Àwọn tó sun ọmọ mi níná ní ó wọ aṣọ olówó ńlá táwọn kò rí irú rẹ̀ wọ̀, ni wọn ṣe pa á - Ìyá Tope Olorunfemi
Mojisola Olorunfemi, tii se mama Tope Olorunfemi, ọkunrin ti araalu dana sun lọjọ Aiku to kọja nilu Akure ti sọrọ soke.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, mama oloogbe naa salaye pe owu ati ilara lasan lo mu ki wọn dana sun ọmọ oun.
Mama Tope ni oun wa nibẹ nigba ti wọn dana sun ọmọ naa, ti awọn to dana sun si n pariwo pe nibo lo ti ri owo ra asọ olowo iyebiye ati mọto to n lo.
Bakan naa lo ni gbogbo alaye ti oun se fun wọn lati jọwọ ẹmi ọmọ oun lo ja si pabo.
Mama Tope fikun pe "Wọn ni nibo lo ti ri asọ to wọ sọrun, bata ati mọto to n lo?
Emi ati baba rẹ si la ra mọto naa fun nigba to ni oun ko ri isẹ se.
A ni ko maa fi mọto naa se kabukabu nitori o ti niyawo ati ọmọ.
Awọn to pa ọmọ mi tun ni wọn ba asọ ọmọ, kolo ati ọsẹ ninu mọto rẹ.
Awọn ẹru ọmọ rẹ ati ti iyawo rẹ si lo wa ninu mọto to n gbe, kii se eroja Yahoo rara."
Mama oloogbe naa wa rawọ ẹbẹ sijọba lati se idajọ ododo lori awọn to pa ọmọ oun nitori kii se onijibiti ori ayelujara bi wọn se lero.
O fikun pe oun da eeyan meji mọ ninu awọn eeyan to suru pejọ pa ọmọ oun loju oun.
O ni orukọ ọkan ninu wọn ni Luku, ti ekeji si n jẹ Jobe.
Bakan naa, iyawo oloogbe sọrọ pẹlu BBC Yoruba, to si n sọkun asundakẹ lori iku ọkọ rẹ.
Oun naa si fidi rẹ mulẹ pe ẹru ọmọ oun ati toun ni awọn gbe fun ọkọ oun pe ko maa gbe lọ si Eko.
O ni ọkọ oun kii se Yahoo, kabukabu lo n se.

Oríṣun àwòrán, twitter/screenshot
Arakunrin kan ti awọn eeyan ṣe idajọ ọwọ fun nilu Akure lẹyin to kọlu ọlọkada kan kii ṣe ‘yahoo boy’ tabi ologun owo gẹgẹ bi awọn eeyan kan ṣe n sọ kiri.
Awọn eeyan lagbegbe ijọka pa ọdọkunrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Temitọpẹ Ọlọrunfẹmi lọjọ Aiku lẹyin ọkọ rẹ rọlu obi ti awọn ọlọkada ati eeyan kan duro si ti olokada kan si ti ipa bẹẹ di ero ọrun.
Iya rẹ ati arabinrin kan to bimọ fun un lo sọ eyi lẹyìn ọjọ diẹ ti iṣẹlẹ yii waye.
"Aráàlú la igi mọ́ mí lórí nígbà tí mo fẹ́ gba ọmọ mi sílẹ̀ pé kí wọn má dáná sun, ojú mi ni wọ́n ti da bẹntiró lu lára"
Titi di akoko yii, ohun ti o n lọ kaakiri nipa arakunrin naa ni pe ọkan lara awọn ọdọ to n lu jibiti ori ayelujara jẹun, ti ọpọ eeyan mọ si “yahoo boy” ni, koda awọn kan sọ pe ara awọn to n f’eeyan ṣetutu ọla ni.
Ninu ọrọ ti wọn sọ sinu fidio kan, iya arakunrin naa ati iyawo rẹ salaye pe awakọ kabuka u Bolt ni ati pe o ni ọmọ ọdun kan, iyawo rẹ si kere jọjọ.
"Ọdún Àjíǹde ni ọmọ̀ mi wá ṣe ní Akure, awakọ̀ Bolt ni"
Iya re, arabinrin Mojisọla Ọlọrunfẹmi sọ pe nigba ti ọmọ oun jade ileewe ti ko risẹ lo fi gba ọna Eko lọ boya nnkan yoo ṣe ẹnure fun. Amoṣa ilẹ ko rọ fun un nibẹ lo fi pada wa si ilu rẹ Akurẹ.
“O ni bi oun ba ri moto oun fẹ maa ṣe Uber. Baba rẹ ra ọkọ naa fun ni nnkan bii ọdun mẹta sẹyin, o dẹ pada si Eko.
“Ajọyọ ọdun Ajinde ni o wale fun. Baba rẹ lo pe mi lọjọ ti nnkan yii ṣẹlẹ nigba ti mo si de bẹ, mo ba ọmọ mi ninu agbara ẹjẹ.
Mo pe awọn ẹgbọn ati aburo rẹ pe ki wọn ba mi gbe e ṣugbọn ṣe lawọn ero naa n da igi bo mi.
Oju mi bayii ni won ti da bẹntiroo sii lara, ti wọn tun dana sii aṣọ ju sii lara.

Oríṣun àwòrán, other
"Gbogbo alaye ti mo ṣe, ni won ko gbọ, ti wọn ko si jẹ ki oun gbe e lọ fun itọju, ko to ku"
“Mo sare sii, mo ju aṣọ naa danu, wọn tun la igi mọ mi.
Wọn tun da aṣọ ina naa pada sii lara , oun fura rẹ dide ju danu nitori o ti n jo o lara.
Lẹyin eyi ni ọkunrin kan ti wọn n pe ni Luku, ẹni mímọ ẹgbọn ọmọ mi ni, o gbe igi loju mi, o si la a mọ ọmọ mi lori.
Ọkunrin kan naa ti wọn n pe ni Jọbẹ naa gbe okuta.”
O ni gbogbo alaye ti oun gbiyanju ati ṣe ni won ko gbọ, ti wọn ko si jẹ ki oun gbe e lọ fun itọju.
Arabinrin Ọlọrunfẹmi ni ariwo ti wọn n pa pe ọmọ ‘yahoo’ ni ọmọ oun kii ṣe otitọ, awakọ kabukabu Bolt ni nilu Eko.

Oríṣun àwòrán, other
Ọwọ ọlọ́paa ti tẹ afurasi meji lori isẹlẹ naa - Agbẹnusọ Ọlọpaa
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo ti ni ọwọ ti tẹ eeyan meji lori bi wọn se sọko pa fun Olorunfemi Tope niluu Akure.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, SP Olufunmilayo Odunlami lo kede ọrọ naa lasiko to kopa lori eto kan lori Rẹdio lọjọ Isẹgun.
O ni ileeṣẹ ọlọpaa fi ofin mu awọn afurasi meji naa lori ẹsun pe wọn se idajọ lọwọ ara wọn.
















