Mo ní ìfẹ́ ọkọ mí Oluwo tí ilu Iwo, àti ọjọ́ tí mo ti fí ojú kàn án ni ìfẹ́ rẹ̀ tí wà ní ọkàn mi – Ayaba tuntun láàfin

Oríṣun àwòrán, Instagram
Iyawo Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Akanbi, Ayaba Firdaus Akanbi ti sọ ọrọ iwuri nipa ọkọ rẹ ati bi ọrọ ifẹ wọn ṣe bẹrẹ.
Ọdun to kọja ni ayaba tuntun naa di olori laafin ọba Oluwo, to si ṣẹṣẹ bimọ tuntun jojolo fun Ọba Akanbi.
Ni ifọ̀rọwerọ to ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin Punch to ti sọ bi ifẹ wọn ṣe bẹrẹ ati iru igbeaye ti oun gbe ni aafin Oluwo
‘’Ọjọ ti mo ti foju kan Oluwo ni ifẹ rẹ ti gbilẹ ni ọkan mi’’

Oríṣun àwòrán, Instagram
Ayaba Firdaus to jẹ ọmọba lati idile Bayero ni ilu Kano ni ẹni ọfun mejidinlọgbọn ni oun ti oun si kẹkọ imo eto ọrọ aje ni fasitit, Modern University of Science and Technology, Cairo, ni orilẹede Egypt.
Ayaba Firdaus ṣapejuwe ọrọ ifẹ rẹ pẹlu Oluwo gẹgẹ bi eleyii ti Edua fi ọwọ si ti o si ti kọ silẹ lati orun, ti oun si dupẹ.
‘’Ọlọrun lo so emi ati ọkọ mi pọ, ọkọ to dara si ni pẹlu ti inu mi si n dun si ni ojoojumọ.’’
‘’Ko si ẹni to mọ Oluwo ti yoo fẹ kuro ni ọdọ rẹ, eniyan to ni iwa pẹlẹ ni, iyanu si ni bi mo ṣe di ayaba laafin rẹ.’’
‘’Auntie mi to jẹ iyawo minisita fun ọrọ abẹle tẹlẹri, Hadiza Bayero Dambazau lo fi wa mọ ara, ti a si pinu lati fi oju kan ara wa.’’
‘’Igba akọkọ ti mo ti ri Kabiyesi ni mo ti fẹran rẹ, ti ifẹ rẹ si ti wa ni ọkan mi.’’
‘’Ọkọ to dara ni Oluwo, o si n toju mi, o ma n pamilẹrin, to si ni iwa tutu pẹlu.’’
Ayaba naa ni igbe aye oun ko fi bẹẹ yipada ni aafin ọba Oluwo nitori aafin ni oun gbe dagba, to si mu igbeaye tuntun ni ilẹ Yoruba dara fun oun.
Bakan naa lo ṣe apejuwe awọn ara ilẹ Yoruba gẹgẹ bi awọn to ni ifẹ, wọn fa awọn eniyan mọra, ti wọn si bọwọ fun ara wọn ati ori ade pẹlu.















