Èèyàn mẹ́rin kú lásìkò tí wọn ń gbà ààwẹ̀ láti pàdé Jésù

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa ti ri oku eeyan mẹrin lọjọbọ, ti eeyan mejila miiran si balẹ si ile wosan niluu Kilifi lorilẹede Kenya lẹyin ti wọn dola wọn.
Wọn ni awọn eeyan kan ni wọn ri ninu igbo, ti wọn si ti wa nibẹ fun ọjọ pipẹ lẹyin ti Pasitọ kan sọ fun wọn pe ki gba awẹ nitori pe wọn fẹ salabapade Jesu.
Awọn alasẹ agbegbe naa ni eeyan mọkanla ni awọn dola ẹmi wọn, mẹfa ninu wọn si ti gbẹ toritori, ti wọn si wa ni ẹsẹ kan ẹsẹ kan oorun.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn yoo bẹrẹ si ni ma awọn yooku lowurọ ọjọ Eti lẹyin ti wọn gbọ pe awọn eeyan miiran si wa ninu igbo ọhun.
Bakan naa ni wọn ni awọn ri sare kan ti wọn sẹsẹ gbẹ ninu igbo naa, ti awọn yoo si se iwadi lori sare naa.
Awọn olujọsin naa ni wọn lọ ile ijọsin Good News International Church, ti Pasitọ wọn si ti wa ahamọ Ọlọpaa lori ẹsun o gba awọn eeyan to tẹle niyanju lati fi ebi pa ara nitori wọn yoo tete lọ ba Ọlọrun
Sugbọn wọn ti pada tu silẹ.
.
Pasitọ sọ fun wa pe ki a fi ebi para ku nitori nnkan buburu fẹ sẹlẹ ni ile aye
Ninu oṣu kẹta, Pasitọ Paul McKenzie Nthenge wọ gau, to fi oju ba ileẹjọ lẹyin ti tọkọtaya kan padanu ẹmi nitori wọn fi ebi pa arawọn ku.
Tọkọtaya ọhun lo jẹ olujọsin ni ile ijọsin Pasitọ naa, ni iroyin sọ pe wọn fi ebi pa arawọn ati ọmọ wọn meji ninu mẹta nitori Pasitọ wọn sọ fun pe ki wọn gba awẹ ku nitori nnkan ajalu buburu yoo sẹlẹ si ile aye laipẹ.
Awọn tọkọtaya naa lo gbe awọn ọmọ wọn sinu sare kan ti wọn gbẹ ni Kilifi
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ọkan lara ọmọ wọn ti ko ku lo salaye bi isẹlẹ naa se waye.
Iroyin ta gbọ nipa awọn tọkọtaya naa ni pinnu pe awọn ọmọ wọn ni yoo kọkọ ku, ki iyawo to tẹle wọn, ki ọkọ to jẹ baale to wa kẹsẹrẹ nilẹ ki ile aye to bajẹ.
Nthenge lo ti fa ọpọlọpọ wahala pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa sẹyin nitori o ma gba awọn olujọsin rẹ imọran lati kọ eti kun si ijọba
Ọpọgba ni ileeṣẹ ọlọpaa ti mu Pasitọ naa, to si ti ilejọsin rẹ ni Malindi pa lọdun 2019, lo sapamọ si ajalẹ.
Lọdun 2017, ọwọ tẹ fun ẹsun pe ko fun awọn ọmọ rẹ mẹta ni ẹkọ to yanranti.















