Àwọn méjì tí a mú lórí ikú dẹ́rẹ́bà ní Ondo yóò jẹ́jọ́ ìpànìyàn- Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo ti ni ọwọ ti tẹ eeyan meji lori bi wọn se sọko pa fun Olorunfemi Tope niluu Akure.
Ti a ko ba gbagbe, Olorunfemi Tope, ọmọ ọdun marundilogoji, lo padanu ẹmi rẹ lasiko ti awọn araalu kọlu lẹyin to fi ọkọ ayọkẹlẹ rẹ sekupa awọn eeyan meji niluu Akure.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, SP Olufunmilayo Odunlami lo kede ọrọ naa lasiko to kopa lori eto kan lori Rẹdio lọjọ Isẹgun, o ni ileeṣẹ ọlọpaa fi ofin mu awọn afurasi meji naa lori ẹsun pe wọn se idajọ lọwọ arawọn.
Odunlami ni ọkan lara afurasi lo siwaju bi wọn se dana sun ọkọ ayọkẹlẹ oloogbe.
‘’Awọn afunrasi naa yoo jẹjọ ipaniyan ati jijo ohun ini nina’’
Ninu ọrọ rẹ, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ni Ondo, Odunlami ni ọwọ ti ba awọn meji to lọwọ ninu iṣekupani naa.
Odunlami-Omisanya naa ni awọn n gbe awọn meji ti ọwọ ba naa lọ si ileẹjọ.
O si ni wọn yoo jẹjọ ẹsun ipaniyan ati jijo ohun ini ẹlomiran ni ina.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa naa ni iwadii fihan pe awọn mejeeji gan an lo sagbatẹru bi wọn ṣe ju okuta lu Tope titi ẹmi fi bọ ni ara rẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa naa wa kesi awọn araalu pe o lodi si ofin lati ṣe idajọ ẹlomiran nipa lilu eniyan pa.
“A ni lati ri ara wa gẹgẹ bi ọkan, ka si nifẹ arawa. A ni lati ri ara wa gẹgẹ bi eeyan ki a to fun ẹnikẹni ni orukọ
“Ti ti di asiko yii, ko si ẹni to le sọ boya oloogbe naa jẹ ọmọ Yahoo.
“Sugbọn nigba to yẹ ki awọn eeyan se iranlọwọ fun awọn to farapa, wọn parapọ lati sekupa ọmọ kunrin na, ti wọn si dana sun ọkọ ayọkẹlẹ rẹ.
“A ni lati yago fun iwa yii, ki a ma se idajọ lọwọ ara wa.
"Nitori nnkan bayi ni ileeṣẹ ọlọpaa fi wa ni ayika wa lati ri pe alaafia jọba ni agbegbe wa."
Inu wa ko dun si bi araalu se se idajọ lọwọ arawọn - Ijọba Ipinlẹ Ondo
Adẹle gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Orimisan Ayedatiwa ti bu ẹnu atẹlu bin awọn araalu kan se se idajọ lọwọ arawọn, eyi to sokunfa bi ọmọ kunrin kan, Olorunfemi Topa se padanu ẹmi rẹ.
Ayedatiwa, ninu atẹjade kan ti Kọmisọna fun eto iroyin nipinlẹ Ondo, Bamidele Ademola Olateju buwọlu, fi ransẹ si awọn akọroyin, Gomina ni ijọba yoo ri pe gbogbo awọn to kopa ninu ikọlu naa foju ba ileẹjẹ.
“Ohun to ba ni lẹru pupọ ni isẹlẹ, ti ijọba si lod pupọ nitori ofin ko fi aye silẹ fun ẹnikẹni lati se idajọ lọwọ ara rẹ.
“Ti ko ba ki n se ti ileeṣẹ ọlọpaa, awọn obi oloogbe naa ko ba padanu ẹmi wọn. Ohun buruku lo jẹ ki obi wo bi wọn se sekupa ọmọ rẹ.
“Gbogbo awọn to kopa ninu isẹlẹ yii ni ijọba yoo ri pe wọn ri ijiya ofin laipẹ.”
Gomina wa ba awọn mọlẹbi to farakasa ninu isẹlẹ naa kẹdun, to si gba ladura pe ki Ọlọrun duro tiwọn.
Dẹ́rẹ́bà tí àwọn aráàlú ṣekúpa nípínlẹ̀ Ondo, kí n ṣe 'Ọmọ Yahoo' - Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti sọrọ sita lori dẹrẹba ọkọ ayọkẹlẹ, ti awọn eeyan kan pe ni Ọmọ Yahoo,ẹni ti ọrukọ rẹ n jẹ, Olorunfemi Tope, ọmọ ọdun marundilogoji, ẹni to padanu ẹmi rẹ lasiko ti awọn araalu kọlu lẹyin to fi ọkọ ayọkẹlẹ rẹ sekupa awọn eeyan meji niluu Akure.
Botilẹ jẹ p eeyan mẹrin ni awọn to fi ọrọ lede lori ayelujara sọ wi pe wọn ku nibi iṣẹlẹ naa to waye lọjọ Aje, ọjọ kẹwaa, oṣu kẹrin ọdun 2023.
Ileeṣẹ ọlọpaa Ondo ni awọn meji nikan ni awọn fidi rẹ mulẹ pe wọn gbẹmi mi nibi ijamba ọkọ naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami, ninu atẹjade to fi ransẹ si awọn akọroyin fidi isẹlẹ naa mulẹ, to si ni eeyan meji nikan ni awọn mọ to jẹ Ọlọrun nibi ijamba ọkọ naa, ti awọn to farapa si ti wa ni ile wosan fun itọju.
Odunlami ni ko si ẹnikẹni to le fidi rẹ mulẹ pe Oloogbe yii jẹ Ọmọ Yahoo ni gẹgẹ bi awọn kan se n gbe kiri lori ayelujara.
“Ijambe yii sekupa pa ọlọkada kan sugbọn o ṣeni laanu pe lasiko to yẹ ki awọn eeyan to wa ni ayika agbegbe naa se iranwọ, wọn pinnu lati se isẹ ofin fun arawọn, ti wọn si sekupa dẹrẹba,lẹyin ti wọn dana sun ọkọ ayọkẹlẹ rẹ.
“Ti ko ba se ti gbinyanju ileeṣẹ ọlọpaa awọn eeyan ti fẹ sekupa pa awọn obi dẹrẹba naa ti wọn suure de ibi isẹlẹ naa lẹyin ti wọn gbọ iroyin”















