Ejò dá rúgúdù sílẹ̀ nínú ọkọ̀ òfúrufú, ó tún fà mọ́ “pilot” lára

Oríṣun àwòrán, Getty image,RudolphErasmus
Awakọ ọkọ ofuurufu aladani kan ni South Africa, Rudolph Erasmus, lo kẹfin ejo paramolẹ ninu ọkọ ofurufu to wa lẹyin to ti wa ni iwọn ẹsẹ bata ẹgbẹrun mọkanla ninu ofurufu (11,000ft).
Nigba ti oun sọrọ nipa iriri rẹ, Erastus ni “o jẹ asiko ti ọkan mi gbe soke, mo ro wi pe ohun to tutu mọ mi lẹyin jẹ ike omi.”
O ni “mo ni imọlara pe nkan to tutu rin mo mi lara, mo ro wi pe omi ti mo n fi ọmọri de ni o da si mi lara “.
“Ẹyin ti mo wo lati gbe ike omi ti mo lero wi pe o da simi lara, bayii, ejo paramolẹ ni mo ri to n fi ori rẹ sẹyin, loba mori le abẹ aga ti mo joko si.”
Erastus to tukọ ọkọ ofurufu aladani Beechcraft Baron 58, eyii to gbe ero mẹrin, to si n dari si Pretoria lati Bleomfontein.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oro ejo paramọlẹ lagbara lati pa eyan laarin ọgbọn isẹju to ba buyan jẹ.
Erasmus ni “ẹru bami, mo ro wi pe ejo paramọlẹ naa yoo wọ sibi ti awọn ero ti mo gbe joko si to si le fa ijamba”.
Ninu ọrọ rẹ, Erasmus ni gbogbo ero to wa ninu ọkọ ofuurufu naa ni wọn parọrọ nigba to sọ fun wọn pe ejo kan ti wa ninu Baalu ọhun, o salaye fun wọn wi pe oun fẹ so baalu na silẹ.
Nigba to n ba akọroyin BBC sọrọ, Erasmus ni ọpọ ẹkọ ni awọn kọ nile iwe ti wọn ti n kọ bi wọn ti wa ọkọ ofurufu ṣugbon ko ṣi ẹni to kọ bi wọn ti n mu ẹjo.
Botilẹ jẹ pe ṣaaju ki baalu naa to fo ni awọn kan ti ri labẹ ọkọ ofurufu naa, igbiyanju wọn lati mu lo jasi pabo ti wọn si ro wi pe o ti fa lọ ni.
Lẹyin ti mo gbiyanju lati wa ejo paramọlẹ naa ki n to bẹrẹ irin ajo mi ti mi o ri, mo ti gbagbọ pe o ti fa lọ ni, lai mo wi pe o ṣi wa ninu ọkọ ofurufu mi.
Lẹyin ti baalu na baa si Welkom tan gbogbo igbiyanju awọn onimo ẹrọ lati wa ejo naa lo ja si pabo.
Erasmus ni botilẹ jẹ pe ọpọ eyan lo ti gborinyin fun oun nitori nkan to sẹlẹ ṣugbọn, igboya awọn ero ọkọ ofurufu ti oun gbe lo ya oun lẹnu julọ.














