ọkunrin ọhun lo tun lu obinrin naa, ẹni ti orukọ rẹ n jẹ, Zainab Babalola ni alu bami lasiko ti ọmọbinrin naa ni ko jawọ ninu iwa naa.

Adajọ Fadahunsi Adefioye ni ki wọn lọ fi Lemo si ọgba ẹwọn lẹyin to ni oun jẹbi ẹsun meji ti wọn kaa si lẹsi.

Adefioye wa palasẹ pe ki olujẹyọ dero ọgba ẹwọn ni Awhajigoh niluu Badagry.

Saaju, agbẹjọro olupẹjọ, ASP Clement Okuoimose, sọ fun ileẹjọ pe olujẹjọ sẹ ẹsẹ naa lọjọ kẹfa oṣu kẹrin ni dede ago meji abo agbegbe Badagry.

Okuoimose ni Lemi mọmọ tẹ igbaya Zainab Babalola ni.

O ni olujẹjọ naa tun gba obinrin naa lẹsẹ loju, to si fa ipa si lara lẹyin to ni ko maa fi ọwọ kan an.