'Iṣẹ́ nọ́ọ̀sì ló wù mi láti ṣe níbẹ̀rẹ̀ ayé àmọ́ àwọn ọ̀gá tó n fi ìṣekúṣe lọ̀ mi ló jẹ́ kí n sá'
Gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Toyin Adegbola, ti ọpọ mọ si aṣewo to re Mecca ti sọ iriri aye rẹ fun BBC Yoruba.
Ọmọ ọgọta ọdun le diẹ naa ṣalaye pe iṣẹ nọọsi lo wu oun lati ṣe ni ibẹrẹ pẹpẹ amọ gbogbo igbiyanju oun lo ja si pabo.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, eyii ko ṣẹyin bi awọn ọkunrin kan ṣe maa n fi ilọkulọ lọ oun ni gbogbo igba ti oun ba ṣe idanwo lati lọ kẹkọọ nipa iṣẹ naa.
O ni igba meji ọtọtọ loun gbiyanju rẹ amọ ko bo si lo jẹ ki oun lọ sile ẹkọ ikọṣẹ iṣẹ ọwọ, nibi ti oun ti kọ nipa ina mọnamọna, lẹyin naa loun lọ ṣiṣẹ lori ẹrọ amohunmaworan.
O ṣalaye pe lẹyin ti oun lo akoko diẹ nidi iṣẹ tẹlifiṣọn loun kọwe fi iṣẹ silẹ lati lọdarapọ mọ awọn oṣere nibi ti Ọlọrun ti gbọ adura oun.

“Ko rọrun lati tọju ọmọ lẹyin iku ọkọ mi”

Toyin sọ fun BBC pe igba ti awọn ọmọ oun wa ni kekere ni ọkọ oun fi aye silẹ.
O ni “Ko rọrun ki ẹru eeyan meji di ti eeyan kan, amọ nitori pe Ọlọrun wa pẹlu mi, ko doju adura ti mi, Ọlọrun ba mi wo awọn ọmọ naa.”
Ẹkunrẹrẹ ohun ti yeye Toyin Tomato ba BBC Yoruba sọ wa ninu fidio yii.













