Fulani adaranjẹ̀ fẹ́jọ́ ìjínigbé sun ọlọ́pàá l‘Osun, ọwọ́ tẹ Ṣéríkí Fulani àti afurasí méjì l‘Oyo

Awon afurasi ajinigbe

Oríṣun àwòrán, POLICE OSUN

Ọwọ́ ṣìkún òfin àwọn ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Osun ti tẹ àwọn afurasí ajínigbé mẹ́ta tó ń da ìpínlẹ̀ náà láàmú.

Ikọ̀ tó ń gbógun ti ìwà ìjínigbé níléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà ló ya wọ bùbá àwọn ajínigbé náà láti fi páńpẹ́ òfin gbé wọn níbi tí wọ́n fara pamọ́ sí.

Àwọn Fulani adaranjẹ́ ló lọ fi ẹjọ́ àwọn ajínigbé sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá pé wọn kò jẹ́ kí àwọn rímú mí.

Ọ̀gá àgbà ikọ̀ àwọn ọlọ́pàá ọ̀hún, Moses Lohor ní abúlé kan ní ìpínlẹ̀ Oyo ni àwọn afurasí náà fara pamọ́ sí, níbi tí wọ́n tún ti ń gbèrò láti jí Fulani darandaran mìíràn gbé.

Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ̀ wá ká tó jí èèyàn gbé torí pé a bèèrè owó N500,000 lọ́wọ́ ẹni tí a fẹ́ jí gbé - Afurasí

Lohor ṣàlàyé pé lásìkò tí àwọn lọ kojú àwọn afurasí ajínigbé náà, wọ́n yìnbọn bá ọlọ́pàá kan, tí ọlọ́pàá náà sì ń gbà ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn lọ́wọ́.

Àwọn afurasí tí ọwọ́ tẹ̀ náà ni Seriki Fulani ìjọba ìbílẹ̀ Afijio ní ìpínlẹ̀ Oyo, Hassan Abdullah àti àwọn Fulani darandaran méjì mìíràn, Barri Galadima àti Muhammadu Abdullah.

Àmọ́ Hassan Abdullah ti jiyàn pé òun kò bá wọn lọ́wọ́ nínú ìwà ìjínigbé náà.

Ọkàn lára àwọn afurasí náà, Barri Galadima sọ pé àwọn gbèrò láti jí ènìyàn kan gbé, tí àwọn sì ti ń pe onítọ̀hún láti wá san owó.

Àmọ́ ó ní onítọ̀hún kọ̀ láti san owó fún àwọn, tí àwọn kò sì tíì rí onítọ̀hún jí gbé, tí ọwọ́ fi tẹ àwọn.

Muhammadu ní tirẹ̀ ní, Seriki ni ọ̀gá àwọn tí àwọn ti jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ láti ọjọ́ pípẹ́ àti pé òun ló fún àwọn ní nọ́ḿbà ẹni tí àwọn fẹ́ jí gbé náà.

"Ẹni ta fẹ́ jí gbé gbà láti san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta fún wa, tó sì ní ka pàdé ní àná àmọ́ kàkà kí a rí owó gbà, ọwọ́ ọlọ́pàá la bọ́ sí."

Ó ní ìdí nìyí tí àwọn fi mú àwọn ọlọ́pàá náà lọ sí ilé Seriki nítorí òun ló fún àwọn ní nọ́ḿbà ẹni ti awọn fẹ ji gbe.

Àwọn ajínigbé yìí ti ba orúkọ Fulani jẹ́ jìnà - Seriki Fulani Ayedire l‘Osun

Seriki Fulani ìjọba ìbílẹ̀ Ayedire ní ìpínlẹ̀ Osun, Sulaiman Oluwatoyin ní àwọn ajínigbé wọ̀nyí ti ba orúkọ àwọn Fulani jẹ́ jìnà.

Ó ní o máa ń ba oun lọ́kàn jẹ́ pé irú àwọn ènìyàn báyìí wà nínú ìran àwọn.

Bákan náà ló dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe láti fi rí àwọn afurasí náà mú.

Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun, Kehinde Longe ní kété tí àwọn bá ti parí ìwádìí ni àwọn máa gbé àwọn afurasí náà lọ sí ilé ẹjọ́.

Bákan náà ló ní iṣẹ́ ń lọ láti ri dájú pé gbogbo àwọn yòókù wọn tó sá lọ ní ọwọ́ tẹ̀ láìpẹ́.

Àkọlé fídíò, Rukayat Shittu: Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ló jẹ́ kí ń borí, mo ti ṣe omi, àtúnṣe ọ̀nà sẹ́kún ìdìbò mi

NDLEA mú ọmọ orílẹ̀èdè Suriname pẹ̀lú egbò igi olórò nínú 'Condom'

Aworan Afurasi pẹlu egbogi oloro

Oríṣun àwòrán, NDLEA

Ọkunrin kan, Dadda Lorenzo Harvy Albert, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn lati orilẹede Suriname ni ọwọ ajọ to n gbogun ti egbogi oloro lorilẹede Naijirai, NDLEAti tẹ ni paapa ofurufu nipinlẹ Rivers lasiko to n gbinjyanju lati gbe egbogi oloro wọle si orilẹede Naijiria.

Ninu atẹjade ti ajọ naa fi ransẹ si awọn akọroyin, Agbẹnusọ ajọ naa, Femi Babafemi ni ninu rọba idabobo ni ọkunrin naa ko egbogi oloro naa si.

O tẹsiwaju pe afurasi naa ni oun kuro lorilẹede Suriname lọjọ keji oṣu kẹrin, to si morile Sau Paulo lorilẹede Brazil, ko to wa si orilẹede Naijiria lọjọ keje, oṣu kẹrin lati wa sawari Baba to bi lọmọ, ẹni to pe orukọ rẹ “Omini”.

aworan

Oríṣun àwòrán, NDLEA

Babafemi ni iwadi ti bẹrẹ lori afurasi naa

Bakan naa ni ajọ NDLEA kede pe ọwọ ti tẹ awọn afurasi nipinlẹ Imo, Eko ati Kano lasiko ti wọn gbinyanju lati gbe egbogi oloro wọ orilẹede Naijiria.

Lasiko to n kan sara si ọmọ ogun ajọ naa, Ọga agba fun NDLEA, Brig. Gen Mohamed Buba Marwa (Retd) rọ awọn ọmọ ologun lati ma se dẹkun bi wọn se n tẹpamọ bi wọn se mojuto ilọsiwaju orilẹede Naijiria.