"Àìrí ìyàwó fẹ́, ló mú mi ṣe iṣẹ́ abẹ lẹ́ẹ̀mejì láti ga si"

Moses Gibson wa lori ibusun nile iwosan

Oríṣun àwòrán, Mirror

Ọkunrin kan lorilẹede Amẹrika lo pinnu lati lọ se isẹ abẹ eyi ti yoo mu ga si, to si ti ga si niwọn ẹsẹ bata marun si bayi.

Bi awọn eeyan se n foju buruku wo nitori ko ga lo mu Moses Gibson lọ maa lo oogun, koda, o lọ ile alawo danwo.

Lẹyin gbogbo igbiyanju rẹ to ja si pabo, ni Moses Gibson, ẹni ọdun mọkanlelogoji pinnu lati lọ se isẹ abẹ nitori ohun kan soso to ku fun lati se ko fi le ga niyẹn.

Isẹ abẹ naa lo da lori pe ki wọn fọ awọn eegun ara rẹ.

O se afikun ẹsẹ bata mẹta si giga rẹ lọdun 2016 pẹlu isẹ abẹ.

Sugbọn lẹyin ọdun meje, o tun pada lọ fun isẹ abẹ miiran, to si tun lo awọn eroja ti yoo mu ga eyi to jẹ ti ẹrọ igbalode.

"Ọpọ igba ni wọn n fi mi se yẹyẹ pe mo kuru, ni mo se na $165,000 ori isẹ abẹ mejeeji"

Moses lo na apapọ owo toto ẹgbẹrun lọna marundinlaadọsan owo dọla fun isẹ abẹ mejeeji, to si ni ireti lati gaa de ibi to fẹ ga de ko to di ọjọ kẹwaa oṣu kẹfa.

Eniyan kukuru ni Moses, eyi to jẹ inira fun lati ni le ni iyawo.

Ọpọ igba ni awọn eeyan n fi se yẹyẹ sugbọn nibayii, o gbagbọ pe oun ti le ba ẹgbẹ pe, ti yoo si ri aya fẹ aipẹ.

Moses, ẹni to wa lati Minneapolis, ni Minnesota lorilẹede Amẹrika ni “O nira fun mi nitori n ko ga.

N ko mọ ohun ti wọn n pe aarun naa sugbọn mo mọ pe eniyan kukuru ni mi.”

Ọdọmọkunrin naa ni lasiko toun wa ni ile ẹkọ, inu oun ko fi igba kankan dun pẹlu bi oun ko se ga.

“Lasiko ti mo pe ọmọ ọdun mẹẹdogun ni mo ti ri pe awọn akẹẹgbẹ mi ti ga ju mi lọ.

“Asiko naa ni ọrọ naa bẹrẹ si ni maa dun mi, ti inu mi ko si dun si ara mi. Gbogbo igba mii, inu ara mi maa n bi mi.

Moses Gibson duro

Oríṣun àwòrán, Mirror

"Mo ra ogun lori ayelujara ti mo lero pe yoo jẹ ki n ga si sugbọn mo ri pe ofutu fẹẹtẹ ni gbogbo wọn"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Moses Gibson fikun pe, “Mo fẹran asọ ati bata sugbọn inu mi ko dun nitori ti n ba wọ wọn, wọn ko da lara mi.

“Irẹwẹsi ọkan bẹrẹ si ni maa se mi pẹlu obinrin.

O se akoba fun igbinyanju mi lati ni iyawo.

Mo si maa fi nnkan si abẹ bata mi lati ri pe mo ga sugbọn ko ki n se nnkan ti mo fẹ.

“Awọn eeyan maa sọrọ. Igba miiran lo le jẹ ọrọ odi tabi wọn fẹ tabuku rẹ sugbọn ọrọ agbako kan bẹ lẹnu bi , okunrin kukuru.

“Akinkanju ni mi, fun idi eyi ọrọ naa ko ki n dun mi sugbọn maa wa ọna abayo.

“Mo ra ogun lori ayelujara ti mo lero pe yoo jẹ ki n ga si sugbọn mo ri pe ofutu fẹẹtẹ ni gbogbo wọn.

“Mo ba awọn babalawo kan sọrọ lori ayejara ti wọn ni awọn tan gbogbo irufẹ isoro. Mo bawọn sọrọ boya wọn le ran mi lọwọ sugbọn pabo ni.

“Nigba ti mo lọ si ile ẹkọ, mo ri isẹ abẹ kan lori ayelujat ti mo si ni nnkan ti mo wa kiri ree”

Lẹyin ọdun mẹta ti mo fi sisẹ, ti mo si n wa ọkọ loru, Moses tele owo jọ, owo toto ẹgbẹrun lọna aadọjọ dọla lati fi ese isẹ abẹ naa.

Isẹ abẹ ọhun lo waye pẹlu ọpọlọpọ inira losu to kọja, ti wọn fọ awọn eegun ara Moses.